category
large_stringclasses
7 values
headline
large_stringlengths
10
171
text
large_stringlengths
1
26.4k
url
large_stringlengths
13
180
lang
large_stringclasses
16 values
politics
Eyinwumi Muka 'Muka Ray' darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ ìṣàkóso ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara
Gbajumọ oṣere sinima Yoruba, Eyiwunmi Muka Aramide ti ọpọ mọ si Muka Ray ti darapọ mọ oṣelu bayii pẹlu bi gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrazaq Abdulrahaman ṣe yan an gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ agba lori ọrọ aṣa ati irinajo afẹ. Gbajumọ onitiata to lokiki ni Muka Ray, ọmọ agbegbe idibo wọọdu Ipetu/ Rore/ Aran-Orin ni ijọba ibilẹ Irẹpọdun si ni. Ijọba ipinlẹ Kwara kede orukọ Eyiwumi Muka Aramide ati ipo tuntun ti wọn yan an si l’Ọjọbọ. Ṣaaju iyansipo rẹ, gomina Abdulrazaq kan naa ti yan eekan elere sinima miran, Fẹmi Adebayọ si ipo amugbalẹgbẹ pataki lori ọrọ aṣa, iṣe ati irinajo afẹ lọdun 2016. Ikede iyansipo Muka Ray tun tọka si ara igbesẹ akọtun eyi to n fihan bi awọn eekan elere sinima lorilẹede Naijiria pẹlu ṣe ti n lẹnu ninu ọrọ oṣelu lorilẹede Naijiria. O n tọ ipasẹ awọn oṣere bii Bukky Wright to dije fun ipo ile aṣofin apapọ lọdun 2014. Bukky Wright dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu SDP nigba naa. Desmond Elliot to wa nile aṣofin ipinlẹ Eko bayii.  Desmond Ellio lo n ṣoju ẹkun idibo Surulere nile aṣofin ipinlẹ Eko bayii labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC. Olubankọle Wellinghton ti ọpọ mọ si Banky W to n dije fun ipo aṣojuṣofin lẹgbẹ oṣelu PDP fun eto idibo apapọ ọdun 2023 pẹlu Funkẹ Akindele ti ọpọ mọ si Jennifer to n dije gẹgẹ bi igbakeji gomina nipinlẹ Eko labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cp6kz6z1xklo
yor
politics
Àwọn olóṣèlú lápá Ariwa fẹ̀ yọwọ́ Tinubu láti díje, àmọ́ a kò ní gbà - Igbimọ Apapọ Yoruba Lagbaye
Ẹgbẹ kan to n ja fun ẹtọ ọmọ Yoruba, Igbimọ Apapọ Yoruba Lagbaye, Yoruba Council Worldwide, ti fẹsun kan awọn agba oloṣelu kan ni Ariwa pe wọn n gbimọ lati yọ ọwọ Bola Tinubu kuro lawo eto ibo sipo Aarẹ ti yoo waye lọdun to n bọ. Aarẹ ẹgbẹ naa, Omoluabi Oladotun Hassan sọ nibi ipade awọn akọroyin kan l’Abuja pe awọn gbagbọ pe awọn eeyan naa fẹ yọ Tinubu ninu ere ije ipo Aarẹ bi wọn ṣe yọ Obafemi Awolowo ati oloye MKO Abiola. Ninu atẹjade ti Hassan fi ṣọwọ si BBC Yoruba, o ni ọna ti awọn oloṣelu Ariwa naa n gba ni lati maa sọrọ kobakungbe lori awọn iwe iroyin nipa awọn iwe ẹri ile ẹkọ Tinubu. O ni eyii n waye lẹyin ti wọn ti kọkọ gbiyanju lati gbe Sẹnetọ Ahmed Lawan gẹgẹ oludije ẹgbẹ oṣelu naa amọ to ja kulẹ. Hassan ni wọn fẹ lo iwe ẹri ile ẹkọ Tinubu lati ja kulẹ loju awọn araalu, awọn ko si ni gba iru rẹ laaye. O ni “A ti mọ nipa ọgbọn ti awọn oloṣelu Ariwa n da lati yọ Tinubu kuro ninu ere ije ipo Aarẹ lọna ati faye gba oloṣelu miran lati inu ẹgbẹ mii, amọ to jẹ ọmọ bibi iha Ariwa.” “A si ti mọ nipa  ero wọn lati fi ọwọ eyin gbe Atiku wọle, ki wọn si le ṣatilẹyin fun lati di Aarẹ.” “Igbimọ Apapọ Yoruba Lagbaye fẹ ki gbogbo aye mọ pe a ko ni faye silẹ ki wọn ṣe ohun kan naa ti wọn ṣe fun Obafemi Awolowo ati MKO Abiola si Tinubu.” Gẹgẹ bii ohun ti Hassan sọ fun BBC, ẹya Yoruba lo ṣokunfa bi eto ijọba awarawa ṣe ṣeeṣe ni Naijiria nipa, o si yẹ ki ẹya kan naa lẹtọọ lati du ipo Aarẹ lai si ẹtanu kankan lati ọdọ awọn ẹya to ku. O ni “O da wa loju gedegbe pe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu nikan ni ọna abayọ si gbogbo iṣoro to n koju Naijiria lasiko yii.” “Eto oṣelu ti a si n fẹ ni eyii ti yoo lọ wọọrọwọ, ti awọn eeyan yoo fi le yan ẹni to wu wọn gẹgẹ bii awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe fẹnuko lori gbigbe ipo naa si ẹlẹkunjẹkun.”
https://www.bbc.com/yoruba/articles/crgnepn9d84o
yor
politics
Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adekunle Makama ti Kuta
Ẹ jẹ́ kí Gómìnà kọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ 'Restructuring' ni ìpínlẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ríró ìjọba ìbílẹ̀ lágbárá- Olowu ilẹ̀ Kuta A mọ́ awọn Fulani Abalaye a dẹ tun mọ ti awọn to n gbe ibọn pe wọn yatọ sira wọn- Oba Kuta Oba Ahmed Adekunle Makama ti Olowu Kuta sọrọ ilẹ kun lori oriṣi awọn Fulani to wa ni Naijiria bayii ati nkan to yẹ ki ijọba se fun koowa. Bakan naa lo ni o yẹ ki ijọba pada si riro awọn ijọba ibilẹ lagbara ni ki alafia le jọba. Oba Kuta tun gba imọran pe ki atunto bẹrẹ lati ipinlẹ Gomina kọọkan. O ni ile la ti n ko ẹṣo rode ni ọrọ Naijiria ba de bayii pẹlu ijiya to tọ si ẹnit o ba huwa aitọ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58296756
yor
politics
Femi Fani-Kayode: Wákàtí mẹ́fà ààbọ̀ ni EFCC fi gbà mí ní àlejò pẹ̀lú àpọ́nlé àti ìjáfáfá
Minisita nigba kan fun igbokegbodo ọkọ ofurufu ni Naijiria, Femi Fani-Kayode, ti sọ pe ajọ EFCC ko mu oun si ahamọ. Ninu ọrọ kan ti Fani-Kayode kọ si ori ayelujara Instagram rẹ ni alẹ ọjọ Iṣẹgun lo ti ṣalaye pe, ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, kọ iwe si oun lati yọju si ọfiisi rẹ. Eyi si lo mu ki oun wọ ọkọ baalu wa si ipinlẹ Eko lati ṣe bẹẹ. Fani-Kayode sọ pe ni nkan bi aago meji ọsan ni oun de ọfiisi naa, ti oun si kuro ni aago mẹjọ abọ alẹ. O ni pẹlu apọnle ati ijafafa lẹnu iṣẹ ni awọn oṣiṣẹ ajọ naa fi ba oun ṣe. Ọsan ọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade pe ajọ EFCC mu Fani-Kayode fun ẹsun iwe yiyi lati fi tan ile ẹjọ nipa eto ilera rẹ. Fani-Kayode n koju igbẹjọ ẹsun kiko owo ilu jẹ lọna aitọ. Laipẹ ni iroyin gba ori ayelujara kan pe ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede Naijiria, EFCC ti tẹ Ọgbeni Femi Fani-Kayode. Iroyin naa ni pe EFCC pe e lati fọrọ wa a lẹnu wo lori akọsilẹ eto ilera ti wọn ni pe o jẹ ayederu to se ki o le fi sa lasiko to n jẹ ẹjọ nile ejẹ giga ipinlẹ Eko. Ileese amohunmaworan Channels ti fi idi ọrọ yii mulẹ. Iroyin naa ni pe nkan bii aago kan ọsan ni Femi Fani Kayode de si ọgba EFCC to wa nipinle Eko pẹlu agbẹjọrọ rẹ. Ajọ EFCC ni pe awọn yoo fi atẹjade sita ni kete ti ifọrọ wanilẹnuwo naa ba yọri sibi kan. Koko ẹjọ naa tẹlẹ ni pe wọn fi ẹsun kan Fani Kayode pe o se magomago owo to le ni bilionu merin o le ọgọrun un mẹfa naira . Adajo Daniel Osiagor nile ẹjọ giga ipinlẹ Eko ni igbẹjọ naa wa niwaju rẹ. Ni ọjọ kẹtala, osu kẹwaa ni Adajo naa ni ki Femi Fani Kayode san igba egbẹrun naira gẹgẹ bii owo itanran pe ko yọju niwaju ile ẹjọ bi o se yẹ,. Adajo ni ti ko ba san owo itanran naa ki wọn da beeli idure re pada. Saaju ni wọn ni minista naa ti fi iwe ransẹ pe dokita rẹ ni ko sinmi sile ko ma jade nitori ilera rẹ
https://www.bbc.com/yoruba/media-59391113
yor
politics
Mi ò ṣé ìpàdé pẹ̀lú àwọn gómìnà PDP G-5 ní London – Tinubu
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Tinubu ti sọrọ lori awuyewuye to n lọ pe awọn gomina kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti buwọlu oun gẹgẹ bi ẹni ti wọn maa dibo fun. O ni gbogbo iroyin pe awọn ṣe ipade pọ niluu London ko yẹ ko jẹ ohun ti yoo mu ẹjọ dani nitori gẹgẹ bi oloṣelu ko si ẹni ti oun ko le ba ṣe ipade. Tinubu ni irọ to jina sotọ ni iroyin naa nitori ko si nnkan to jọ mọ bẹ rara. Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Tunde Rahman fi lede ni iroyin ofege nipa ipade naa lo ni erongba buruku, ti o yẹ ki wọn yi danu. O tẹsiwaju pe ohun ti oun gbajumọ lasiko yii ni ipolongo oun nikan bayii ati bi oun yoo ṣe bori ninu eto idibo aarẹ to n bọ, eyi ti yoo fun ni anfani lati mu ileri to ṣe fun awọn orilẹede Naijiria wa si imusẹ. Tinubu ni oun wa si ilu London lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kejila lati simi fun igba diẹ ko to morile orilẹede Saudi Arabia fun Umrah. “Gẹgẹ bii mo ṣe maa ṣe ni ipari ọdun, mo gba isinmi lati lọ si Umurah. “Nigba ti mo wa niluu London, mo n ka awọn iroyin ofege pe mo ṣe ipade pọ pẹlu awon gomina lati ninu ẹgbẹ oṣelu PDP. “Erongba iroyin ofeege yii no ko dara rara, awọn oloṣelu kan lo fẹ tẹ arawọn lọrun. Tinubu ni gẹgẹ oloṣelu, oun ni ẹtọ lati ṣe ipade pẹlu ẹnikẹni ti yoo ba wulo fun iponlogo oun ati bii oun yoo ṣe di aarẹ. Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ní òun àti àwọn gómìnà akẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́rin tó kù tí wọ́n ń pe ara wọn ní G5 kò ì tíì fẹnukò pẹ̀lú olùdíje sípò ààrẹ kankan gẹ́gẹ́ bí ẹni tí àwọn máa tẹ̀lé ní ọdún 2023. Àwọn G-5 ọ̀hún ni gómìnà Seyi Makinde ti ìpínlẹ̀ Oyo, Samuel Ortom ti Benue, Ifeanyi Ugwuanyi ti Enugu, Okezie Ikpeazu ti Abia àti Nyesom Wike fúnra rẹ̀. Ẹ ó rántí pé láti ìgbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ti ṣètò ìdìbò abẹ́nú láti yan ẹni tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ náà níbi tí Alhaji Atiku Abubakar ti gbégbá orókè ni awuyewuye ti ń wáyé láàárín àwọn gómìnà náà àti PDP. Ohun tí wọ́n ń bèèrè fún ni pé kò yẹ kí ipò ààrẹ wá láti ẹkùn árìwá kí alága ẹgbẹ́ náà tún wá láti árìwá tí wọ́n sì ní kí alága ẹgbẹ́ Iyorcia Ayu kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ tí wọn kò sì ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje wọn. Láti ìgbà náà ni ẹnu ti ń kùn wọ́n wí pé àwọn gómìnà ń gbèrò láti ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje mìíràn àti wí pé ìdúnàádúrà ti ń wáyé láàárín wọn àti àwọn olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú mìíràn. Ìròyìn tilẹ̀ ti ń lọ pé wọ́n ti fẹnukò pẹ̀lú olùdíje kan pàtó. Àmọ́ gómìnà náà ti wá ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà wí pé àwọn kò ì tíì buwọ́lu àdéhùn kankan pẹ̀lú olùdíje kankan. Wike nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ òpópónà Eneka-Igbo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló mọ̀ wí pé tí òun bá fẹ́ ṣe nǹkan, òun máa ṣe ni. Ó ní tí òun bá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ lórí ẹni tí àwọn máa dìbò fún gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà òun máa fi ìpinu òun léde àti pé òun kò ní kọ̀ láti gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ òun. Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti fi àwọn gómìnà náà lọ́rùn sílẹ̀ àti òun fẹ́ gbádùn ara òun pẹ̀lú àwọn ẹbí òun nígbà tó jẹ́ wí pé òun kò du ipò kankan lọ́dún tó ń bọ̀. Wike tún fẹ̀sùn kan alága ẹgbẹ́ PDP pé ó ń yọ ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn gómìnà APC àmọ́ tó kọ̀ láti mú ìlérí ṣẹ pé alága ẹgbẹ́ àti ààrẹ kò ní wá láti ẹkùn kan náà.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c517dw0lzzzo
yor
politics
Discover Nigeria: Buhari ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìwé tó sọ nípa ẹ̀wa Nàìjíríà ṣáájú ayẹyẹ òmìnira
Yoruba bọ, wọn ni alara nii gb'ara ga, bi adiẹ ba fẹ wọle, a bẹrẹ. Bi ayẹyẹ ọdun mọkanlelọgọta ti orilẹede Naijiria gba ominira ṣe ku ọjọ kan, Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe ifilọlẹ iwe kan to sọ nipa ẹwa, awọn ibi irinajo afẹ ati ohun manigbagbe ninu itan Naijiria. Oludamọran fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Femi Adesina to fi ọrọ yii lede ṣalaye pe akọwe iwe naa ni ''DISCOVER NIGERIA'' eleyi to tumọ si ṣe awari Naijiria. Adesina ni ayafọto aarẹ Buhari, Bayo Omoboriowo, lo kọ iwe naa eyi to sọ nipa irinajo Naijiria lati igba ominira titi di akoko yii. Iwe naa to ni ewe to din mẹjọ ni irinwo(392) lawọn eeyan ti sọ pe yoo wa lara awọn to lamilaaka julọ ninu lagbaaye. Iwe yii sọ nipa awọn ọba alaye, oriṣiiriṣii ẹya, ilẹ oko Naijiria ati okun ti Eledua fi jinki Naijiria. Omoboriowo ṣalaye pe iwe naa wa lara awọn eto lati fi ṣe ayẹyẹ ọgọta ọdun ominira orilẹede Naijiria. Yàtọ̀ sí ọkọ Dora Akunyili, wo àwọn ibòmìí tí wọ́n tún ti pààyàn ní Anambra lọ́jọ́ kan nàá Kí ló mú kí agbẹjọ́rò àgbà yọ ọwọ́ nínú ìgbẹ́jọ́ Dibu Ojerinde ọgá JAMB tẹ́lẹ̀? Àwọn Oba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí Oba míràn jẹ lójú ayé wọn Awọn ọdọ to le lọgọta ni wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu Omoboriowo lori ati kọ iwe naa. Ayẹyẹ ifilọlẹ iwe ọhun nile iṣẹ ijọba l'Abuja yoo tun ṣe afihan oriṣiiriṣii iṣẹ ọna lati ẹkun idibo mẹfa to wa ni Naijiria. Koda oriṣiiriṣii ounjẹ awọn ẹya to wa ni Naijiria naa ko ni gbẹyin nibi ayẹyẹ ọhun. Olori orilẹede Naijiria tẹlẹ. ajagun fẹhinti, Abdulsalami Abubakar, lo kọ ọrọ iṣaaju fun iwe naa. Minisita eto iroyin ati ọrọ aṣa, Lai Mohammed lo kọ ọrọ ifihan fun iwe ọhun. Koda, olori ologun Naijiria to tun jẹ aarẹ ologun orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Ibrahim Babangida naa ti ka iwe ọhun ti o si gboṣuba rabandẹ fawọn onkọwe Omoboriowo atawọn to ṣiṣẹ pọ pẹlu rẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58746057
yor
politics
Edo Election 2020: Obaseki gba ìwé-ẹ̀rí moyege gẹ́gẹ́ bí gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn
Ajọ eleto idibo INEC ti fun Gomina Godwin Obaseki ni iwe-ẹri moyege lẹyin to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ EDo to waye lọjọ Abamẹta to kọja. Obaseki fẹyin oludije APC, Osagie Ize-Iyamu gbalẹ ti o si ṣe bẹẹ wọle ibo gomina fun saa keji. Gomina Obaseki to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP lo ni ibo to pọju ninu idibo naa. Kọmiṣọnna INEC fun ipinlẹ Edo, Rivers ati Bayelsa, Arabinrin May Agbmuche-Mbu lo fun ni iwe-ẹri ọhun lọjọ Iṣẹgun ni ilu Benin. Agbmuche-Mbu ko ṣai lu gbogbo awọn ti ọrọ kan lọgọ ẹnu to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo fun aṣeyọri eto idibo ọhun. Wo ìdí tí ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo ṣe lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ Godwin Obaseki wọle ibo gomina ipinlẹ Edo ninu eto idibo to lọ ni irọwọ-rọsẹ kaakiri ipinlẹ naa lọjọ Abamẹta. Obaseki to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP fẹyin oludije APC Osagie Ize-Iyamu gbalẹ ninu idibo ọhun ti o si wọle lẹẹkeji. Ohun to ya ọpọ eeyan lẹnu ni pe edto idibo naa lọ ni wọọrọwọ laisi rogbodiyan papaa julọ pẹlu gbọmisi omi o too to ti waye laarin laarin awọn ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ṣaaju ibo naa. Onwoye nipa eto idibo, Ọmọwe Dikrullahi Yagboyaju to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye ohun to ṣe okunfa alaafia to jọba ninu eto idibo gomina ipinlẹ Edo. Ọmọwe Yagboyaju sọ pe nkan koko mẹta lo mu ki eto idibo Edo kẹsẹjari lai si rogbodiyan. Ekinni ni pe gbangba laṣa ta ni eto iforukọsilẹ awọn oludibo, eto idibo, akojọpọ ibo ati ikede esi ibo,. Ọmọwe Yagboyaju ni eto idibo naa lọ ni irọwọ rọsẹ nitori gbogbo awọn ti ọrọ kan bi ajọ INEC, awọn ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo tẹle alakalẹ ofin eto idibo. O fikun ọrọ rẹ pe niwọn igba ti awọn ti ọrọ kan ninu eto idibo ko ba ri ara wọn pe awọn ju ofin lọ, ko le si rogbodiyan ninu iru eto idibo bẹẹ. Àjọ INEC ò gbọdọ̀ kéde pé ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo kò yanjú- Wike kìlọ̀ Alaga igbimọ ẹgbẹ oṣelu PDP to n ri si eto ipolongo eto idibo gomina ipinlẹ Edo to tun jẹ gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ti kilọ fun ajọ eleto idibo INEC pe ko maa kede wi pe eto idibo naa ko yanju. Wike rọ ajọ INEC lati ṣe afihan ohun gbogbo ti wọn ba fẹ ṣe lori eto ibo gomina Edo lai fi igba kan bọkan ninu. Gomina ipinlẹ Rivers ni awọn oṣiṣẹ eleto aabo gbọdọ ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ ki wọn si maa faye gba ẹnikan kan lati da eto idibo naa ru. Wike ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo ko si lọpọlọpọ ibudo ti wọn ti n ko esi idibo jọ eleyi to sọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ. Wike sọ pe oun nigbagbọ pe ajọ INEC ko ni ba orukọ ara jẹ, yoo si sẹ eto idibo naa ni aṣeyọri ti alakan n ṣe epo. Lakotan, gomina ipinlẹ Rivers ni oun ti ẹgbẹ PDP ko fẹ gbọ ni pe ki INEC kede ibo gomina Edo pe ko fori sọ ibi kan. Wo bí èsì ìdìbò ìpínlẹ̀ Edo ṣe ń jáde Eto idibo ti pari ni ipinlẹ Edo bayii, ohun ti awọn oludibo atawọn onwoye n foju sọna fun bayii ni esi idibo lati mọ ẹni ti yoo maa ṣe akoso iṣejọba ni ipinlẹ naa fun ọdun mẹrin. O kere ta ijọba ibilẹ mejila ninu mejidinlogun to wa ni ipinlẹ ni yoo kopa ribiribi lonii lati yan ẹni ti yoo di gomina wọn gẹgẹ bi gomina to wa lori alefa lọwọlọwọ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP yoo ṣe maa gbena woju oludije ti ẹgbẹ oṣelu APC, Pasitọ Ize-Iyamu. Bo tilẹ jẹ pe nibẹrẹ pẹpẹ, oludije mẹrinla lo wa ṣugbọn awọn oluwoye ti wo o fin fin pe gbogbo awọn toku ti bila to si ti ku ija laarin erin meji, PDP ati APC. Awọn ijọba ibilẹ ti iroyin n s pe idibo oni yoo ti waye ni Egor, Ikpoba/Okha, Oredo, Ovia North-East, Ovia South-West, Uhunmwode, Akoko Edo, Owan West, Owan East, Etsako East, Etsako West ati Etsako Central. Ẹgbe oṣelu Peoples Democratic party ti ni ki awọn ọlọpaa jawọ ninu idunkoko mọ awọn Gomina ẹgbẹ naa to wa ni ipinlẹ Edo fun idibo Gomina nibẹ. Ninu atẹjade kan ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Kola Ologbondiyan fi sita o ni iwa yi ko bojumu nitori awọn ọlọpaa ko dẹgun le awọn Gomina APC to wa fun idibo Edo. Ologbondiyan to ni alaga ẹgbẹ Uche Secondus koro oju si iwa awọn ọlọpaa yi ni ọna lati da wahala silẹ ni wọn n ba bọ. Pdp sọ pe o jẹ iyalẹnu fawn pe awọn ọlọpaa ko de ọdọ awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu APC bi Gomina Abdullahi Ganduje ti Kano ati akẹgbẹ rẹ Hope Uzodinma ipinlẹ Imo. Wọn ni bẹẹ naa ni igbakeji aar ile aṣofin agba Sẹnetọ Ovie Osagie naa n yan fanda kiri ile alaga ẹgbẹ APC tẹlẹ Adams Oshiomole. Ileeṣẹ ọlọpaa ko ti fesi sọrọ yi bẹẹ naa si ni APC naa ko ti fesi. Idibo Gomina ipinlẹ Edo yoo waye lọjọ Kọkandilogun oṣu Kẹsan nibi ti Gomina Godwin Obaseki ati Pasitọ Ize-Iyamu yoo ti jọ maa figa gbaga.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-54209920
yor
politics
Ajimobi: Obaseki, Ambode àtàwọn gómìnà míràn tí tírélà gba ààrín àwọn àtàwọn bàbá ìsàlẹ̀ wọn kọjá
Awọn ‘Baba Isalẹ’ ni eto oṣelu Naijiria ni ọpọlọpọ eniyan gbagbọ wi pe wọn kii dije dupo fun ara wọn, Amọ awọn ni o maa n sọ nipa ẹni ti yoo bori tabi ti yoo kuna ni idibo sipo lagbegbe wọn. Gẹgẹ bi eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo ati ipinlẹ Edo ṣe ti n sunmọle bayii, awọn Baba Isalẹ yii ni wọn n sọ bi o ṣe maa ri. Awọn Baba Iṣalẹ yii ni wọn maa n lo owo ati ipọ wọn lati fi gbaruku ti ẹni ti wọn ba tilẹyin ninu ididbo naa. Awọn eniyan lo gbagbọ pe ẹni to ba ni Baba isalẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria ni anfaani lati dije dupo ti wọn yoo si bori, bi wọn ko tilẹ ni ọpọlọpọ imọ nipa oṣelu. Saaju idibo sipo gomina ni ipinlẹ Edo ni Osu Kẹwaa, Odun 2020, ohun to gba ẹnu awọn eniyan kan ni ija to bẹ silẹ laarin Adams Oshiomọlẹ ati Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki. Ni ọdun 2016 ni Obaseki deede yoju si gbagede oṣelu Naijiria lẹyin ti Adams Oshiomole gbe e wa lati ilu Eko nibi ti o ti n ṣiṣẹ, ti ọpọ eniyan ko si mọ ọ ni gbagede oṣelu ipinlẹ Edo. Iroyin gbe e wi pe lasiko idibo sipo gomina ni ọdun 2016 naa ni Gomina Adams Oshiomole gbe ipolongo rẹ kari, Nibe naa lo si ti n logun rẹ fun awọn eniyan nigba naa lati tako Pasito Osagie Ize-Iyamu to n dije dupo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP. Nibayii, ti ọdun mẹrin miran ti de, ọpọlọpọ nkan ti yi pada, Adams Oshiomọle ti le Obaseki kuro lẹgbẹ Oṣelu APC Eyi waye lẹyin ti o fi lede wi pe oun naa fẹ dije dupo gomina fun saa keji lẹgbẹ oṣelu APC. Ibaṣepọ laarin awọn mejeeji ti fori sanpọn, ti Obaseki si ti mura lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣẹlu PDP. Ohun itiju lo jẹ fun Gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambode lasiko idibo sipo gomina ni ipinlẹ Eko lọdun 2019 nibi ipolongo kan. Eyi sele nigba ti baba isalẹ rẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu na ọwọ Babajide Sanwo-Olu sọke gẹgẹ bi oludije sipo gomina ni ipinlẹ Eko lẹyin to ni ki Ambode lo rọọkun nilẹ lẹyin ọdun mẹrin to lo nipo. Amọ, ohun ti awọn eniyan sọ ni pe, bi Tinubu ṣẹ na ọwọ rẹ soke ni idibo sipo gomina lọdun 2016 lasiko ti ko si ẹni to mọ ọ rara, ti ko tilẹ di ipo ọṣelu kankan mu tẹlẹ ki o to di igba naa. Nigba naa, gomina to wa nibẹ, Babatunde Fashola fẹ ki kọmisọnna fun eto idajọ nipinlẹ naa, Supo Shasore dije dupo sipo gomina lasiko naa, Amọ Tinubu kọ jalẹ pe Ambode ni yoo ṣe gomina naa pẹlu gbogbo agbara rẹ. Ọdun 2019 ni idibo gbogboogbo naa ni Babajide Sanwo-Olu naa fi idi Ambode janlẹ ninu idibo abẹlẹ saaju idibo sipo gomina naa, amọ Ambode si wa ni ẹgbẹ oṣelu APC. Rashidi Ladoja jẹ gomina ipinlẹ Oyo ni ọdun 2003 si ọdun 2007, ti Adedibu si ṣe agbatẹru fun Ladoja gẹgẹ bi oludije lẹgbẹ oṣelu PDP ni ọdun 2003, ti o si ran an lọwọ lati bori. Ladọja fun ara rẹ fi idi ẹ mulẹ fun ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Human RIghts Watch pe Adedibu ṣe bẹbẹ lasiko idibo lati jẹ ki o bori idibo naa. Amọ o ni bi oun ṣe wole ni o gbe igbesẹ lati gba ara rẹ lọwọ Adedibu, ti oun ko si tẹle awọn ilana rẹ mọ. Ladọja ni oun kọ lati jẹ ki Adedibu lu owo ipinlẹ naa ni ponpo lẹyin ti Adedibu ni ki oun maa fi ida marundinlọgbọn owo Security Vote to to miliọnu marundinlogun Naira si apo oun ni oṣoosu. Bakan naa ni Ladoja kọ lati jẹ ki Baba iṣalẹ rẹ fi orukọ silẹ fun awọn Kọmisọnna ti wọn yoo jọ ṣe ijọba. Ninu ọrọ tirẹ, Adedibu ni alaamọrẹ ẹda ni Ladọja, ti o si saa gbogbo ipa rẹ lati jẹ ki o kuro nipo gomina nipinlẹ naa, amọ o lo saa rẹ tan, idibo miran ni ko bori ninu rẹ mọ. Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje naa ti pin gaari pẹlu baba isalẹ rẹ, Rabiu Kwankwaso to ṣe agbatẹru fun un lasiko idibo sipo gomina ni ọdun 2016. Ganduje sọ wi pe idi ti oun fi yapa kuro labẹ Kwankwaso ni pe o jẹ ẹni ti imọtara ẹni nikan n da laamu. O fẹsun kan an wi pe nitori o jẹ baba isalẹ fun awọn, o fẹ gaba lẹ wọn lori, ki o si sakoso gbogbo nkan to n wọlẹ si ipinlẹ naa fun ara rẹ nikan. Amọ, Kwankwanso naa lo fa ọwọ rẹ soke ni idibọ ọdun 2016. Ọpọlọ̀pọ eniyan lo gbagbọ wi pe Godswill Akpabio ni baba isalẹ fun wọn ni ipinlẹ Akwa Ibom. Amọ ija to de lorin di owe laarin Gomina ipinlẹ naa, Udom Gabriel ati Akpabio lẹyin to kuro ni ẹgbẹ oselu PDP lọ si ẹgbẹ oṣelu APC. Ohun to han gbangba ni si awọn eniyan pe Udom di gomina ipinlẹ Akwa Ibom nitori ibaṣepọ rẹ pẹlu Baba isalẹ Akpabio ti o gbe le ejika lati dije dupo gomina ni ọdun 2015 to si yege. Amọ ni bayii wọn ko foju rinju mọ lẹyin ti Udom yẹba fun Akpabio, eleyii to fa gbọnmi si omi o to laaarin wọn , ki wọn to pin gari, ti Akpabio si fi PDP silẹ lọ si APC.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53078020
yor
politics
Xi Jinping kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àkọ́kọ́ tó ṣe sáà kẹta ní China
Aarẹ orilẹede China, Xi Jinping ti sọ pe “gbogbo agbaye nilo China”. O sọ eyi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to kede ara rẹ̀ faraye gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àkọ́kọ́ tó ṣe sáà kẹta ní China. “China ko lee ri idagbasoke lai si gbogbo agbaye bẹẹ si ni gbogbo agbalaaye naa nilo China”.\nXi sọ eyi lẹyin ọpọlọpọ ọdun akitiyan fun atunto to le ni ogoji ni China. Xi Jinping, aarẹ China ti di ẹni akọkọ to ṣe saa mẹta nipo arẹ orilẹ-ede naa. Owurọ ọjọ Aiku ni ikede naa waye nibi eto kan nilu  Beijing. Nibi eto naa ni Jinping tun ti kede awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ tuntun ti yoo ba a ṣe saa kẹta ọhun. Lara awọn to kede ni oloye kan ninu ẹgbẹ oṣelu Communist, Li Qiang, ẹni ọdun mẹtalelọgọta, ti yoo duro gẹgẹ bi igbakeji rẹ (olootu ijọba) nigba ti Li Keqiang ba fi ipo naa silẹ loṣu Kẹta, ọdun 2023. Eeyan marun-un mii lo tun yan sinu igbimọ alaṣẹ naa – Zhao Leji, Wang Huning, Cai Qi, Ding Xuexiang ati Li Xi. Amọ iroyin to n lọ ni pe gbogbo awọn to yan sinu igbimọ oluṣakoso naa lo jẹ awọn to n wáríí fun, to n ṣe baba rere, baba kẹ̀ fun. Onimọ eto oṣelu kan nilẹ America sọ pe igbesẹ Xi tumọ si pe “ẹnikẹni ko ni le yẹ ẹ lọwọ wo to ba gbe igbesẹ ti ko yẹ”. Bakan naa ni gbogbo aṣẹ lori igbimọ naa ati awọn igbimọ oludari ẹgbẹ oṣelu Communist. Ikede ifinijoye naa waye lẹyin ọjọ ipade gbogboogbo ẹgbẹ Communist , nibi ti wọn ti ṣe atunsẹ si awọn ilana ẹgbẹ naa lati le fi ontẹ lu saa kẹta Ọgbẹni Xi, ati awọn ojuṣe rẹ si ẹgbẹ. Xi Jinping ree, pẹlu eeyan mẹfa to yan lati ṣe iṣakoso saa kẹta pẹlu rẹ. Wọn bi Xi Jinping ni ọdun 1953, o si jẹ ọmọ ẹnikan lara awọn to pilẹ ẹgbẹ oṣelu Communist. Ọdun 2012 ni Jinping de ipo aarẹ orilẹ-ede China, lẹyin ti aṣiwaju rẹ Hu Jintao yan an. O ti kọkọ ṣe igbakeji aarẹ Hu Jintao lọdun 2008. Lati igba to ti de ipo naa lo ti wa agbara mọ aya, ti oun nikan si n da a paṣẹ tako ilana ijọba ajumọṣe ti wọn n lo tẹlẹ lati aye Mao Zedong. Ni ọdun 2018, labẹ iṣakoso rẹ ni awọn adari ni China dibo lati pa ofin ti wọn ti n lo lati ọdun 1990, ti ko faaye gba ju saa meji lọ nipo aarẹ. Inu oṣelu ẹgbẹ communist ni wọn bi Xi si, nitori pe baba rẹ, Xi Zhongxun jẹ ọmọ ẹgbẹ naa, to si ti dari ẹkun Guandong ri. Bi i baba rẹ, Xi Jinping naa gbajumọ fun gbigbogun ti iwa ibajẹ, idagbasoke ọrọ aje, ati riri daju pe agbara ko kuro lọwọ ẹgbẹ oṣelu naa.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c723v777301o
yor
politics
Samuel Ortom: A ti fi kún owó ìtanràn fún ẹni tó ba da ẹran jẹ̀ nígboro Benue- Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue
Ẹnikẹ́ni tó bá daranjẹ ko láàárín ìgboro yóò san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Náírà - Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue, Samuel Ortom Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue Samuel Ortom tí buwọ́lu àtúnṣe sí òfin tó sọ dída ẹran jẹ̀ ní ìta gbangba di èèwọ̀ àti ìdásílẹ ibùjẹ ẹran ti ọdún 2017. Òfin yìí ti wá fi òté le wí pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú pé ó da ẹran láàárín ìlú tàbí ẹsẹ̀ kùkú tàbí apá ibì kankan fún ìgbà àkọ́kọ́ ní Ìpínlẹ̀ náà yóò san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Náírà. Kini ofin yii yoo ṣe bayii? Bákan náà ni òfin yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú fún ẹ̀ṣẹ̀ kan náà fún ìgbà kejì yóò san mílíọ̀nù kan Náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn. Nígbà tó ń buwọ́lu òfin náà ní Ọjọ́ bọ̀, ní gbọ̀ngán Banquet ilé ìjọba ní ìlú Makurdi, gómìnà Ortom ní àwọn ṣe àfikún àwọn owó ìtanràn látàrí bí ohun gbogbo ṣe rí lọ́wọ́ yìí lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ijiya wo lo wa tọ si arufin yii? Ortom ni fún ìdí èyí, màlúù kan tí wọ́n yóò gba ìdáǹdè rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún méjì Náírà tẹ́lẹ̀ ti di ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta Náírà báyìí látàrí bí owó àwọn ohun tí wọ́n fi ń tọ́jú àwọn màlúù náà ni àyè tí wọ́n ń kó wọn sí ti gbówó lórí. Bákan náà ni òfin yìí ṣe àlàkakẹ̀ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá tàbí sísan owó ìtanràn mílíọ̀nù márùn-ún Náírà fún ẹni tí ó bá ní kí àwọn ọmọdé máa dá ẹran láàárín ìgboro. Àwọn owó ìtanràn mìíràn ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta Náírà lórí màlúù kan, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lórí Ẹlẹ́dẹ̀ kan àti ẹgbẹ̀rún kan Náírà lórí adìẹ. Gómìnà tún ṣàlàyé pé ẹni tí wọ́n bá mú nǹkan ọ̀sìn rẹ̀ tí kò sì wá gbà á ní ọjọ́ náà yóò san àlékún ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún Náírà, tí kò bá sì wá gbà á lẹ́yìn ọjọ́ méje, òfin fàyè gba ìjọba láti lu nǹkan ọ̀sìn bẹ́ẹ̀ ní gbàǹjo. Ṣaájú ni gómìnà Ortom ti tẹ́ pẹpẹ òfin náà síwájú ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ náà fún àtúnṣe lójúnà à ti wá ojútùú sí àwọn tó ń tẹ òfin náà lójú mọ́lẹ̀. Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun to kọjá ní ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Benue buwọ́lu òfin náà lẹ́yìn ìjíròrò gbogbo ilé.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60083893
yor
politics
APC vs PDP: Òótọ́ ni pé Gbanga Daniel ti kúrò ní PDP, ṣùgbọ́n kii ṣe tuntun - Agbẹnusọ PDP
Alukoro ẹgbẹ oṣẹlu PDP ni Naijiria, Kola Ologbondiyan ti sọ pe o ti to ọdun diẹ ṣeyin ti gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Gbenga Daniel ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu naa. Ologbondiyan lo ṣalaye ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC. Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ gbode pe Gbenga Daniel ṣẹṣẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣugbọn alukoro ẹgbẹ na sọ pe ko ṣẹṣẹ gbe igbesẹ naa nitori ni kete ti idibo Aarẹ pari lọdun 2019 lo fi ẹgbẹ naa silẹ. Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye "aarin ọsẹ ti a pari eto idibo tan lọdun 2019 ni Ọtunba Gbenga Daniel kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, to si sọ pe oun ko ṣe ẹgbẹ oṣelu kankan mọ." "Ṣugbọn ni nnkan bi ọdun kan ṣeyin lo sọ ni gbangba pe awọn alatilẹyin oun ke si oun pe ki oun ko wọn lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC." Ologbondiyan ṣalaye pe gomina tẹlẹ ọhun sọ pe oun gba lati ṣe ohun ti awọn alatilẹyin oun n fẹ, nitori naa kii ṣe pe ó kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ si APC. Alukoro ẹgbẹ PDP naa sọ siwaju si pe loju awọn, Gbenga Daniel ko fi ẹgbẹ PDP silẹ lọ si APC, "ṣugbọn o fi ẹka ẹgbẹ APC kan silẹ lọ sinu ẹka ẹgbẹ APC miran ni." Ologbondiyan sọ pe ẹgbẹ APC ti pin si ọna mẹrin, nitorin naa, awọn ọmọ APC ni ọrọ naa ye. O pari ọrọ rẹ pe amọran awọn alatilẹyin Gbenga Daniel ni o tẹle. Ni ti pe boya iyapa tabi rukerudo wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, Ologbondiyan sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/56101912
yor
religion
Polygamy: Ẹ wo pásítọ̀ tó fẹ́ omidan mẹ́rin lẹ́ẹ̀kàn náà! Ó ní kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀
Bíbéli mi ló sọ pé kí n fẹ́ ìyàwó omidan márùn ún, kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀- Pásítọ̀ Pasitọ kan lorilẹede Congo ti ṣe ohun ti ẹnikan ko ṣe ri, o fẹ iyawo mẹrin ni ẹẹkan naa, lẹyin to ti ni ẹyọkan si ilẹ tẹlẹ. Pasitọ Zagabe Chiluza lati orilẹede Congo ni awọn eniyan n sọrọ nipa rẹ lori ayelujara lẹyin to ṣe iyawo alarede fun obinrin mẹrin lẹẹkan naa. Pasitọ Chiluza lo kọkọ ni iyawo ẹyọkan ki o to wa pa ero rẹ da to si fẹ omidan ti wọn ko i tii ja abale rẹ mẹrin, pẹlu idaniloju pe inu Bibeli ni oun ti ri ero naa. Pasitọ naa rọ awọn ọmọlẹyin Kristi lati ṣe bi oun, ki wọn si di alaya pupo nitori awọn omidan ti wọn ko i tii ja abale wọn ni awọn ọkunrin ni ile ijọsin oun ma n fẹ. Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin AfriMax English ṣe gbe jade, pasitọ naa fi apẹrẹ han lati inu Bibeli to fihan pe kii ṣe ẹṣẹ fun awọn eniyan lati fẹ ju iyawo kan lọ. Ni ọjọ igbeyawo rẹ ni pasitọ naa sọ wi pe 'Mo ti ni iyawo kan tẹlẹ amọ ma a fẹ awọn mẹrin yii loni, ti wọn yoo si darapọ mọ iyawo akọkọ to wa ni ile.'' O fikun un pe fifẹ iyawo pupo wa lati inu ẹsẹ Bibeli. 'Jacob ni iyawo pupọ to fi mọ Leah ati Rachel, Bilha ati zilpa... iyawo mẹrin fun ọkunrin kan.'' Kini iriri Zagabe? Zagabe ni ọdun 1986 ni oun fi aye oun fun Jesu ti oun si sọ fun awọn alejo pe inu oun dun lati ni iyawo marun un. Iroyin fikun un pe omidan ti ko mọ ọkunrin ri ni awọn omidan mẹrin ti pasitọ fẹ ni ẹẹkan naa.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61249248
yor
religion
Shiite: Kò ní sí ìwọ́de mọ́ yíká Nàíjíríà láti bu ọ̀wọ̀ fáwọ̀n èèyàn tó dá sí wa
Ẹgbẹ Shiite ti kede pe oun ti wọgile awọn iwọde gbogbo loju popo ilu Abuja, eyi to ni se pẹlu itusilẹ olori wọn, Ibrahim El-ZakZaky. Igbesẹ yii lo waye lẹyin wakati mẹrinlelogun ti ọga agba ọlọpa nilẹ yii, Mohammed Adamu kede ijọba ti fofin de ẹgbẹ Shiite. Atẹjade kan ti ẹgbẹ Shiite fisita sisọ loju rẹ pe, oun gbe igbesẹ naa lọna ati faaye gba iwadi nipa isoro to n koju wọn, paapa ẹjọ tawọn agbẹjọro awọn gbe ls sile ẹjọ eyi to da lori bijọba apapọ se kede pe oun ti fi ofin de ẹgbẹ ẹlẹsin musulumi naa. "A gbe igbesẹ naa pẹlu igbagbọ nla ati ọwọ taani fun awọn eeyan iyi ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti wọn da si ọrọ yii, a si lero pe wọn yoo wa ọna lati yanju awọn aawọ to wa nilẹ nitubi n nubi, paapa lori bi wsn se ti asaaju wa mọle lati bii ọdun mẹrin sẹyin." "Ti ifẹhonu han kankan ba si waye nibikibi lorilẹede yii, a jẹ pe atẹjade yii ko tii tẹ awọn to wa nibẹ lọwọ ni, tabi pe wọn si ọrọ yii gbọ abi awọn agbofinro lo wa nidi isẹlẹ naa, gẹgẹ bi wsn ti n se lati latẹyinwa lati ta ẹrẹ si asọ ala wa, lọna ati mu kawọn eeyan maa fi oju arufin wo wa, dipo oju awọn eeyan ti wọn n fi iya jẹ lati ọdun 2015." Atẹjade naa tun wa n dupẹ pupọ lọwọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ẹni nilẹ yii ati loke okun, ati awọn ajafẹtọ ẹni lori ikanni ayelujara, fun bi wọn se gbe awọn iroyin to nii se pẹlu iwọde wọn sita lasiko ijagudu fun idajọ ododo naa. Ẹgbẹ Shiite tun tẹnumọ ipinnu rẹ lati wa ọna abayọ miran lati yanju isoro ọlọjọ pipẹ to n koju wọn ọhun, ti wọn si tun n beere fun itusilẹ asaaju wọn, iyawo rẹ ati ọpọ ọmọ ẹgbẹ Shiite miran to wa ni ahamọ, ti wọn si fi ẹtọ si ominira dun wọn lati ọdun 2015.
https://www.bbc.com/yoruba/49184526
yor
religion
TB Joshua: Kí ni ìdí tí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn yìí ṣe kọ̀ láti yọjú síbi ètò ìsìnkú TB Joshua?
Lẹyin iku wolii Temitope BalogunJoshua, ti ọpọ eeyan mọ si TB Joshua ni ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye ti bẹrẹ si n ṣedaro rẹ. Lara awọn eeyan naa ni awọn gomina, Aarẹ, minisita, awọn oṣere atawọn alẹnulọrọ mii lawujọ. Ṣugbọn lọjọ ti TB Joshua wọ kaa ilẹ sun ninu ijọ rẹ, Synagogue Church of All Nations, SCOAN, ọpọ awọn iranṣẹ Ọlọrun bii tirẹ ti awọn eeyan n reti nibi ayẹyẹ isinku ọhun ni ko yọju rara. TB Joshua jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta lẹyin to dari isin kan tan ni ile ijọsin rẹ lọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ti a wa yii. Ṣaaju ni ijọ SCOAN ti kọkọ kede pe eto isinku naa yoo waye laarin ọjọ karun un si ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2021, nibi ti wọn ti n reti obitibiti ero. Ẹwẹ, iyalẹnu nla lo jẹ fun ọpọ awọn bi wọn ko ṣe ri awọn iranṣẹ Ọlọrun nla-nla miran nibi ayẹyẹ isinku ọhun. Gẹgẹ bii ọrọ ti awọn eeya n sọ nibi eto isinku naa, lara awọn iranṣẹ Ọlọrun jankan-jankan ti wọn ko ri ni pasitọ agba ijọ RCCG, Enoch Adeboye, pasitọ Sam Adeyemi ti ijọ Daystar, adari agba ijọ Living Faith, Biṣọọbu David Oyedepo. Ko tan sibẹ, awọn ojiṣẹ Ọlọrun miran ti awọn eeyan ko tun ri ni adari ijọ Deeper Life, W.F. Kumuyi, Paul Enenche ti ijọ Dunamis ati Lazarus Mouka ti ijọ The Lord's Choosen. Bakan naa lawọn eeyan tun reti awọn pastọ mii bii Chris Okotie ti Household of God Church International Ministries, Tunde Bakare ti ijọ Citadel Global Community Church ati pasitọ Matthew Ashimolowo to jẹ adari ijọ Kingsway International Christian Centre. Ọpọ eeyan lo ti n woye idi ti awọn ojiṣẹ Ọlọrun wọnyi atawọn miran to lamilaaka ni Najiria ko ṣe yọju, ṣugbọn iroyin ni lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun naa ran awọn aṣoju wọn lọ sibi ayẹyẹ ikẹyin ọhun. Sibẹ, awọn eeyan jankan mii to peju sibi eto isinku naa ni Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo; aṣoju gomina ipinlẹ Eko, Olarewaju Elegushi; Aarọ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, aya Ooni Ile Ife, Olori Naomi Adeyeye; minisita tẹlẹri fun eto irinna ọkọ ofurufu, Femi Fani-kayode ati Oloye Bibopere Ajube. Ti ẹ ko ba gbagbe, ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, ati ọpọ ojiṣẹ Ọlọrun ni Naijiria ni ko sọ ọrọ kankan lẹyin iku oloogbe ọhun. Ṣugbọn CAN fi atẹjade kan lede lati ba ẹbi oloogbe naa kẹdun lẹyin nnkan bi ọjọ mẹta lẹyin iku rẹ. Mọlẹbi Wolii TB Joshua ati gbogbo ijọ Synagogue lagbaye ti fi eeru fun eeru, wọn si ti fi erupẹ fun erupẹ. Gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe isin ikẹyin fun oloogbe naa ninu ij synagogu to wa nipinlẹ Eko, wọn ti gbe e sinu ile ikẹyin rẹ laye bayii. Awọn eniyan jankanjankan ti n de si ibi isinku gbajugbaja Woli to jade laye, TB Joshua ni ẹni mẹtadinlọgọta. Lara awọn to ti de si be ni Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu to fi mọ gomina ipinlẹ Ogun, Abiodun. Bakan naa ni awọn eniyan jankanjankan lati awọn ilẹ ijọsin Kristẹni kaakiri agbaye lo ti wa nibẹ. Oni ni ọjọ ti ile ijọsin Synagogue of All Nations yoo sin oku oludasilẹ wọn, TB Joshua. Ayika ile ijọsin naa ni wọn yoo sin i si ni owurọ Ọjọ Kẹsan, Osu Keje, ọdun 2021. Lẹyin osu kan ti TB Joshua papoda ni wọn ṣeṣẹ fẹ eto isinku rẹ. Ó tó gẹ́, Sunday Igboho fẹ́ gbé ìjọba lọ ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́' Ijọ SCOAN fi atẹjade sita ni were to ku wi pe ọṣẹ kan ni wọn yoo fi ṣe eto isinku rẹ, lati ọjọ karun un , osu keje, pẹlu titan abẹla yika ilẹ adura rẹ, ti eniyan to le ni ẹgbẹrun marun un si pejọ sibẹ. Ni Ọjọ Tuesday ni Ọjọ iwuri ti awọn eniyan pejọ pọ lati sọ ohun ti wọn mọ nipa igbe aye TB Joshua. Ni Ọjọ yii ni awọn eniyan jankan jankan ni awujọ pejọ to fi mọ awọn oṣere to lamilaaka lorilẹede Naijiria jade lati wa sọ ọrọ iwuri nipa rẹ. Ayajọ asalẹ orin waye ni Ọjọru, ti awọn olorin to fi mọ Timi Dakolo, Shasha Malley lati orilẹede Ghana naa ko gbẹyin ni bẹ. Awọn eniyan pejọ ni Ọjọbọ lati wo oku rẹ nibi ti wọn tẹ si ninu ile ijọsin, ti ọpọlọpọ eniyan si n ṣe idarọ rẹ. Ọpọlọpọ lo mọ TB Joshua nitori awn iṣẹ ara ati iṣẹ iyanu ti o ma n waye ni ile ijọsin rẹ, eleyii ti o si si sọ ọ da ilumọọka kaakiri agbaye. Bi o tilẹ jẹpe ko si ẹnikẹni to mọ patọ ohun to ṣekupa, lẹyin to waasu tan ni ile ijọsin ni o wọle lọ ti wọn si ba ni ori ijoko to ti dake si.
https://www.bbc.com/yoruba/media-57773834
yor
religion
Èèyàn mẹsan an pàdánù ẹ̀mi wọn nínú ìwọ́de tako Hijab ní Iran
Ifẹhonuhan to bẹ silẹ lẹyin iku obinrin kan ti gbẹmi eeyan mẹsan-an miiran lorilẹede Iran. Obinrin to ku naa ni awọn agbofinro ti mọle nitori o tapa si ofin to rọ mọ lilo ibori lorilẹede naa. Obinrin naa si lo padanu ẹmi rẹ lẹyin to lo ọjọ mẹta nile wosan. Lara awọn to ti ba iṣẹlẹ naa lọ ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan , ẹni ti awọn agbofinro yinbọn lu, nigba ti wọn ṣe ikọlu si awọn olufẹhonuhan. Orisirisi fọnran lori ayelujara ṣe afihan bi awọn obinrin to n ṣe ifẹhonuhan ṣe ju anamọ soke, lẹyin ti wọn dana sun awọn ibori wọn. Fọnran naa ṣe afihan bi wọn ṣe pariwo pe “A ki n ṣe anamọ, a fẹ itusilẹ ati ibaradọgba akọ ati abo" Ninu ọrọ rẹ niwaju Ajọ Isọkan Agbaye, Aarẹ Joe Biden ti orilẹede Amẹrika ni awọn wa lẹyin awọn obinrin to n fi ẹhonu han naa ni Iran nitori wọn ja fun ẹtọ wọn ni. O sọrọ yii ni kete ti Aarẹ Iran, Ebrahim Raisi ni ki ajọ agbaye kọ eti ikun si ipe awọn obinrin naa to n ja fun ẹtọ wọn. Ọpọ awọn obinrin lo lewaju ifẹhonuhan ni Iran, ti wọn si n dana sun ibori wọn, ‘Hijab’, lẹyin ti ọkan lara wọn to tapa si ofin ‘Hijab’ padanu ẹmi rẹ. Ifẹhonuhan naa lo ti gbalẹ fun ọjọ marun un bayi, to si ti tan kalẹ kaakiri orilẹede naa. Mahsa Amini, obinrin kan ti awọn ọlọpa fi ẹsun kan pe o tapa si ofin to de lilo ibori si lo padanu ẹmi rẹ ni ile wosan lọjọ Ẹti. Amini yii lo ku lẹyin to ti wa ni ẹsẹkan aye ẹsẹkan ọrun (Coma) nile iwosan fun ọjọ mẹta. Ni Sari, ẹkun ariwa ilẹ Tehran, ogunlọgọ awọn obinrin lo tu sita, ti wọn si bẹrẹ si ni dana sun ‘Hijab’ wọn lati fẹhonu han. Amini ni ọwọ awọn ọlọpaa to n risi igbọran araalu tẹ ni olu ilu orilẹede naa lọsẹ to kọja. Wọn si fi ẹsun kan pe o tapa si ofin to rọ mọ pe ki obinrin gbọdọ fi nkan bo ori, apa ati ẹsẹ wọn. Iroyin naa ni awọn ọlọpaa na obinrin naa, to si daku, eyi to mu ko wa ni koma fun ọjọ mẹta. Asoju ajọ United Nation to ri ija fun ẹto ọmọniyan, Nada al-Nashif,  ni Iwadi awọn safihan pe awọn ọlọpaa naa fi kumọ naa Amina. O ni ti wọn si tun gba ori rẹ mọ ọkan lara ọkọ wọn. Awọn ọlọpaa ni awọn ko fi iya jẹ obinrin naa ati pe o kan sadede ni ijakulẹ ọkan rẹ. Mọlẹbi Amina ni ilera rẹ wa ni alaafia, ti ko si nkan to mu rara. Amini, ẹni ọdun mejilelogun wa lati Kurdistan ni ẹkun iwọ orun orilẹede Iran. Agbegbe yii si ni eeyan mẹta ti padanu ẹmi wọn lọjọ Aje nigba ti ọlọpaa sina bolẹ fun awọn olufẹhonuhan. Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ adari Ayatollah Ali Khamenei, ti orilẹede Iran sabẹwo si idile ọmọbinrin, to si ṣe ileri pe ẹlẹsẹ kan ko ni lọ la jiya lori iṣẹlẹ naa. MP Jalal Rasidi Koochi wa bu ẹnu atẹlu ihuwasi awọn agbofinro, to si ni wọn kan ko ba awọn araalu si ni lorilẹede Iran. Lẹyin ti ẹsin Islam ri ayipada lọdun 1979, awọn alasẹ lorilẹede Iran gbe ofin kalẹ lori asọ wiwọ awọn obinrin. Wọn ni wọn gbọdọ bo ori wọn, wọn ko si gbọdọ wọ asọ to fun mọra ju ni awujọ. Ẹka ọlọpaa to ri si igbọran "Gasht-e Ershad", ni wọn gbe isẹ naa le lọwọ lati ri pe awọn obinrin tẹle ofin naa. Awọn ọlọpaa ni asẹ lati da obinrin duro lati wo boya o tẹle ofin ati irufẹ asọ ti wọn ba wọ sara. Ijiya ẹsẹ fun ẹni toba tapa si ofin naa ni, owo itanran, lilọ sọgba ẹwọn ati ẹgba jijẹ. Lọdun 2014., awọn obinrin bẹrẹ lati ma ṣe afihan awọn aworan ati fọnran ara wọn ni awujọ nibi ti wọn ti n tapa si ofin naa lati fi ṣe ifẹhonuhan lori ayelujara. Ifẹhonuhan naa ni wọn pe ni   "My Stealthy Freedom". Lara awọn ifẹhonuhan ti ọpọlọpọ awọn obinrin miran ti se lori lilo ibori ni wọn pe akori rẹ ni "White Wednesdays" ati "Girls of Revolution Street".
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c4nd20n22d0o
yor
religion
Chris Oyakhilome: Wọn tí fòfin de iléeṣẹ́ ìròyìn Chris Oyakhilome lẹ́yìn tó sọ pé 5G lọ ṣokùnfà Coronavirus
Ijọba ilẹ gẹẹsi ti fofin de ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ oluṣoagutan ijọ Christ Embassy, pasitọ Chris Oyakhilome lẹyin ti wọn fẹsun kan pasitọ naa pe o n waasu tako ilana ofin wọn. Igbeṣẹ yii lo waye lẹyin ti pasitọ ọhun sọ pe nẹtiwọọki 5G lo ṣokunfa ajakalẹ arun Coronavirus. Ileeṣẹ to n mojuto igbohunsafẹfẹ nilẹ naa, Ofcom ni iwaasu naa ti awọn eeyan orilẹede Gẹẹsi ni anfani lati tẹti si lee ṣe ijamba fun wọn, nitori naa, o lodi si ofin igbohunsafẹfẹ ilẹ wọn. Bakan naa, wọn fẹsun kan ileeṣẹ amohunmaworan Loveworld to jẹ ti pasitọ naa pe o sọ pe ogun Hydroxychloroquine lagbara lati ṣegun arun Covid-19 to n ba gbogbo aye finra. Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ Ofcom fi lede, wọn ni ileeṣẹ amohunmaworan Loveworld ti gba pe wọn ko ni ṣe bẹ mọ. Ijọba ilẹ Gẹẹsi ni ijiya ileeṣẹ tẹlifiṣọn Loveworld ni pe yoo maa sọ ninu igbohunsafẹfẹ rẹ pe oun kede ọrọ ti ko ni otitọ ninu nipa arun Cpvid-19. Ileeṣẹ naa si ti fesi pe oun yoo ṣe gẹgẹ bi ijọba ti pa laṣẹ fun un. Ẹwẹ, ijọba UK atawọn onimọ ijinlẹ ti ni ko si ootọ ninu ọrọ ti awọn kan sọ kiri pe nẹtiwọọki 5G naa lee ṣokunfa arun Coronavirus. Biṣọọbu David Oyedepo ti ṣe apejuwe ijọba to wa lorilẹede Naijiria bayii gẹgẹbi egun fun orilẹede Naijiria. Biṣọọbu Oyedepo sọrọ yii lasiko to fi n waasu ni ijọ rẹ. O ni ofin tawọn aṣofin n gbero lori kẹlẹnu o ṣẹnu lori ayelujara, (social media bill) iyẹn social media bill jẹ eyi to tako ọpọlọ ati arojinlẹ. Agba iranṣẹ ọlọrun naa wa ṣalaye pe gbogbo ọmọniyan lo lẹtọ lati sọ ọrọ ẹnu wọn lai si ẹni ti yoo dawọn lẹkun. Oyedepo ni "ni iwoye temi eyi ni ohun to buru juls ti yoo ṣẹlẹ si orilẹede Naijiria, iyẹn ijọba yii. Ohun ni ijọba to buruju, koda bii egun lo ri." O ni ijọba to wa lorilẹede Naijiria bayii ko ni pato ibi to n lọ ati pe gbogbo ilana iṣejọba lo ti fẹ sọ orilẹede Naijiria da bi Ọgba ẹranko. Eyi kọ ni igba akọkọ ti Biṣọbu oyedepo yoo ma sọko ọrọ ranṣẹ si aarẹ Muhammadu Buhari ati ijọba rẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51798231
yor
religion
TB Joshua burial: Ètò ìsìnkú TB Joshua ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àṣálẹ́ àbẹ́là títàn
Ayẹyẹ eto isin idagbere ti bẹrẹ fun oloogbe Temitope Joshua ni ipinlẹ Eko ati ilu abinibi rẹ, Arigidi-Akoko nipinlẹ Ondo. Eto aṣalẹ titan abẹla ni wọn fi bẹrẹ ayẹyẹ naa ni Arigidi, eyi ti ọpọ ọmọ ilu naa ati awọn ololufẹ rẹ ti kopa. Kaluku wọn to mu abẹla ti wọn tàn dani lo daro rẹ, ti wọn si n fi awọn abẹla wọn silẹ ni ibi kan ti wọn ya sọtọ ni ile ti wọn ti bi oloogbe. Ọkan lara awọn eeyan to kopa nibi aṣalẹ abẹla titan ti wọn fi bẹrẹ isin idagbere fun oloogbe, Wolii Temitope Joshua ni ilu abinibi rẹ, Arabinrin Kemi Omoniyi, Arigidi-Akoko, ti sọ pe lootọ lo kú amọ isẹ iranṣẹ n tẹsiwaju. Nibi eto naa ti akọroyin BBC Yoruba ti kopa, ni obinrin naa ti sọ pe o ma n nira fun oun lati bimọ ti oun ba loyun wọn. O ni lọjọ ti iroyin iku TB Joshua jade, ibanujẹ lo jẹ fun oun nitori pe oun gbagbọ pe pẹlu iranlọwọ isẹ iransẹ rẹ, oun yoo bi oyun inu oun layọ. O sọ pe bẹẹni oun bẹrẹ si ni gbadura pe to ba jẹ lootọ ni Ọlọrun pe TB Joshua, ki oun bimọ wẹrẹ. Arabinrin Omoniyi sọ pe bẹẹ gẹlẹ lo ri fun oun ni ọjọ ti oun fẹ ẹ bimọ, debi pe oun ko ni irora kankan lasiko irọbi. Emmanuel to jẹ ara orukọ oloogbe TB Joshua ni oun ati ọkọ rẹ to jọ wa sibi eto naa sọ ọmọ wọn lati bu ọla fun un. Zaki ilu Arigidi-Akoko ni ipinlẹ Ondo, to jẹ ilu abinibi oloogbe Wolii Temitope Joshua, Ọba Yisa Olanipekun, ti sọ pe oriṣiriṣi eto lo wa nilẹ fun isinku wolii naa. Ọjọ Aje, ọjọ karun-un, oṣu Keje, ni ayẹyẹ isinku T.B Joshua to di oloogbe ni ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, bẹrẹ nile ijọsin rẹ, Synagogue Church of All Nations, nipinlẹ Eko. Ọba Olanipekun sọ pe gbogbo eto ati ayẹyẹ ti wọn ba ṣe ni Eko, naa ni yoo waye ni Arigidi O ni awọn naa yoo bẹrẹ ayẹyẹ idagbere ni ọjọ Aje, ọjọ karun-un, oṣu Keje, pẹlu alẹ abẹla titan, lasiko kan naa to ba n waye ni ile ijọsin Synagogue nipinlẹ Eko. Ṣaaju ni Ọba Olanipekun ti fi erongba ọkan ara ilu Arigidi han pe ilu Arigidi ni awọn fẹ ki wọn o sin oku T.B Joshua si.
https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-57725879
yor
religion
Tunde Bakare: Àwọn èèyàn kò gbọ́ ìwàáṣù mi délẹ̀, kí wọn tó bú mi lórí ọ̀rọ̀ Tinubu
Olusọagutan Tunde Bakare, ti i se asaaju ijọ Citadel Global, ti yọ suti ete sawọn eeyan to n foju laifi wo oriyin to gbe fun ipa ti Bola Tinubu ko si idagbasoke orilẹede yii. Bẹẹ ba gbagbe, fidio kan lo lu sori ayelujara laipẹ yii, ninu eyi ti Bakare ti yonbo asaaju ẹgbẹ APC naa ninu iwaasu to se lori pẹpẹ ijọ rẹ. Gbajugbaja oniwaasu naa si lo fi Tinubu we Jephtar ninu bibeli, pẹlu afikun pe gbajumọ oloselu naa ti ja ọpọ ogun fun ilọsiwaju ilẹ Yoruba. Bakan naa lo ni o ti gba ipinlẹ Eko atawọn ipinlẹ yoku nilẹ Yoruba silẹ lọwọ ifiyajẹni ẹgbẹ oselu PDP laarin ọdun 1999 si 2007. Iwaasu yii lo mu awuyewuye dani, ti ọpọ si n kọminu pe ki lo de ti Tunde Bakare ti ti laali Tinubu tẹlẹ, se wa yipada maa kọrin re ki i. Nigba to n fun awọn alariwisi rẹ lesi ọrọ wọn, Bakare wa se apejuwe awọn eeyan to n bu ẹnu atẹ lu naa gẹẹ bii 'Agbokujo'. O ni kii se pe oun gba owo lọwọ Tinubu, ki oun to kọrin rere kii, bẹẹ ni ko si ẹni to lowo lọwọ to bẹẹ lati sanwo isẹ fun oun. O tun kesi awọn eeyan to n yọ suti ete si pe o ti gba owo ẹyin, lati fi ẹri to daju lelẹ, ti wọn ba ni lọwọ. Ninu iwaasu miran to se lọjọ Aiku ana, eyi ti Bakare pe akori rẹ ni 'Ko si ẹni to mọ bii Ọlọrun', wa n beere pe ki lo de tawọn eeyan fi n tako oun lai gbọ ẹkunrẹrẹ iwaasu naa delẹ tan. Bakare ni ọwọ Ọlọrun ni idajọ wa, ko si yẹ ki awọn eeyan maa fi iwanwara se idajọ ọmọnikeji nitori iwa ti wọn ti hu sẹyin. O fikun pe lootọ ni oun yonbo Tinubu nipa awọn aseyọri to se nidi oselu amọ eyi ko tumọ pe oun fara mọ igbe aye rẹ Ojisẹ Ọlọrun naa ni nigba ti ọpọ eniyan n sun, Tinubu n sisẹ kara lati fi awọn eeyan rẹ sibi to lagbara. O ni yoo nira fun ẹnikẹni lati bori oludije ti Tinubu ba ti lẹyin nipinlẹ Eko nitori akoko ko tii to fun wọn. Wayi o, Bisọọbu ijọ aguda ti Sokoto Ẹniọwọ, Matthew Kukah ni aarẹ Muhammadu Buhari ti fi ọjọ iwaju Naijiria rubọ nitori ifẹ ati ipinu rẹ lati mu ki iha Arewa Naijiria maa jẹgaba lori ẹya to ku. Kukah sọ eyi ninu atẹjade iwe ikini rẹ fun ọdun keresimesi to pe akọle rẹ ni A Nation in Search of Vindication.' O ni Naijiria wa ninu okunkun birimu labẹ akoso aarẹ Buhari, ati pe o ṣe pataki ki aarẹ ṣalaye nkan to wa ni idi itajésilẹ ojoojumọ nitori eto abo to mẹhẹ. O ṣapejuwe orilede Naijiria bi eyi ti ara ilu rẹ n rinrin ajo ọkọ oju omi ṣugbọn ti ko si awakọ, iwe irina ati ebute ibi ti yoo ti sọkalẹ. Kukah ni " Aarẹ Buhari nilo lati ṣalaye fun ọmọ Naijiria ibi ti o ń dari ọkọ wọn lọ gan nitori pe o jọ pe inu okunkun birimu ni. "Itajẹ silẹ ojoojumọ ti pọju o si kọja afẹnusọ, ṣe bi awọn oniṣẹ ibi yii yoo ṣe di ara ilu lọwọ ati ẹsẹ ree abi o ti di nkan ti a o maa ba gbe titi lai?" "Aarẹ Buhari mọọmọ fi iran awọn ọmọ orilede yii to dibo fun rubọ ni, ó jọ bi ẹni pe, o ni ileri kan to gbọdọ muṣẹ fun awọn Arewa nitori naa o gbọdọ sọ ẹya toku di "boo ba o pa a" boo ba o bu u lẹsẹ. Imọ tara ẹni nikan ni aarẹ ni ṣe lai fi ti ara ilu ṣe." " Gbogbo ọmọ Naijiria ti ko ba ni parọ tan ara rẹ mọ pe ẹnikéni ti kii ṣe musulumi lati iha Arewa ko dan ida kan nkan ti aarẹ Muhammadu n dáwo lọọwọlọwọ bayii ti yoo si mujẹ bẹẹ. Awọn ọmọ ologun yoo ti ditẹ gba ijọba tipẹ tabi ki orilede yii ti béré ogun". O ni nitori iwa aibikita aarẹ ajalu lori arelu ni aburu to n de ba Naijiria, orilede yii ti wa ninu wahala ati isoro to n ranju mọ ara ilu kọọkan. Ọpọ ala ati iran ara ilu lo si ti sọnu pẹlu, wọ́n ti ji ọrọ gbogbo ilu gbe, ti iwa ajẹbanu si ti ni éka loriṣiriṣi, awọn mitan ti gba émi ara wọn pẹlu. Ẹwẹ, o rọ gbogbo ara ilu lati ma sọ ireti nu loju gbogbo isoro yii, inira, ibanuje ati ainireti to kun orilede Naijiria
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55451266
yor
religion
Winners Pastors Sack: Oyedepo tún ti fèsì sí áwọn tó bẹnu atẹ́ lu ìgbésẹ̀ to gbé lórí àwọn Pásítọ̀ rẹ̀
Bisọọbu ijọ Winner tun ri fesi lati da awọn to n sọrọ alufansa sii nitori pe o le awọn pasitọ ijọ rẹ lẹnu isẹ nitori pe wọn ko so eso. Bakan naa lo Soko ọrọ ranṣẹ si awọn to tako lori ile ijosin onijoko eniyan ẹgbẹrun lọna ọgọrun ti o pe ni "The Ark" Oyedepo ni awọn olusọaguntan ti oun le n saisan bakan naa wọn ko so eso rere, gẹgẹ bi gbedeke ti oun fun wọn lati jere o kere ju emi mejila lọsẹ. O ni: Awọn ijọ igberiko n lọ lọwọ ti awọn nkọ idamẹwaa ati ọrẹ ti wọn n da nibẹ ti wọn ba ko jọ ni ogoji ọdun ko le kọ iru ile ijọsin ti ijọ n kọ fun wọn. Mo gbọ pe awọn kan n sọ pe nitori awọn ni owo ọrẹ ni oun se ni ki wọn maa lọ". " Nitori pe ẹ saisan. Ẹ o so eso. A fayin tu. "A ran yin lọ si igberiko ki ẹ lọ gba ọkan eniyan mejila la lọsẹ ki ẹ si ri daju pe eniyan mẹfa ninu wọn wa si ile ijọsin, sugbọn lẹyin osu mẹfa ko si eniyan mewaa ni sọọsi. E o so eso, amoju gidi lo gbe wa de ibi ti a wa yii "Ti eniyan ba fi ọmọsẹ ti ko so eso kalẹ, o tumọ si pe eni naa kii se adari rere'. Ẹ ni ẹtọ lati kowe fipo silẹ, a ní ẹtọ lati da yin duro lẹ́nu iṣẹ. Bi o se ri ni ibi gbogbo niyẹn. "Wọn n kọ ile alaga ẹgbẹrun lọna ọgọrun. Ṣe wọn gba owo lọwọ yin ni? O yẹ ki wọn di owo naa kọ ile ìṣe, ṣe ẹyin ni ẹ o maa se eto isuna owo olowo ni. Ẹ gbe enu yin dakẹ ki ẹ si kọju mọ iṣẹ yin. Wọn fẹran lati maa gbọ lati ọdọ mi, mo si feran lati maa gbọ lati ọdọ mi, emi naa si feran lati maa dawọn lohun"
https://www.bbc.com/yoruba/media-58064108
yor
religion
Daddy Freeze ti sọ̀rọ̀ lórí ẹjọ́ àgbèrè tó ṣe pẹ̀lú ìyàwó Paul Odekina, Benedicta Elechi
Gbajugbaja Agbohunsafẹfẹ, Ifedayo Olarinde, ti ọpọ eyan mọ si Daddy Freez ti kede pe oun n lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun, lẹyin ti ile ẹjọ giga kan nipinlẹ rivers ni ko san owo itanran nitori pe o ṣe agbere pẹlu iyawo oniyawo, Benedicta Elechi. Ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Youtube ni alẹ ọjọ Satide ni Daddy Freeze ti sọrọ lori idajọ naa. O ni ile ẹjọ ko fi iwe kankan ranṣẹ si oun. Bakan naa lo sọ pe oun ko ni sọ ohunkohun nipa awọn ẹsun to jẹyọ ninu idajọ naa, nitori pe ọrọ ti wa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun. Ṣugbọn lori ikọsilẹ to waye laarin oun ati iyawo rẹ nigba kan, Opeyemi Morenike Oni, Freeze sọ pe kii ṣe agbere tabi aarun ọpọlọ lo tu igbeyawo naa ka, gẹgẹ bi nkan ti obinrin ọhun n sọ kiri. O ni iwa ipa ninu ile lo tu awọn ka. Ọjọ diẹ sẹyin ni iroyin jade pe ile ẹjọ giga kan to wa ni ili Port Harcourt nipinlẹ Rivers, dajọ ni ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2021, pe ki Ifedayo Olarinde san miliọnu marun-un Naira fun Paul Odekina, to jẹ ọkọ Benedicta Elechi to ṣe agbere pẹlu Freeze lasiko to ṣi wa nile ọkọ. Onidajọ Akpughunum sọ pe ki Daddy Freeze san miliọnu marun-un naa jẹ owo itanran fun Odekina, nitori pe ko jẹ ko gbadun iyawo rẹ. Bakan naa ni adajọ tu igbeyawo ka laarin Paul ati Benedicta nitori agbere ti Benedicta ṣe pẹlu Freeze. Iroyin sọ pe agbere naa bi ọmọkunrin kan laarin wọn. Yatọ si pe Daddy Freeze jẹ gbajugbaja agbohunsafẹfẹ ni Naijiria, o tun gbajumọ fun bo ṣe ma n sọrọ tako awọn pasitọ, paapaa lori ọrọ idamẹwa ati ọrẹ. O ti sọrọ abuku si awọn pasitọ bi David Oyedepo ti ijọ Winners Chapel, Pasitọ Enoch Adeboye ti ijọ Redeem ati awọn pasitọ nla mii. Koda, o da ẹgbẹ kan silẹ to pe ni 'Free the Sheeple Movement' lati ma a 'tu awọn eeyan silẹ kuro ninu ide awọn pasitọ'.
https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-56311237
yor
religion
Osinachi Nwachukwu: Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ olóògbé sọ pé lóòótọ́ ni ọkọ rẹ̀ n fi ìyà jẹ ẹ́, ohun tó mọ̀ rèé
O ti le ni ọsẹ kan ti gbajugbaja akọrin ẹ̀mí, Osinachi Nwachukwu, jáde laye. Sugbọn ọrọ ko tii tán lori iku rẹ. Lati igba to ti ku ni awọn eeyan kọọkan ti n sọ ni gbangba pe lílù ti ọkọ rẹ, Peter Nwachukwu, má n lu u lo ṣe okunfa iku rẹ. Lara àwọn eeyan naa ni àwọn ọmọ oloogbe, ẹbi rẹ, ati awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ orin bii Frank Edwards. Àwọn aláṣẹ ko tii fidi eyi mulẹ ṣa. A rí àwọn fọ́tò tó fihàn pé ọkọ Osinachi ní ìyàwó míràn sí ìkọ̀kọ̀ - Mínísítà fọ́rọ̀ obìnrin Nǹkan márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Peter, ọkọ Osinachi, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ikú aya rẹ̀ kàn Ọdún mẹ́jọ ni ọkọ ọmọ mi kò jẹ́ ki n fojú kan ọmọ mi lẹ́yìn ìgbéyàwó - Ìyá Osinachi Kọjú sí iṣẹ́ ìwàásù táa fí rán ọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wà darapọ̀ mọ́ òṣèlú - Ilééṣé ààrẹ sí Father Kukah Ẹni tuntun to tun sọrọ nipa iku Osinachi, ni ọrẹ rẹ timọtimọ, Odinakachi Ukanwa. Ukanwa sọ fun BBC Igbo pe o ni asiko kan ti Osinachi rinrinajo lọ si ilu Eko, o ni ni ṣe ni Peter sọ fun iyawo rẹ pe ko lọ sun sile aṣẹwo, dipo ile òun ọrẹ rẹ. O ni oun ti mura silẹ lati gbalejo rẹ, ki ọkọ rẹ to pàṣẹ fun un pe ko ma sun sile oun. " Bo ṣe de papakọ ọkọ ofurufu, lo pe mi pe ọkọ oun ni ile ìtura ni ki oun sun. Koda, ibẹ lo wa to ti n reti ki ọkọ fi owo ti yoo fi gba yaara ránṣẹ́ si i". "Nigba to de ile itura naa, ni awakọ takisi to gbé e lọ síbẹ̀ salaye fun pe ile aṣẹwo ni ibẹ, kii ṣe ile ìtura." Arabinrin Odinaka Ukanwa ṣalaye pe lẹyin iṣẹlẹ naa ni Osinachi sọ fun oun nipa nkan to n la kọja ninu igbeyawo rẹ. Ati bo ṣe jẹ́ pe ọkọ rẹ lo n mojuto gbogbo owo to ba pa nibi orin kíkọ. Odinaka sọ pe ọrẹ òun jẹ ẹnikan ti ko fọwọ si tabi gbagbọ ninu ikọsilẹ tọkọtaya. Idi ni pe o gbagbọ pupọ ninu Bibeli. O ni sugbọn, kii fẹ sọ̀rọ̀ nipa nkan to n la kọjá, ki ọrọ naa ma baa di wahala laarin oun ati ọkọ rẹ. Lọwọlọwọ, ọkọ Osinachi, Peter, wa ni ahamọ ọlọpaa n'ilu Abuja. Eyi waye lẹyin ti aburo oloogbe fi ẹjọ sùn ni agọ ọlọpaa, pe Peter lo lu iyawo rẹ pa. Nítorí orin 'Angeli mi' ti Tope Alabi kọ, iléeṣẹ́ MTN, Glo àti Airtel dèrò ilé ẹjọ́ Kókó pàtàkì márùn ùn rèé tí Bíṣọ́bù Kukah fi sọ ọ̀rọ̀ gbá ààrẹ Buhari nínú ìwàásù ọdún àjínde Wo èsì ilé ìtura Zanzibar tí ọmọbìnrin yìí ní wọ́n fẹ́ fipá bá òun lòpọ̀ níbẹ̀ Ìyà tó jẹ́ mi lẹ̀yìn tí mo kúrò nílé ọkọ lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà kọjá sísọ - Iyabo Ojo Ìdí nìyí tí àwọn Igbo kò lè jẹ Ààrẹ lórílẹ̀èdè Nàíjíríà - Oluwo Minisita fun ọrọ awọn obinrin ni Naijiria tilẹ sọ pe àṣírí tú nigba ti oun bẹ awọn ọmọ oloogbe wo pe Arakunrin Peter ni iyawo miran ni ikọkọ. Mama Osinachi, Arabinrin Madu, sọ fun BBC pe lẹyin ọdun mẹjọ ni oun to fi oju kan ọmọ oun nigba to ṣe igbeyawo pẹlu Peter. Bakan naa ni ẹbi naa sọ pe Ọgbẹni Nwachukwu ko gba ki Osinachi wa ẹbi rẹ tabi ki awọn naa o wa. Koda, wọn sọ pe awọn ti gbe e kuro nile arakunrin naa ri, nigba to n fi iya jẹ ẹ. Ṣugbọn, oloogbe pada sile ọkọ rẹ "nitori pe ko fẹ ki ẹnikẹni tu nkan ti Ọlọrun ti so pọ". Pásítọ̀ Paul Enenche to jẹ oludasilẹa ti adari ijọ ti wọn n lọ naa sọ nnkan tó mọ̀ nípa ikú akọrin Ekwueme, Osinachi Nwachukwu. Lẹyin ọsẹ kan ti gbajugbaja akọrin ẹmi, Osinachi Nwachukwu, jade laye, pasitọ Paul Enenche, ti sọrọ lori iku rẹ. Pasitọ naa sọ pe oun ko mọ tabi gbọ pe ọkọ obinrin naa ma n lù ú, titi awọn eeyan fi n sọrọ nipa rẹ lẹyin iku rẹ. Wo àwọn ibi mẹ́rin tí ènìyàn kò le fi ẹsẹ̀ tẹ̀ láyé Ọlópàá 16 farapa nínú ikọlù tó wáyé torí àwọn kàn gbèrò láti dáná sún Quran
https://www.bbc.com/yoruba/61146634
yor
religion
Boxing Day: Kí ni ìdí tí wọ́n fi ń pe ọjọ́ kejì ọdún Kérésì ní Boxing Day?
Itan 'Boxing Day' yii bẹrẹ lakoko ti Ọbabirin Victoria wa lori aleefa niwọn ọdun 1800. Boxing Day ko ni nnkankan ṣe pẹlu ẹṣẹ kíkàn gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe lero. Orisun orukọ naa bẹrẹ pẹlu bi awọn ọlọla ṣe maa n di ẹbun sinu apoti, ti wọn si maa n pin fun awọn alaini lọpọlọpọ ọdun sẹyin. Ọjọ ọhun jẹ ọjọ ti awọn ẹrú kii ṣe iṣẹ kankan, ti awọn olowo wọn si maa n fun wọn ni ẹbun ọdun Keresi ninu apoti. Awọn ẹbun ọhun ni awọn ẹru naa maa n gbe lọ fun awọn ara ile wọn, ki wọn fi ṣafihan bi awọn olowo awọn ṣe mọ riri iṣẹ ti wọn ṣe ni odidi ọdun kan to. 'Boxing Day' tun jẹ ọjọ ti awọn orilẹ-ede kan bii Hungary, Germany, Poland ati Netherlands maa n ṣe ajọyọ ọjọ to tẹle ọjọ ọdun Keresimesi. Ninu iwe itan, awọn ile ijọsin naa kopa ninu ṣiṣagbekale ọjọ 'Boxing Day'to wa fun pinpin ẹbun fi mọ riri ara ẹni. Lẹyin ti wọn ba ti gba owo ọrẹ lọwọ awọn ijọ laarin ọdun, wọn maa n ko owo naa sinu apoti, wọn a wa ṣi apoti owo ọrẹ yii lọjọ keji ọdun Keresi, ti wọn a si pin owo inu rẹ fun awọn talaka. Ọjọ wo ni ọjọ' Boxing Day'? Boxing Day jẹ ọjọ keji, ọdun Keresimesi, o si maa n bọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn, ninu oṣu Kejila ọdun. Ọjọ ọhun tun jẹ ọjọ isinmi lorilẹ-ede Naijiria ati ni awọn orilẹ-ede miran lagbaye. Lorilẹ-ede wa nibi, ọjọ yii jẹ ọjọ faaji ati ọjọ igablejo loriṣiriṣi fun ọpọ eeyan. Ọjọ ọhun tun jẹ ọjọ ti awọn eeyan ma jẹ ajẹyo ati ajẹṣẹku ounjẹ ti wọn se lasiko ọdun.
https://www.bbc.com/yoruba/media-50918074
yor
religion
Wòlíì bá ọmọ ìyá méjì sùn nínú ìjọ rẹ̀, ọ̀kan níńú wọn ti lóyún
Wolii ijọ Kerubu ati Serafu kan, Joseph Ogundeji ti wọ gbaga ọlọpaa nipinlẹ Ogun fun biba awọn ọmọ iya meji kan lo pọ. Awọn ọlọpaa sọ pe, ọkan lara awọn ọmọbinrin naa loyun nipasẹ aṣemaṣe naa. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ṣalaye ninu atẹjade kan pe ọmọ ijọ Wolii Ogundeji ni awọn ọmọ iya mejeeji naa jẹ ati pe awọn ọlọpaa lọ fi panpẹ ofin mu wolii naa lẹyin ti wọn fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa to wa lagbegbe Ajuwọn. O ni wolii naa jẹwọ nigba ti wọn fi ọrọ waa lẹnu wo pe lootọ loun ṣe aṣemaṣe naa. Iwadii ọlọpaa fihan pe ọkan lara awọn ọmọbinrin naa jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti ikeji si jẹ ọmọ ọdun mẹtala “Awọn ọmọbinrin mejeeji yii fi to ọlọpaa leti pe pe nigbakugba ti wọn ba ti ni iṣọ oru ni ile ijọsin, wolii naa ti ile rẹ ko jina si ile ijọsin naa yoo ni ki awọn lọ sun si ile oun nigbakugba ti iṣọ oru naa baa pari ni nnkan bi agogo mẹta.” Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun sọ pe awọn ọmọbinrin naa tun sọ pe nigba kugba ti awọn ba ti wa ni ile wolii na yoo fun awọn ni nnkankan lati la, eleyi ti yoo mu wọn sun lọ ti awọn yoo si taji nigba to ba ya lati rii pe wolii ti ba awọn ni ibalopọ. “Nigba ti a bi wọn pe ki lo de ti wọn ko fi ọrọ naa to awọn obi wọn leti, wọn ni wolii naa leri lati pa awọn bi awọn ba sọ ọrọ naa fun ẹda alaye kankan.”
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c1dgl50n455o
yor
religion
National Prayer: Àjọ́ CAN pàṣẹ ètò àdúrà ọlọ́jọ́ mẹ́tà fún Naijiria , ẹ wo kókó àdúrá...
Ajọ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijria, CAN ti pe fun adura ọlọjọ mẹta lati gbadura fun Naijiria. Ajọ CAN ninu atẹjade ti wọn fi lede ni Ọjọ Ẹti, Ọjọ Kejidinlọgbọn si Ọgbọnjọ, Oṣu Karun un lati gbe ohun adura soke kaakiri ẹkun Naijiria ti awọn ọmọlẹyin Kristi. CAN ni asiko ti to lati bẹbẹ fun aanu lorilẹ-ede Naijiria nitori itajẹsilẹ naa ti to ge. Bkan naa ni wọn kigbe si Ọlọrun lati dẹkun ipaniyan, ijinigbe pẹlu wahala ati idaanu to n koju awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria. Akọwe Ajọ CAN, Daramola Bade Joseph ni ibanujẹ ọkan ni itajẹ silẹ ojoojumọ n jẹ fun awọn ọmọlẹyin Krisiti ni Naijiria, ati wi pe ẹṣẹ ti pọju ni orilẹ agbaye. ''Ẹjẹ ki a gbadura wi pe ki Ọlọrun dari gbogbo aiṣedede wa jinwa gẹgẹ bi ijọ ọlọrun ati orilẹede, paapaa awọn adari ni Naijiria''. '' Ẹ gbadura wi pe imọ ọta ati awọn ẹni ibi lati ba aye awọn eniyan jẹ ati eto ọrọ aje kaakiri, ki o di ofo'' Ajọ CAN fikun pe ki ijọ dide ninu adura pe ki ogun maṣe bẹ silẹ ni Naijiria, ki awọn eniyan le raye sin Ọlọrun. Laipẹ yii ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari naa kesi awọn ẹlẹsin Musulumi lati gbe ohun ẹbẹ si Allah lasiko ọdun itunu aawẹ, ki gbogbo ogun to n ja orilẹede Naijiria lọ si okun igbagbe. Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi iṣẹ ikini ku ọdun itunu awẹ ranṣẹ si awọn ọmọ Naijiria ati Musulumi kaakiri agbaye. Ninu atẹjade ikini ti agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu fi sita, Buhari sọ fun awọn ọmọ Naijiria, lati gbadura tako ijinigbe ati iṣẹ awọn agbebọn ni Naijiria. Buhari sọ pe " a gbọdọ gbadura tako awọn iṣẹlẹ ibanujẹ bi ijinigbe ati ikọlu lati ọwọ awọn agbebọn, to fi mọ bi awọn kan ṣe n wa gbogbo ọna lati já agbara gba, eyi ti wọn fi n dunkooko mọ orilẹede wa". Aarẹ sọ pe oun rọ awọn olori ilu ati olori ẹsin, lati ba awọn "eniyan wa sọrọ pe ki wọn o ma a fi ifẹ ati oju aanu ba ara wọn lo". Alaye ti aarẹ ṣe ni pe inu didun ati iwuri ni bi awọn ẹlẹsin Kristiẹni kan ṣe n ṣe ọdun itunu awẹ pẹlu awọn Musulumi, tabi fun wọn ni ẹbun lasiko Ramadan. Eyi ti awọn Musulumi kan naa ma n ṣe lasiko ọdun awọn Kristiẹni. O ni iru awọn iwa bẹẹ n ṣe atọna fun jijẹ ibatan ati idariji. Ṣaaju ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti funpe si gbogbo awọn mumini ati mumina lati ṣe ayẹyẹ ọdun Eid-el-Fitr ninu ile ara wọn lati yago fun itankalẹ arun Corona Virus. Aarẹ sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu fi sita lọjọ Aiku ninu eyi to ti sọ wipe oun naa yoo ṣe adura ọdun Eid ninu ile ti ko si ni si a nkini kankan lẹyin rẹ. ."Gbogbo mọlẹbi aarẹ, awọn oluranlọwọ rẹ, minisita atawọn olori oṣiṣẹ alaabo aarẹ to wa ni ilu Abuja yoo ṣe adura ọdun ni ile aarẹ ni ilana ati ofin fun igbogun ti arun Covid-19". Atẹjade naa tun sọ pe "lẹyin eyi, ko ni si ikini ti Salat. Ati pe adura yoo bẹrẹ ni ago mẹsan". Gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe e lọdun to kọja lọ, bẹẹ gẹlẹ naa ni aarẹ rọ awọn adari lati ṣe ayẹyẹ yii ninu ile wọn nitori ajakalẹ arun. Lọjọ Aiku, aarẹ Buhari ba wọn pe nibi ikadi eto kika Quaran eyi ti wọn ṣe ni ile rẹ ti Sheikh Abdulwahi Abubakar Sulaiman ti n dari lati ibẹrẹ awẹ Ramadan.
https://www.bbc.com/yoruba/57062039
yor
religion
SCOAN leadership tussle: Ìyàwó Wòlíì TB Joshua di olórí ìjọ Synagogue
Ijọ Synagogue, SCOAN ti yan iyawo oloogbe Wolii TB Joshua, Evelyn Joshua gẹgẹ bii adari tuntun ijọ naa bayii. Ijọ naa ṣalaye ninu atẹjade kan loju opo Facebook rẹ pe gbogbo eto ijọ naa yoo wa labẹ itọni Ọlọrun ati idari arabinrin Evelyn Joshua bayii. Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, akoko ti a yan lo to, wọn si rọ gbogbo awọn ọmọ ijọ naa lati maa fi adura tii lẹyin fun ogo Ọlọrun lati maa tii lẹyin. Ṣaaju asiko yii ni oniruru iroyin ti n kaakiri nipa edeaiyede lori tani yoo ṣe olori ijọ naa lẹyin ti oludasilẹ ijọ ọhun, TB Joshua jade laye loṣu karun ọdun 2021. Edeaiyede naa lo faa ti wọn fi le awọn ọmọlẹyin Wolii TB Joshua kan kuro ni gbagede ijọ naa laipẹ yii. Ileesẹ iransẹ TB Joshua kede pe oludasilẹ ijọ naa ati agba wolii lorilẹede Naijiria, Temitope Balogun Joshua ti dagbere faye loju opo Facebook rẹ, lọjọ Satide, ọjọ karun osu Kẹfa ọdun 2021. Wolii Joshua, to dele aye ni ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1963, lo lo ọdun mejidinlọgọta loke eepẹ, ki ọlọjọ to de. Ikede naa fidi rẹ mulẹ pe Ọlọrun kii se ohunkohun lai fi iran rẹ han awọn wolii rẹ saaju, to si tọkasi iwe mimọ Amosi, ori kẹta ẹsẹ keje. Gẹgẹ bi ikede ijọ naa ti wi, Wolii Joshua sọrọ lọjọ Satide lasiko ipade to se pẹlu awọn alabasisẹpọ rẹ fun ileesẹ mohunmaworan ijọ rẹ, Emmanuel TV, to si dabi ẹnipe o n sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58539526
yor
religion
Mummy G.O: Ẹ bi àwọn tó ti mulẹ nínú ayé gidi, wọ́n mọ̀ wípé òótọ́ ni mò ń sọ - Evangelist Funmilayo Adebayo
Ko sẹni to fi bẹẹ mọ Ajihinrere Funmilayo tẹlẹ ni ijọ rẹ to duro si jẹjẹ to ti n waasu amọ kete ti awn kan gbọ pe o n waasu pe awọn kan yoo lọ ọrun apaadi tori iwa wọn, awọn eeyan han an to si ti tara eyi di gbajugbaja lori ayelujara. "Wọ́n ń ru ìbínú àwọn èèyàn sí mi ni wọn ṣe n tun gbogbo iwaasu mi "edit" ti wọn n fi ọrọ tiwọn kun un". Evangelist Funmilayo Adebayo gangan ni orukọ arabinrin oniwaasu ti gbogbo aye n pe ni Mummy G.O lori ayelujara ti gbogbo eeyan si n fẹ lati wo awọn fidio iwaasu rẹ. Koda o ti kọja wiwo fidio iwaasu rẹ nikan, awọn eeyan ti n lo aworan rẹ ati ọrọ rẹ lati fi ba ara wọn ṣe yẹyẹ lori ayelujara pe boo ba ṣe bayi bayi, ọrun apaadi lo n lọ. Eyi wa lara ọrọ to saba maa n jade lẹnu Ajihinrere Funmilayo tori o maa n waasu pe awọn iwa mii ati igbe aye ti awọn eeyan n gbe gaan ni yoo ran wọn lọ si ọrun apaadi eyi tii ṣe inu ina ajooku titi ayeraye eyi ti awọn ọmọlẹyin Kristi gbagbọ pe o jẹ ibi ijiya ayeraye fun awọn ti ko ba gba Jesu Kristi gbọ nigba ti wọn wa ninu aye. Lara awọn ọrọ to ti jẹyọ ninu iwaasu Ajihinrere yii ti awọn eeyan gbọ ti wọn fi n pariwo niwọnyii: Àsọtẹ́lẹ̀ 2022 àti ìgbésẹ̀ tí Pásítọ̀ Enoch Adeboye fẹ́ gbé lórí ìdojúkọ Nàìjíríà nìyí 'Ẹ ṣọ́ ẹnu yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọdún 2022, àwọn ọlọ́pàá kìlọ̀ fáwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run bí bẹ́ẹ̀ kọ́...' 'Kí òpin dé sí ìmọtaraẹni nìkan àti gbogbo ìwà àjẹbánu lórílẹ̀èdè Nàíjíríà'' Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó já s'ófo lórí ìdìbò 2019 'Àwọn olóṣèlú Nàìjíríà náà máa n ṣàbèwò sí àwọn wòólì, wọn kò lè fòfin de àsọtẹ́lẹ̀ ọdún tuntun' -Iwọ too ba n fi irun onirun kun irun rẹ ti wọn n pe ni "attachment" ọrun apaadi lo n lọ. -Iwọ too ba n ṣe iṣẹ apanilẹrin, ko si ijọba ọrun rere fun ọ tori oo le ṣe koo ma pa irọ. -Iwọ too ba fẹran ere bọọlu tabi too tilẹ n gba bọọlu, inu ina janto. -Iwọ to ba n kun eekana lọda, ọrun apaadi lo n lọ Mummy G.O to jẹ oludasilẹ ati adari ijọ Rapture Proclaimer Evangelical Church of God tọka si ibi ti awọn ọrọ to n sọ yii wa ninu bibeli to si ni o n pariwo rẹ faraye tori bibeli lo sọ bẹẹ lai wo ti pe wọn korira oun. Ajinhinrere yii ni oun ko bikita bi awọn eeyan ba korira oun fun otitọ tori nigba ti oun wa ninu ẹgbẹ okunkun, gbogbo wọn lo fi ifẹ han si oun. Ninu ẹgbẹ okunkun to wa tẹlẹ yii lo ti tọka si pe awọn lawọn pese gbogbo awọn irun afikun irun ati ọpọlọpọ ọṣọ ara ati ipara to si ni ki awọn eeyan jawọ lilo wọn tori oun toun da wọn gan ti faye oun fun Jesu. Irọ́ ni pé àwòrán CCTV ṣàfihàn bí Ramon Adedoyin ṣe pa Timothy Adegoke - Agbẹjọ́rò Adedoyin Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi àwòrán Raheem Adedoyin léde láwọn ìwé ìròyìn lórí ikú Timothy Adegoke
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-59926363
yor
religion
Christmas: Ìdí tí Bàbá Kérésì fi máà n wọ aṣọ pupa àti funfun nígbà gbogbo
Ọpọlọpọ gbagbọ pe Baba Keresi maa n wọṣọ ni ibamu pẹlu aàwọ̀ pupa ati funfun to wa lara agolo nkan mimu ẹlẹrindodo Coke. Won ro eyi nitori pe ipolowo ọja Coca Cola ni nkan bii ọdun 1030 lo sọ Baba Keresi di gbaju-gbaja. O dara bẹẹ, ṣugbọn wọn ko da Baba Keresi alaṣọ pupa ati funfun kalẹ lati polowo Coca Cola, ṣugbọn nitori pe o n du ọja pẹlu White Rock l'ọdun 1923 ni. Ọkan lara wọn ni Saint Nicholas. Biṣọọpu Greek ni aye atijọ, to maa n wọ aṣọ pupa ni gbogbo igba to ba ti fẹ ẹ fun awọn alaini ni ẹbun. paapa awọn ọmọde. Ìtàn miran lati ọwọ oṣere Netherlands, Sinterklas, to tun dale Saint Nicholas, to gbajumọ laarin awọn olowo ni New York, bi i Washington Irving ati Clement Clark Moore ni nkan bi ọdun 1800. Awọn mejeeji gbiyanju lati sọ Aisun alẹ Keresimesi di nkan ti gbogbo eniyan yoo wa lori ibusun wọn lati sun, dipo ayẹyẹ ati ariya ita gbangba. Ọgbẹni Moore jẹ ọ̀kan lara awọn to da Baba Keresimesi ti Amẹrika silẹ - ẹni mimọ to maa n wọ aṣọ pupa, ti yoo si maa fun gbogbo eniyan ni ẹbun, boya wọn fẹ tabi wọn ko fẹ ẹ. A le tọ ipasẹ Baba Keresi lọ si ọdọ Biṣọọpu Greek, Nicholas. Ninu ẹ̀sìn Kristiẹni, ọpọ maa n pọn ọn le gẹgẹ bi alaabo awọn ti ko ni iya ati baba, awakọ oju omi ati awọn ẹlẹwọn. Olukọtan kan ni Fasiti Manitoba, Gerry Bowler, ṣalaye pe nitori pe Ẹni Ọwọ Nicholas maa n pin ẹbun fun awọn eniyan, ni wọn ba bẹrẹ sii ri gẹgẹ bi baba-isalẹ awọn ọmọde ati onidan to maa n fun nii ni nkan. Ṣugbọn, ipolowo ọja lo mu ki Baba Keresimesi ode-oni o gbajumọ. Ni nkan bi ọdun 1820, ipolowo fun ẹbun ọdun Keresimesi bẹrẹ si ni tan kiri orilẹ-ede Amẹrika, nigba ti yoo si fi di ọdun 1940, Baba Keresi naa ti bẹrẹ si ni farahan daada ninu ipolowo ọja. Bi ififunni lasiko Keresi ṣe bẹrẹ niyi.
https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-50910234
yor
religion
Oyo Chieftancy Coronation: Ìpapòda Aláàfin kò ní dá ètò ìfinijoyè Femi Gbajabiamila dúró- Ọyọmesi
Ti baba ba ku, baba nii ku, adiyẹ kii si ku kaa dọmọ rẹ nu. Ni kete ti Alaafin ilu ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi tẹri gbaṣọ ni ọpọlọpọ ti sọ pẹ oye Aarẹ Baasofin ti ilẹ Yoruba ti Alaafin fẹ fi da Abẹnugan ile igbimọ aṣojuṣofin orilẹ ede Naijiria, Femi Gbajabiamila lọla ni o ṣe ṣeeṣe ki o ma waye mọ. Ṣugbọn ọrọ yipada ni ọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ, oṣu karun-un, ọdun 2022 nigba ti Oyomesi ni ipapoda Alaafin ko ni da jijẹ oye naa duro. Basorun ilu Oyo, Oloye Olayinka Ayoola lo sọ ọrọ naa nigba ti Gbajabiamila ṣe abẹwo si Aafin ilu Oyo lati ba idile Alowolodu, Oyomesi ati gbogbo ilu Oyo kẹdun Alaafin Adeyemi to lọ darapọ mọ awọn babanla rẹ Oloye Ayoola ni ifinijoye naa jẹ nnkan ti Ọba Adeyemi fẹ ko ṣeeṣe ki wọn to waja ṣugbọn àwọn alalẹ ko kọ. Ninu ọrọ mọlẹbi Alowolodu, Ọmọọba Akeem Adeyemi sọ pe tori Gbajabiamila jẹ ọkan lara awọn Yoruba to gbe Aṣa ati iṣe ẹya naa larugẹ ni Ọba Lamidi fi ni pe oye naa tọ sii. O ni "Alaafin ni gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, Gbajabiamila koju oṣuwọn lati di Aarẹ Baasofin ilẹ Yoruba, o si di dandan lati di ṣiṣe." Ayẹyẹ ifinijoye naa lo yẹ ko waye lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu karun-un, ọdun 2022 lati fi ṣami ayẹyẹ ọjọ ibi abẹnugan naa.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61384829
yor
religion
Ọdún 1981 ni mo ti ń ṣe ayálégbé kí ṣọ́ọ̀ṣì tó kọ́lé fún mi – Aludùrù ìjọ
Ajani Godwin Babalola ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin, to jẹ aluduru ninu ijọ African Church ti ṣalaye fun BBC Yoruba bi igbe aye rẹ ṣe yi pada lẹyin ọpọ ọdun to ti n ṣiṣẹ fun ọlọrun. Baba agba naa ti ijọ ọhun kọ ile fun ni ile tuntun naa jẹ iyalẹnu nla fun oun. O ni awọn elere aye kan loun n tẹ gita fun tẹlẹ ki oun to pẹyinda bẹrẹ si n lo ẹbun oun fun Oluwa. Ninu iriri rẹ, o ni igba ti oun bẹrẹ si n lo gbogbo akoko oun fun duru titẹ ninu ile Oluwa loun padanu owo ti oun n ṣe tẹlẹ, to fi mọ iyawo oun atawọn ọrẹ kan, amọ ni igbẹyingbẹyin, ayọ lo pada ja si fun oun. Nigba to n sọrọ, alufaa ijọba ti babalola ti n ṣiṣẹ sin Ọlọrun, Pasitọ Adebayo Olujimi sọ pe Ọlọrun lo fi si oun lọkan ki wọn da ọkunrin naa lọla. Olujimi sọ pe asiko ti baba naa n ṣe ọjọ ibi lawọn gbero lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ naa fun ki inu rẹ le dun amọ Ọlọrun ni eto rere miran fun baba oniduru ọhun ju ero ti awọn ni lọkan. Ọkan lara awọn to kọ gbero bi wọn ṣe kọ ile naa, Olusesan Akinpelu ni asiko ti wọn n gbero lati ṣe akara oyinbo nla kan fun baba ni ẹnikan ninu igbimọ ti wọn gbe kalẹ fun eto naa sọ pe o san ki wọn kọ ile fun baba ju ki wọn ṣe akara oyinbo fun lọ. Gẹgẹ bii ohun ti Olujimi sọ, ile oniyara kan ni awọn kọkọ fẹ kọ tẹlẹ, amọ wọn yi ero awọn pada, ti wọn si kọ ile oniyara meji fun baba, eyii ti wọn pe orukọ rẹ ni “Bethel House.” Lori bi inu rẹ ṣe dun to lori ile naa, Babalola sọ pe ayọ oun ko lohunka. O ni ile ọhun da bi igba ti eeyan ba kuro ninu ile eku si aafin ọba lo ri loju oun. Baba Babalola wa gba awọn eeyan to n ṣiṣẹ sin Ọlọrun lamọran pe ki wọn ni suuru nidi iṣẹ naa, ki wọn si maa fi ọkan kan ṣiṣẹ ọhun.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cyd43qzmd80o
yor
religion
Day before Valentine: Àyànmọ́ ẹlòmíì yóò bàjẹ́ lóríi bẹ́ẹ̀dì ní ọ̀la- Mike Bamiloye
Ilumọọka ajihinrere to tun jẹ oṣere fiimu Kristni, Mike Bamiloye ti sọ oko ọrọ sita lori ọrọ ayajọ ololufẹ ti ọpọ mọ si Valentine. O sọrọ naa ni ayajọ ololufẹ ku ọla lọdun to lọ ni bi awọn mii ṣe n gbaradi fun ayajọ ọjọ ololufe ti o maa n waye ni ọjọ kẹrinla, oṣu keji ọdun. Oṣere naa kọ imọran ati akiyesi rẹ bi ẹni n kọ itan ere ori itage ni pe: "Irọle ọla jẹ ọjọ faaji, nigba ti awọn ọkunrin ati awọn ọdọbinrin yoo ba ayanmọ ọpọlọpọ jẹ lori ibusun ifẹkufẹ ara". Bamiloye ni nigba ti ilẹ ọjọ keji yoo fi mọ, nkan ti dahun. "Ayanmọ yoo di tita fun ọdọkunrin tabi ọdọbinrin to ti ta ọjọ iwaju rẹ fun eṣu". Bawo ni ọrọ ayajọ ololufẹ ṣe kan Josẹfu? Mike Bamiloye, Gbajugbaja oṣere yii fi apẹrẹ ọrọ naa we Josẹfu ninu Bibeli to ni ayanmọ rẹ ko ba ti di gige kuru to ba jẹ pe o ba iyawo Potiphar to jẹ ọga rẹ lajọṣepọ. O fi sita lori ayelujara pé "ẹ ku ayajọ ọjọ ololufẹ...! Bi o ba ṣe pe Josẹfu ba iyawo Portiphar ni ajọṣepọ, ko ba ma de aafin to ti di ọba to si ri iru opgo to ri". Bamiloye ni Josẹfu moribọ lọwọ panpe ti ko ba mu u da ayanmọ rẹ legbodo eyi ti aye ọpọlọpọ eeyan ni ilu naa ati iran rẹ dara le lori". Ọgbẹni Mike Bamiloye ni itan ọmọkunrin kan ni Bibeli toun naa ṣe "Valentine" ninu iwe Oniwaasu ori ikeje, ẹsẹ ikẹfa si ikẹtadinlọgbọn jẹ itan ibanujẹ. Bamiloye ni: "O ti ro pe oun fẹ gbadun alẹ ọjọ naa, o ti ro pe oun yoo jaye ori ara oun amọ o doju ọjọ iwaju ara rẹ bolẹ po lalẹ ọjọ igbadun kanṣoṣo. "Oniwaasu 7:21-23 21 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn. 22 Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà, bí i màlúù tí ń lọ sí ibùpa, tàbí bí (aṣiwèrè) àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́. 23 Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.
https://www.bbc.com/yoruba/56051810
yor
religion
Siyanbola Omolade Asabi: Hijab kò dí mi lọ́wọ́ iṣẹ́ mọkáníìkì tí mo n ṣe; ó kàn máa ń rán mi létí àwọn ǹkan ni
'Iṣẹ́ ni iṣẹ́ n jẹ́; kò sí nkan ti ọkunrin n ṣe ti obinrin kò le ṣe' Siyanbola Omolade Asabi jẹ akẹkọo jade lati Fasiti Olabisi Onabanjo to wa ni Agọ iwoye nipinle Ogun ni iwo oorun guusu Naijiria. Leyin to ṣetan lo ṣeṣẹ lọ kọ iṣẹ atun ọkọ ajagbe nlanla ṣe ni ipinlẹ Eko. Siyanbola jẹ ọmọ bibi ilu Oyo. O ṣalaye bi irinajo aye rẹ se gbe e lọ si ibi ti ori daa si abyii. Omolade Asabi gab awọn obinrin ẹgbe rẹ niyanju lati ma bẹru mọ. O ni pe iṣẹ ni iṣẹ n jẹ ti eeyan ko ba ti huwa ibi lawujọ.
https://www.bbc.com/yoruba/64149758
yor
religion
Ẹ wo bí wọ́n ṣe bẹ́ orí ènìyàn nitori ó sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Anabi Muhammed (SAW)
Ija ẹsin ti bẹ silẹ ni ipinlẹ Rajasthan ni India lẹyin ti wọn bẹ ori arakunrin ẹya Hindu nitori o satilẹyin fun isọrọ odi si Prophet Muhammed. Ẹni ti wọn pa naa to jẹ aranṣọ telọ ni orukọ rẹ n jẹ Kanhaiya Lai, ti awọn ẹlẹsin musulumi meji pa, ti wọn si tun gbe si ori ẹrọ ayelujara. Wọn ni pipa ti awọn paa ni pe o ṣe atilẹyin fun ọrọ ti oloṣelu kan sọ tako Prophet Muhammmed. Niṣe ni wọn wọ ṣọọbu arakunrin naa, ti wọn si ṣebi ẹni pe awọn fẹ ranṣọ ki wọn to ṣekupa a. Nibayii ijọba ti wọgile lilo oju opo ayelujara ati ipejọpọ eniyan ni ọgọọrọ. Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ mu awọn meji ti wọn darukọ ara wọn ninu fidio ọhun. Ijọba ilẹ India si rọ awọn akoroyin lati maṣe ṣe apinka fidio naa. Awọn alaṣẹ ni agbegbe Uttar Pradesh ti wo awọn ile palẹ to jẹ ti awọn Musulumi lorilẹede India. Awọn ti wọn wo ile wọn palẹ naa lo niiṣe pẹlu ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ to gbale kan lorilẹede naa, lẹyin ti awọn kan sọrọ odi si Prophet Muhammed. Ifẹhọnuhan ti wọn n ṣe kaakiri naa lo da rogbodiyan silẹ kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹede ọhun. Ọrọ ti awọn meji ninu awọn oṣiṣẹ agba ninu ẹgbẹ oṣelu BJP sọ nipa Prophet Muhammad lo mu ki awọn araalu to jẹ Musulumi binu ti wọn si bẹrẹ sini ṣe ifẹhọnuhan. Agbẹnusọ fun ẹgbẹ osẹelu BJP, Nupur Sharma ati agba osẹlu miran Naveen Jindal ni wọn sọrọ kubakugbe nipa Muhammad naa. Amọ ifẹhọnuhan naa da ija igboro, ti awọn kan siba ọja ati ohun ini awọn eniyan jẹ. O kere tan ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu ọọdunrun eniyan. Awọn alaṣẹ naa wo awọn ile ẹlẹsin Musulumi mẹta palẹ ni opin ọsẹ lẹyin ti wọn sọ wi pe ọna ẹburu ni wọn gba kọ ile naa. Amọ awọn onile naa ni kọ si otitọ ninu ẹsun naa. Wiwo ile wọn naa mu ki ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede naa fi ẹsun kan ijọba apapọ ti Olotu ijọba Yogi Adityanath ṣe adari fun pe, wọn n ṣe ikọlu si awọn Musulumi ti ẹsin wọn kere lorileede naa, ti kii ṣe ẹsin Hindu to jẹ gboogi nibẹ. Lati ọdun 2014 ni ija ẹlẹsinmẹsin ti n bẹ silẹ lorilẹede India, lẹyin ti ẹlẹsin Hindu ni ẹgbẹ oṣelu BJP bọ si ipo adari orilẹede naa.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cg399j17pxqo
yor
religion
Pakistan Blasphemy: Ìjà ẹlẹ́ṣìnmẹ̀sìn bẹ́ sílẹ̀ nítorí ọmọ ọdún mẹ́jọ tó tọ̀ sí ilé kéwú
Ọmọ ọdun mẹjọ kan ti wa ninu ewu idajọ iku lori ẹsun pe o tọ si ile ikawe ile ijọsin kan. Lọwọlọwọ bayi ọmọdekunrin ẹlẹsin Hindu yi wa ni abẹ aabo ọlọpaa ni Pakistan. Lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o mọọmọ tọ sara ninu ile ikawe ile ijọsin. Ọmọde yi ni ẹni tọjọ ori rẹ kere julọ ti wọn fẹsun kan pe o tabuku ẹsin ni ilẹ naa to se pe ijiya iku lo so mọ ẹsẹ yi. Wọn fi ẹsun kan pe o mọọmọ tọ si ori itẹ ninu ile ikawe Madrassa ti wọn ko awọn tira si losu to kọja. Awọn mọlẹbi ọmọdekunrin yi ti sa asala fun emi won. Nigba ti ọpọ awọn ẹlẹsin Hindu ni Punjab naa si sa asala fun ẹmi wọn. Eyi waye lẹyin ti awọn musulumi kan ya bo ile ijọsin awọn Hindu lẹyin ti ile ẹjọ gba oniduro ọmọdekunrin naa ti wọn si ni ko maa lọ sile. Ọrọ yi le debi pe wọn ti ni kawọn ọmọọgun lọ si adugbo isẹlẹ yi lati le daabo awọn eeyan. Lọjọ Abamẹta, eeyan ogun ni awọn agbofinro mu lori ẹsun pe wọn dana sun ile ijọsin Hindu. Ọkan alara awọn mọlẹbi ọmọ yi to foripamọ ba awọn akọroyin sọrọ. O ni ''ọmọ yi ko tiẹ mọ nipa ẹsun itabuku ẹsin ati pe ko tiẹ yee bayi ohun ti o jẹ ẹsẹ rẹ ati idi ti wọn fi fi si ahamọ fọsẹ kan''. O salaye pe " A ti fi sọọbu wa ati isẹ wa silẹ salọ.Gbogbo wa lẹru n ba wa pe wọn le wa gbẹsan nipa ikọlu si wa.A o fẹ pada si agbegbe yi.'' O ni awọn ko lero pe wọn yoo gbe igbesẹ kan to jọju lati le mu awọn to wa nidi ikọlu yi tabi daabo bo awọn ẹya ti ko lẹnu lọrọ lagbegbe ọhun. Nise ni ọrọ yi se awọn amọfin ni kayeefi lori bi wọn se fi iru ẹsun yi kan ọmọde. Ramesh Kumar, agbẹjọro to si tun jẹ olori ẹka alasẹ Hindu ni ''ikọlu tawọn eeyan se si ile ijọsin Hindu ati ẹsun itabuku ẹsin Islam ti wọn fi kan ọmọde yi ya mi lẹnu. O ni o le ni ọgọ́run idile Hindu to ti sipo pada nitori ibẹru lori isẹlẹ yi. O wa parọ́wa si ijọba lati pese aabo to peye. Ikọlu sawọn ile ijọsin Hindu lẹnu ọjọ mẹta yi pọ si nitori awọn alakatakiti ẹsin ati awọn to gba nkan mii mọ ẹsin.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58177577
yor
religion
Dare Adeboye, #PDee àti #NotTodaySatan, I'm not leaving God: Ẹ wo bí Leke Adeboye, àwọn ọ̀dọ́ ìjọ RCCG ṣe gẹ irun wọn láti bú ọlá fún olóògbé Dare Adeboye
Gbogbo eto lo ti bẹrẹ fun eto isinku oloogbẹ, Pasitọ Dare Adeboye to jẹ ọmọkunrin ikeji Pasitọ Enoch Adeboye to jẹ adari ijọ Redeem Christian Church of God lagbaye. Ọjọ Kọkanla, Oṣu Karun un ni yoo wọ kaa ilẹ sun, amọ lati Ọjọ Aiku ọṣẹ naa ni ayẹyẹ ikẹyin loriṣiriṣi ti bẹrẹ fun un pẹlu awọn ọdọ ijọ naa ti wọn gẹ irun ori wọn lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun oloogbe naa. Pẹlu Hashtag #PDee ati #NotTodaySatan, I'm not leaving God, ni wọn n lo lati fi aworan wọn sita pẹlu bi wọn fa irun wọn lori ayelujara. ''Awọn ọrọ akọle ti wọn ko si be ni pe'' A o bẹru iku mọ, iye ayeraye ni tiwa ni aye ati ni orun ti n bọ. Kikuro ninu ara mu mi wa pẹlu Oluwa ninu ẹmi'' ''Ki emi wa laye ni lati wa ninu Kristi, ki emi si ku jẹ ere nitori iye ayeraye ni - Phillippians 1:21.'' Ẹni akọkọ to kọkọ gẹ irun rẹ ni aburo oloogbe naa, Leke Adeboye ki awọn ọmọlẹyin Kristi ninu ijọ naa kaakiri agbaye to bere lati ma a ṣe gẹgẹ bi Leke ṣe n ṣe. Ninu fidio to fi lede lo ti sọ wi pe iṣe wọn ni lati bu ọla fun ẹni to ba jẹ akinkanju ọkunrin to jẹ ọdọ ninu Kristi, to si ja fitafita fun ọrọ Ọlọrun ki o to rekọja kuro ni aye. Ọpọlọpọ eniyan lo si ti bẹrẹ si ni fesi si irun gigẹ naa lati bu ọla fun ẹni to doloogbe. Ọpọ sọ wi pe kii ṣe ọna igbagbọ lati gẹ irun nitori oloogbe to kọja lọ nigba ti awọn miran ni o dara bẹẹ nitori ẹni ọdun mejilelogoji ni Dare ko to di oloogbe. Ọjọ kẹfa, oṣu Karun un, ọdun 2021 ni iroyin iku pasitọ Dare Adeboye fa ori ayelujara ya. Iroyin iku rẹ da omi tutu si ọkan gbogbo eeyan, paapaa awọn ọmọ ijọ Redeemed Christian Church, RCCG, ni Naijiria ati loke okun. Dare Adeboye nigba aye rẹ jẹ ọkan lara awọn ọmọ alufa agba, to tun jẹ adari ijọ RCCG kaakiri agbaye, pasitọ Enoch Adejare Adeboye. Wọn bi Dare Adeboye ni ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹfa, ọdun 1979. Dare jẹ olukọ awọn ọdọ, o jẹ ẹnikan to ko awọn eeyan mọra, o si tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọdọ to lẹnu lọrọ ati ilumọka ninu ijọ RCCG. Orukọ ti ọpọ awọn ọdọ ninu ijọ irapada maa n pe ni "Pastor Dee tabi PD".
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57053601
yor
religion
Ọlọ́pàá mú pásítọ̀ tó kó àwọn ọmọ ìjọ pamọ́ sí àjà ilẹ̀ l'Ondo, Ó ní oṣù kẹsàn án ni 'Jesu' yóò dé
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ alufa ijọ kan nilu Ondo ati igbakeji rẹ tim wọn fi itanjẹ ko awọn ọmọ ijọ ni papa mọra pe Jesu yoo de ni oṣu kẹsan ọdun yii. Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti ṣalaye ọrọ lori awọn ti wọn ko nni ijọ naa pe wọn kii ṣe ọmọde nikan. Alukoro ileeṣẹ ọ̀lọpaa nipinlẹ Ondo, SP Ọdunlami ṣalaye pe alufa ijọ naa sọ fun awọn ọmọ ijọ naa pe aye yoo parẹ loṣu kẹsan an ọdun 2022, nitori naa ni gbogbo awọn ọmọ ijọ naa fi ko ara jọ pọ si ijọ naa ni ireti ipadabọ Jesu. Ileeṣẹ ọlọpaa ni eeyan mẹtadinlọgọrin ni wọn ko ninu ijọ naa ninu eyi to ni awọn agbalagba lo pọ julọ laarin wọn. “Ọpọ awọn ọmọde miran ni wọn ti fi fi ile wọn silẹ lati bii oṣu karun un lẹyin ti pasitọ naa ti sọ fun wọn pe Jesu yoo de loṣu kẹsan ko si si idi fun wọn lati kawe mọ.” Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ni iwadi ti bẹrẹ, bẹẹni pasitọ naa ati igbakeji rẹ ti wa ni atimọle awọn ọ̀lọpaa. Ọpọlọpọ awọn ọmọde ni wọn ri ninu aja ilẹ kan nile ijọsin kan lagbegbe valentino nilu Ondo nipinlẹ Ondo lalẹ ọjọ Ẹti. Gẹgẹbi ohun ti a gbọ, awọn ajinigbe lo ji awọn ọmọde naa gbe ti wọn si fi wọn pamọ sinu aja ilẹ nile ijọsin naa. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, SP Funmilayọ Ọdunlami ṣalaye fun BBC pe awọn ọlọpaa ti wa lagbegbe naa bayii lati tan ina wadii ohun to ṣẹlẹ nibẹ gan an. Amọṣa awọn iroyin atọwọdọwọ ti a gbọ lori iṣẹlẹ naa fi yeni pe, awọn ọmọde ti wọn ba nibẹ to aadọta, bi o tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ko  tii fi idi iye awọn ọmọ tyi wọn ba nibẹ mulẹ. Ninu fidio kan to n ja ranyin lori ayelujara, awọn ọmọde naa wa ninu ọkọ ọlọpaa kan eyi to gbe wọn lọ si agọ ọlọpaa. Amọṣa alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa ni wọn ti n ko awọn ọmọde naa lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa nilu Akurẹ. Ninu ọrọ to fi sita loju opo twitter rẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ SCID ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa. Bakan naa ni wọn rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati simẹdọ ki wọn si gba alaafia laaye. Bi ẹ ko ba ni gbagbe, laipẹ yii ni iṣẹlẹ manigbagbe waye nile ijọsin kan nilu Ọwọ nipinlẹ Ondo kan naa nibi ti awọn agbebọn ti ṣeku pa eeyan ti ko din ni ogoji.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cl7gnpk7kdjo
yor
religion
TB Joshua dead: Ikú TB Joshua, Ọmọ Pasitọ Enoch Adeboye, Dare àti àwọn Pásítọ̀ jàǹkàn-jànkàn tí ikú wọn tí mí orílẹ̀èdè Naijiria
Iyalẹnu ati ibanujẹ ọkan ni awọn eniyan fi gbọ iroyin iku gbajugbaja Woli TB Joshua to ni ile ijọsin Synagogue Church of All Nations [SCOAN] to wa ni ilu Eko ni orilẹede Naijiria. Pasitọ naa jẹ gbajugbaja kaakiri agbaye ti awọn eniyan si ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to o ma n fi fun ni ni ọpọ igba. Pasitọ naa to ku ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọta lo mu jinni-jinni ba gbogbo awọn eniyan lagbaye paapaa awọn orilẹede ni iwọ guusu Naijiria. Iroyin iku pasitọ naa lo n waye lẹyin oṣu kan ti Dare Adeboye to jẹ ọmọ baba Enoch Adeboye, iyẹn adari ijọ Redeem Christian Church of God lagbaye jade laye. Akojọpọ awọn pasitọ ti iku wọn ti mi orilẹede Naijiria ni aipẹ yii ree. Ileesẹ iransẹ TB Joshua ti kede pe oludasilẹ ijọ naa ati agba wolii lorilẹede Naijiria, Temitope Balogun Joshua ti dagbere faye. Gẹgẹ bi ikede kan ti ileesẹ iransẹ naa ati ijọ Church Of ALl Nations fisita loju opo Facebook rẹ, ana ọjọ Satide, ọjọ karun osu Kẹfa ọdun 2021 ni agba wolii naa mi kanlẹ. Wolii Joshua, to dele aye ni ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1963, lo lo ọdun mejidinlọgọta loke eepẹ, ki ọlọjọ to de. Wolii Joshua sọrọ lọjọ Satide lasiko ipade to se pẹlu awọn alabasisẹpọ rẹ fun ileesẹ mohunmaworan ijọ rẹ, Emmanuel TV, to si dabi ẹnipe o n sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ. Ọgọọrọ eniyan ti o pejọ pọ si ijọ rẹ ni Ọjọ Isinmi, Ọjọ Kẹfa, Oṣu Kẹfa lati ṣe ikẹdun iku akọni naa to re ọrun aremabọ. Apapọ ẹgbẹ awọn ọmọ Pasitọ ni ijọ Redeemed Christian Church of God lo fi kede sita pe Oluwadamilare Temitayo Adeboye ti jade laye. Awọn ọdọ ijọ RCCG ni pẹlu ọkan wuwo ni awọn fi kede ipapoda ọmọ wọn, ẹgbọn wa, ọkọ ati baba wọn, Oluwadamilare Temitayo Adeboye to lọ ba Ọlọrun ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrin oṣu karun ọdun 2021". Atẹjade naa ka wipe igbe aye rẹ jẹ igbe aye rere gẹgẹ bo ṣe sin Ọlọrun lai kaarẹ, to n fun ni. to si n dari lai si ifoya. "Bo tilẹ jẹ pe iroyin yii fi wa gidi gan, a duro lori Jesu Kristi ninu ẹni ti a ni idaniloju pe a o pade nibi ti ko si inira". Ẹni ọdun mejilelọgoji ni Pasitọ Damilare Adeboye ki o to jẹ kuro laye. Pasitọ Elijah Abina, to jẹ adari ijọ Gospel Faith Mission International, GOFAMINT, ti padanu ọmọ rẹ ọkunrin, Emmanuel Folorunso. Iroyin iku ọmọ Pasitọ Abina jade lẹyin ọjọ diẹ ti ọmọkunrin Pasitọ agba ijọ Redeem, Enoch Adeboye naa jade laye. Iroyin sọ pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ni Emmanuel Abina ku nilu Eko. Eyi to jẹ ọjọ kẹjọ ṣaaju iku ọmọ Adeboye. Ariwo ati ibanujẹ gbode lorilẹede Naijiria nigba ti iroyin iku pasitọ Ibidun Ighodalo to jẹ́ ọbinrin tó rẹ̀wà jùlọ nígbàkan rí, tó sì tún jẹ́ ìyàwó adarí àti olùdásílẹ̀ ìjọ Trinity House tan jade. Ibidunni Ighodalo náà kú ní ìdájí Ọjọ́ àìkú, Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Kẹfa, ọdun 2020 ní ìlú Port Harcourt, nípìnlẹ̀ Rivers nibi to ti lọ ṣèrànwọ́ kíkọ́ ibudó ti wọn yóò ti maa tójú àwọn aláàrùn Covid-19 nibẹ. Nurudeen Lawal to jẹ adarí Elizabeth R ti Pasitọ Ibidun jẹ oludasilẹ fun, sọ wi pe àwọn kò mọ ǹkan to ṣe ku paa nítori lẹ́yìn ti àwọn pari iṣẹ́ ní olúkúlùkù wọ yàrá rẹ̀ lọ láti sù, sùgbọ́n nígbà ti ilẹ̀ mọ́ ni ni kò jí mọ. Ibídùn fí ọkọ àti ìbejì rẹ̀ silẹ̀ sáyé lọ. Ariwo he lo jade lori ẹrọ ayelujara lẹyin ti ọdọmọde olowo ati oniṣowo ni ipinlẹ Eko, Kayode Badru ku iku ojiji ni ile ijọsin Celestial Church of Christ ni ilu Eko. Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹta, Osu Karun un, lasiko to n ṣe eto adura ninu ile ijọsin naa. Ọkan gboogi ninu awọn agba ni ile ijọsin ti iṣẹlẹ naa ti waye, Imolẹmitan Ojo ni Badru ṣẹ̀ṣẹ de lati Dubai wa si Naijiria lati wa ṣe ayẹyẹ to ti wa pin nkan fun awọn eniyan. Imọlẹmitan ni ọpẹ́ ní Kayode Badru ń ṣe pẹ̀lú imọlẹ meje ti o fi n ṣe ọpẹ naa ki o to di wi pe nkan yiwọ. O ni: ''Funrara Kayode Badru lo tan imọlẹ meje to fẹ fi ṣe ọpẹ ni Ọsan Ọjọ Aje naa, ti o fi dupẹ lọwọ Ọlọrun ''Lẹyin naa ni wọn gba imọlẹ meje naa ni ọwọ rẹ, ti wọn si sunmọ kuro ni ọdọ rẹ, ki Woli Ebony to gbadura fun un to si wọn 'perfume' si i lara amọ ko pọju bi o ṣe yẹ lọ'' ''Ti ina fi jo Kayode ni ara ko ju iṣẹju aaya ọgbọn, ti ko si to iṣẹju kan ti awọn eniyan to wa nibẹ fi sare digbadigba lọ bu omi ti wọn si pa ina naa''. Arakunrin Imọlẹmitan tun ṣalaye fun BBC ''nii Ọjọọru ti mo pada lọ si ile iwosan lo wo o, Kayode Badru sọ fun mi pe oun jẹun, o jẹ amala to si mu olomiọsan, amọ Ọjọbọ ni wọn sọ fun mi pe o ti jade laye''. Iku doro, iku ṣeka, iku ti mu gbajugba ajiyinrere agbaye, Reinhard Bonnke lọ lẹni ọdun mọkandinlọgọrin. Ninu atẹjade kan ti iyawo rẹ, Annie Bonnke buwọ lu loju opo Facebook rẹ ni wọn ti kede iku ojiṣẹ Ọlọrun yii. Wọn sọ ninu atẹjade naa pe pẹlu alaafia ni Ọgbẹni Bonnke fi pada lọ ba Ẹlẹdaa rẹ ni ọrun. Fun ọgọta ọdun sẹyin, Bonnke ṣiṣẹ ajihinrere kaakiri agbaye papaa julọ nilẹ Afirika, o ṣe eto isọji kaakiri awọn orilẹ-ede, ti awọn ọmọlẹyin Kristi ni orilẹede Naijiria si gba tirẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57377004
yor
religion
COZA RAPE Allegation: Ìdí rèé tí mi ò fi yọjú sí ìgbìmọ̀ àjọ PFN- Fatoyinbo
Oludasilẹ ijọ Commonwealth Of Zion Assembly ti ọpọ mọ si COZA, Biodun Fatoyinbo ti iyawo gbajugbaja olorin Timi Dakolo, Busola Dakolo fẹsun ifipabanilopọ kan ti ṣaleye pe agbẹjọro oun lo gba oun ni imọran pe k'oun maa yọju si igbimọ ajọ PFN. Fatoyinbo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lati ọwọ amugbalẹgbẹ rẹ, Ademola Adetuberu. O sọ ninu atẹjade naa pe o ti gbangba pe igbimọ PFN yoo ṣegbe lẹyin ẹnikan ni ko jẹ ki oun lọ siwaju wọn. Adetuberu ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe lootọ ni pasitọ Akinola Akinwale pe Fatoyinbo lori aago pe ko wa farahan niwaju igbimọ PFN, ṣugbọn COZA sọ fun un pe ko le wa nitori iwadii si n lọ lọwọ lori ẹsun ti Busola fi kan an. O fikun ọrọ pe agbẹjọro sọ fun Fatoyinbo wi pe ko maa yọju si igbimọ naa nitori aarẹ ajọ PFN, Bisọpu Felix Omobude ti sọ tẹlẹ pe oun o mọ Fatoyinbo ri. Adetuberu tun sọ pe niṣe ni igbimọ ajọ PFN tun kọ lati fi iwe pe Fatoyinbo. O ni Fatoyinbo yoo yọju si igbimọ PFN tawọn ọlọpaa ba pari iṣẹ iwadii wọn lori ọrọ naa. PFN: Fatoyinbo kọ̀ láti yọjú ni ìwádìí wa kò ṣe parí Ajo awọn ẹni ẹmi ni Naijiria, eyi ti wọn n pé ni Pentecostal Fellowship of Nigeria (PFN), ti fi ọrọ lede pe awọn ko tii pari iwadii ti wọn n ṣe lori ẹsun ifipabanilopọ ti Busọla Dakolo fi kan Biọdun Fatoyinbo. Ẹni ti o jẹ akọwe fun ẹgbẹ naa, Biṣọọbu Emma Isong lo fi ọrọ naa lede nigba ti o n ba ileeṣẹ BBC sọrọ nilu Eko lowurọ oni. O sọ ninu ifọrọweró naa pe: olusọ agutan Biodun Fatoyinbo kọ lati yọju si ibi iwadii ti ajọ naa gbe kalẹ, bi o tilẹ jẹ pe, Busọla Dakolo ti yọju nitirẹ. Awọn ajọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé ìjọsìn pẹntikọsita ní Nàìjíríà (PFN) ti so pe iwadi ajọ naa si ẹsun ifipabanilopọ ti Busola Dakolo fi kan oludasilẹ ijọ Commonwealth of Zion Assembly (COZA), Pasitọ Biodun Fatoyinbo ko pari. Ajọ PFN sọ pe iwadii naa ko pari nitori Pasitọ Fatoyinbo kọ lati yọju si igbimọ ẹlẹni marun-un to n ṣewadii ẹsun naa. O te siwaju ninu ọrọ pe "iwadii ti ẹgbẹ PFN ṣe ko nii ṣe pelu iwadii ti awọn ọlọpaa." Iwadii ẹgbe PFN lo waye nitori awuyewuye awọn eniyan ati awọn oniroyin lori ẹsun naa.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49451547
yor
religion
Èèyàn méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jesu gún pasítọ̀ ìjọ RCCG pa nínú ṣọ́ọ́ṣì l'Eko
Awọn afurasi ọmọ ita ti pa pasitọ ijọ Redeemed Christian Church of God kan to wa ni Festac Town, nijọba ibilẹ Amuwo-Odofin, nipinlẹ Eko. Iroyin sọ pe inu ṣọọṣi RCCG Chapel of Resurrection ọhun ni wọn pa Pasitọ Babatunde Dada si, lọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 2021. Gẹgẹ bi iwe iroyin The Punch ṣe sọ, awọn meji kan to ṣẹṣẹ fi aye wọn fun Jesu ninu ijọ naa lo pa a . Iroyin sọ pe ọjọ Aiku to ṣaaju ọjọ naa, ni awọn ọdọ mejeeji jade sita lasiko ti ijọsin n lọ lọwọ pe awọn fi aye awọn fun Jesu. Koda, ọjọ ni ọjọ akọkọ ti wọn lọ si ṣọọṣi naa. Lẹyin ti wọn jade, ti wọn fi aye wọn fun Jesu, ni awọn alaṣẹ ile ijọsin naa fun wọn ni ile gbigbe ninu ọgba ile ijọsin ọhun, nitori wọn ni awọn ko ni ibi ti awọn n gbe. Ko si ti i to ọsẹ kan ti wọn ti n gbe inu ọgba ile ijọsin, ni iroyin sọ pe wọn gún pasitọ pa. Aya oloogbe naa, Bose Dada sọ fun awọn akọroyin pe ọkọ oun ni oluṣiro owo ati alamojuto ni ọfiisi ile ijọsin naa, to si tun jẹ oluṣọ agutan ni ṣọọṣi RCCG miran, Chapel of Glory, to wa ni Agboju. Ko ti i pẹ ti tọkọtaya naa ṣe igbeyawo, ti iyawo si wa ninu oyun. Bakan naa ni mọlẹbi rẹ kan, Abolarinwa Olatunbosun sọ fun iwe iroyin Punch pe lẹyin ti Pasitọ Dada gba owo ni banki ni wọn pa a. O ni o lọ gba owo ni banki, to si pada si ile ijọsin naa. Nibi to ti n sinmi ni aja kinni ṣọọṣi, ni wọn sọ pe awọn meji to ṣẹṣẹ fi aye wọn fun Jesu ọhun wọle lọ ọ ba loke, ti wọn si fọ ni ori, gun ni nkan pa ki wọn o to gbe owo lọ. Aburo oloogbe to ba BBC sọrọ, Akin Dada, ni ẹgbọn oun ni ṣọọbu kan nitosi ṣọọbu naa, nibi to tun ti n ṣe iṣẹ agbafọ aṣọ. O ni koda o tun gba awọn ọkunrin meji ọhun sibẹ lati ma a ba ṣiṣẹ. Bakan naa lo ni ọwọ ti tẹ ẹnikan lara awọn afurasi naa nilu Ilorin to salọ. Ọkan lara awọn foonu oloogbe ti wọn mu, ni awọn ọlọpaa fi tọpasẹ rẹ. Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu to fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC sọ pe iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ naa.
https://www.bbc.com/yoruba/59605992
yor
religion
Oloye Peter Fatomilola: Ọjọ̀gbọ́n olùkọ́ni ni Jesu àti Orunmila jẹ́, àwòkọ́ṣe sí rere si ni wọ́n
Wo bi Orunmila àti 'Mechizedek' inu Bíbélì ṣe tan mọ ara wọn- Peter Fatomilola Oloye Peter Fatomilola salaye ni kikun fun BBC Yoruba ajọṣepọ to wa laarin Jesu Kristi inu bibeli mimọ ati Orunmila. Ọjọ̀gbọ́n olùkọ́ni ni Jesu àti Orunmila jẹ́, àwòkọ́ṣe sí rere si ni wọ́n. Baba Peter Fatomilola sọrọ nipa iwa omoluwabi ninu iran yoruba. O gba awọn eeyan nimọran lati ni iwa omoluwabi lẹnu iṣẹ, ninu ile ati laarin ẹbi. Bakan naa lo gba imọran pe ki awọn akẹkọọ maa kọ nipa Ifa nile ẹkọ. Njẹ́ ìwọ ń ṣe ìfẹ́ Olodumare lẹ́nu iṣẹ́ rẹ bí? Ta ni Yorùbá ń pè ní Omoluwabi?
https://www.bbc.com/yoruba/58568477
yor
religion
TB Joshua Burial: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní kí ìjọ SCOAN tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò ìṣínkù Wòlí TB Joshua tí yóò bẹ̀rẹ̀ lónìí
Ijọba ipinlẹ Eko ti buwọlu eto isinku adari ijọ Synagogue Church of All Nations (SCOAN), Woli TB Joshua to jade laye. Eyi ko ṣẹyin bii ijọ naa ṣe n reti ọpọlọpọ eniyan kaakiri agbaye ti wọn yoo ma awa si ibi isinku naa lati oni lọ. Kọmiṣọnna fun eto ilẹra nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi to saaju awọn to ṣe abẹwọ sibẹ ni idi ti awọn fi lọ sibẹ ni lati ri pe wọn tẹlẹ ilana to de arun Coronavirus. Abayomi ni awọn n gbiyanju lati ri pe ọwọja ikẹta aarun Coronavirus to n kaakiri awọn orilẹede paapaa India, ko ja de Naijiria. O ni awọn ko fẹ ki arun Coronavirus to ti n rele ni Naijiria tun ru gẹgẹ si oke si nitori iye awọn eniyan to n bọ lati okeere wa si Naijiria. ''A tun fi asiko yii ba ẹbi ati ara oloogbe TB Joshua kẹdun ipapoda ẹni ire to lọ, paapaa ni asiko yii.'' ''Ohun ti a mọ ni pe orisirisi ọwọja aarun Coronavirus lo n ja kaakiri ni agbaye bayii, amọ a ko fẹ ko wọ ilu Eko.'' ''Lẹyin iku T.B Joshua ni gomina ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki a ṣe abẹwo to yẹ si ile ijọsin naa nitori eniyan nla lo kọja lọ, ti ọpọlọpọ eniyan yoo si pejọ sibẹ.'' ''Nibayii, gbogbo ẹni to ba n bọ gbọdọ wa ni ipamọ fun ọjọ meje, lẹyin naa ni wọn to le darapọ mọ ayẹyẹ kankan.'' Bakan naa ni kọmisọnna ohun ni gbogbo eto lo ti wa lati ri pe ẹnu ibode Naijiria gbogbo lo wa ni ilana idẹkun arun Coronavirus. Gẹgẹ bi eto isinku gbajugbaja Wolii agbaye ni ati ati oludari ijọ Synagogue Church of All Nations, Temitope Joshua yoo ṣe bẹrẹ lọsẹ yii, ijọ naa ti kéde ohun to yẹ ni ṣiṣe fun awọn ti yoo wa nibi eto isinku naa. Wọn ni bo tilẹ jẹ pe isin akọkọ ti yoo waye, kii ṣe gbogbo eniyan ni yoo lanfani lati wa nibẹ tori wọn ko ṣe aye silẹ fun gbogbogbo amọ awn ti ko ba si nibẹ lee ba awọn pe lori ayelujara tabi lorii tẹlifisan wọn. Ninu fidio ti wọn fi sita lori ayelujara ijọ SCOAN lowurọ oni yii kan naa ni wọn ti ki awọn eniyan nilọ pe ki wọn ṣọra fun awọn ọdaran to n dibọn bii ileeṣẹ tẹlifisan Emmanuel tabi ijọ SCOAN lati maa beere owo lọwọ wọn fun eto isin ikẹyin Woli TB Joshua. "Ole paraku ni iru awọn bẹẹ! Ẹ ma jẹ ki ẹnikẹni tan yin jẹ, Ọlọ run mọ bo ṣe n sọrọ si ọkan awọn eeyan lati na ọwọ si ohun ti a nilo. A o ran ẹnikẹni, a ko si ni ran ẹnikẹni lai lai". Ileeṣẹ naa ni awọn ni ọna ti awọn fi n kan si awọn onigbọwọ awọn nipasẹ Emmanuel TV to jẹ agbẹnusọ awọn. Lẹyin eyi ni wọn kede ilana bi eto isinku ti yoo bẹrẹ lọla yoo ṣe lọ laarin ọla ọjọ karun titi di ọjọ kọkanla oṣu keje eyi ti wọn n pe akori rẹ ni "kii ṣe temi, bikoṣe ifẹ Ọlọrun". Bí ìlànà ìsìnkú TB Joshua yóò ṣe lọ rèé - Mọ̀lẹ́bí kéde Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti Mo rí Áńgẹ́lì mẹ́fà tó wá gbé Wòlíì TB Joshua lọ sọ́run - Àlúfáà kan kéde Wo ohun tí Dele Momodu sọ nípa TB Joshua lẹ́yìn ikú rẹ̀ Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀ Ninu ikede naa ni wọn ti ni eto idagbere nipa titan abẹla yoo waye ni ọjọ Aje ọjọ karun oṣu keje. Wọn kede pe ki awọn to n bọ ma gbagbe ati mu abẹla wọn dani. Koda wọn ni "gbogbo ẹni ti ko ba le wa sibi eto naa, o lee tan abẹla ninu ile rẹ gẹgẹ bi ami didarapọ mọ wa lati inu ile lati bu iyi fun iranṣẹ Ọlọrun oloogbe TB Joshua". Lọjọ keji eyi ni wọn isin orin idagbere lataarọ yoo waye ninu ijọ SCOAN to wa ni Eko ninu eyi ti ẹ o ti lanfani lati jẹri nipa ohun rere ti Ọlọrun ti lo Wolii naa lati ṣe ninu aye yin. Isin ti wọn ni aaye rẹ wa ni ṣiṣi fun gbogbo awọn eeyan amọ pẹlu aaye ijoko to lonka ni eyi ti yoo waye l'Ọjọbọ ati ọjọ Ẹti. Bi ko ba gbagbe, laip ti ikede iku Wolii Temitope jade ni Ọba ilu ibi rẹ, Arigidi-Akoko ti sọ fun ẹbi pe awọn n f ki wọn wa bu iyi fun ilu awọn nipa sinsin oku rẹ si Arigidi amọ ij pada kede ninu ijọ wn to wa ni Eko ni yoo ti waye. Nibayii, ijọ Synagogue Church of All Nations ti kede iyawo oloogbe gẹgẹ bi adari tuntun. Sunday Igboho kọ̀wé sí ìjọba àpapọ̀, o ní dandan kí wọn sàn owó gbà má bínú ₦500m ''Ṣọ́ọ̀bù ìyá rẹ̀ ní Jumoke wá tí ìbọn ọlọ́pàá ti pa lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota'' Kò jọ́ọ́! Àṣìṣe kọ́, Ọlọ́pàá mọ̀ọ́mọ̀ pa ọmọ ọdún mẹ́rínlà lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota - Femi Falana Gbogbo ìpilẹ̀sẹ̀ ìṣoro Nàìjíríà ni àtúnyẹ̀wò òfin ta ń ṣe yìí yóò mójútó - Gbajabiamila Ọkọ̀ òfurufú ọmọ ogun já lulẹ̀, èèyàn 92 ló wà nínú rẹ̀ Wo ohun tó yẹ kí o ṣe sí ojú abẹ́ rẹ, ''vagina'' lẹ́yìn ìbálòpọ̀
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57711414
yor
religion
T.B Joshua: ...Àwọn ọmọ ẹ̀yin ń sọ̀fọ̀, ìdá mẹ́ta àǹgẹ́lì Olorun dójútí Lucifa tó lọ- Pasito Chris Okotie
Ibinu nla lati oke wa ti mu anjonu to n jẹ́ Emmanuel lọ, bẹ́ẹ̀, awọn ọmọ lẹ́yin rẹ́ n sọ̀fọ̀ ipapoda abuku rẹ̀- Pasito Chris Okotie Pasito Chris Okotie jẹ́ ọ̀kan lara awọn pasito ti won ti sọ̀rọ̀ sita lẹ́yin iku Wolii TB Joshua. Okotie sọ̀rọ̀ yii lori ero ayelujara ni eyi ti wọ́n ni o wa fun oludasilẹ̀ ijọ Household of God International Ministries. Ọ̀pọ̀ awon omo Naijiria, lo ti faraya lori ayelujara lori ọ̀rọ̀ Okotie naa. Won n sọ pe ko kuku si ẹni ti ko ni ku. Bẹ́ẹ̀, wọ́n ni ọ̀rọ̀ naa ti pọ̀ ju. Nitooto Chris Okotie ko darukọ kankan ju Emmanuel to fi kun srọ̀ rẹ̀ lọ Sugbọ́n awn eeyan n ni pe o jọ gate, ko jọ gate, o n fi ẹ̀sẹ̀ mejeji tiro ni ọ̀rọ̀ naa jọ. Awọ́n to n sọ̀rọ̀ loriayelujara ni eyi ko seyin Wolii TB Joshua to ku yii to si je pe Emmanuel naa ni orukọ́ ile ise amohunmaworan re ti ijọ Synagogue Church of All Nations (SCOAN). Ẹni akọkọ to kọkọ tako TB Joshjua ni Pasitọ Chris Okotie, ti ijọ Household of God, nigba to ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi iransẹ esu lagbaye, to fẹ da ijọ Ọlọrun ru ni Naijiria. Okotie ti ko fi igba kan sọ ọrọ TB Joshua ni rere sọ wi pe, o n ṣiṣẹ pẹlu agbara ẹmi okunkun lati sọ agbara ijọ ni Naijiria di okunkun nitori ifẹ esu ni ohun ṣe. Bakan naa ni Pasitọ naa ko fi ẹhọnu rẹ bo, nigba ti o ri fidio ti Pasitọ Chris Oyakhilome ati TB Joshua ti n gbadura fun arakunrin kan to rọ lapa rọ lẹsẹ. Gbajugbaja akọroyin, Dele Mọmọdu ti fesi lori iku oloogbe T.B Joshua Dele Momodu ń bèèrè pé ṣe ẹgbẹ́ CAN àtàwọn pásítọ̀ ṣì ń bá olóògbé jà ni lẹ́yìn ikú rẹ̀? Ṣugbọn yatọ si pe o daro iku wolii naa, ibeere to n beere ni pe ki lo de ti awọn ẹgbẹ ẹlẹsin Kristiẹni ko ti i sọ nkankan nipa iku rẹ. Lati owurọ ọjọ Aiku ti iroyin iku Joshua ti jade, ni ọpọlọpọ eniyan kaakiri agbaye ti n daro rẹ, ti wọn si n sọ oriṣiriṣi nkan nipa rẹ. Amọ, akiyesi fihan pe ko si ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi kankan bi Christian Association of Nigeria, CAN, Pentecostal Fellowship of Nigeria, to fi mọ awọn iranṣẹ Ọlọrun to gbajumọ, ko ti i sọ ohunkohun nipa akẹẹgbẹ wọn to lọ. Ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ, Momodu sọ pe "o ga o, pe ko ti i si ọrọ kankan nipa iku TB Joshua lati ọdọ awọn ọmọlẹyin Kristi. Se wọn tun ṣi korira rẹ lẹyin to ku ni?". "Ko nilo ibuwọlu ẹnikẹni... Gbogbo ọkan ni yoo ku." A ko le sọ idi ti awọn eeyan yii ko ti i sọ ọrọ tabi daro iku wolii naa, tabi iru ibaṣepọ to wa laarin TB Joshua ati ẹgbẹ awọn Kristiẹni nigba to fi wa laye. Amọ awọn iroyin ti a ko le fidi rẹ mulẹ to n lọ ni pe awọn ẹgbẹ Kristiẹni ati awọn gbajugbaja iranṣẹ Ọlọrun kan ni Naijiria ti sọrọ ri pe, awọn ko le gba T.B Joshua laaye ninu ẹgbẹ awọn. Bakan naa ni wọn ni awọn ko ni lọ si ṣọọṣi rẹ fun iṣẹ iranṣẹ "nitori pe kii ṣe ẹni igbala, bẹẹ ni orisun iṣẹ iyanu to n ṣe ko mọ ọ". Ọpọ igba ni awuyewuye waye lori iṣẹ iranṣẹ rẹ. Laipẹ yii ni ileeṣẹ ayelujara Youtube pa oju opo rẹ lọdọ wọn rẹ, nitori fidio kan ti Joshua ti sọ pe oun n wo awọn ọkunrin to n ni ibalopọ pẹlu ọkunrin ẹgbẹ wọn san. Yatọ si eyi, awọn igba kan wa ti awuyewuye ti waye ri nipa rẹ nitori awọn asọtẹlẹ to sọ ti ko wa si imuṣẹ. Bakan naa ni lọdun 2014, nigba ti ile kan wó ninu ọgba ile ijọsin Synagogue, to si pa eeyan to le ni ọgọrun. Pupọ ninu awọn eeyan naa lo wa lati orilẹ-ede South Africa. Yoruba ni ta ba ku laa dere, eeyan ko sunwọn laaye. Pasitọ Ijọ Synagogue Church of All Nations, Wolii Temitope Balogun Joshua to dagbere faye ni ọpọ eeyan n kọrin re ki lẹyin iku rẹ pe oloore lọ. Amọ ni ọpọ igba, ni ọrọ nipa agba wolii naa ti fa awuyewuye, ti wọn si n beere pe ṣe lootọ ni Woli naa jẹ iranṣẹ Ọlọrun? Lati igba ti Woli TB Joshua ti bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi eniyan Ọlọrun ni ọpọlọpọ eniyan ti ma n tẹle fun itusilẹ lọwọ ẹmi okunkun, igbala ẹmi wọn ati iṣẹ iyanu. Kaakiri orilẹede agbaye si ni awọn eniyan ti maa n wa si ile ijọsin rẹ fun igbala ati iwosan, ti ọpọlọpọ ṣi n jẹri si pe agbara rẹ daju. Amọ ọpọlọpọ awọn pasitọ miran lo ri Joshua nigba aye rẹ, gẹgẹ bi onirọ, to kan n fi orukọ Ọlọrun jẹun ati ẹlẹgbẹ okunkun to n lo agbara ẹmi okunkun ati awọn alawo lati fi ṣe iwosan. Diẹ lara aero awọn ojisẹ Ọlọrun miran ree nipa TB Joshua lasiko to wa loke eepẹ. Ohun ti Chris Okotie sọ nigba naa ni pe, o ṣeun ni aanu pe Chris Oyakilhome n ṣepọ pẹlu TB Joshua. O si tẹnumọ pe ẹlẹgbẹ okunkun ni pasitọ naa, to si bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe n pe e ni ''Emmanuel'', orukọ ti wọn n pe Jesu Kristi, to jẹ adari gbogbo ijọ Kristẹni lagbaye. TB Joshua kii ṣe ara wa, ẹlẹgbẹ okunkun ni - Pentecostal Fellowship of Nigeria Lasiko ti ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, Pentecostal Fellowship of Nigeria dahun si ija laarin TB Joshua ati Chris Okotie, ni wọn sọ wi pe TB Joshua kii ṣe ara awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria. Bisọọbu Mike Okonkwo, to jẹ adari ẹgbẹ Pentecostal Fellowship of Nigeria nigba naa ni TB Joshua kan n farapẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria ni, kii ṣe ara wọn rara. O wa kilọ fun un pe ko ma pe ara rẹ ni ara ijọ Pentecostal lorilẹede Naijiria. Ninu ọrọ tirẹ, Pasitọ ijọ Revival Assembly Church ni ipinlẹ Eko, Anselm Modubuku ni ko si otitọ ninu ọrọ ti TB Joshua sọ wi pe ati inu iya oun ni oun ti di atunbi, ti o si ti ṣi ọpọlọpọ onigbagbọ ni ọna iye. Bakan naa ni pasitọ ijọ Word of Life Bible Church, Ayo Oritsejafor ni ilu Warri ni oun ko mọ oun ti awọn ara ilẹ Amẹrika ri lara TB Joshua, ti wọn fi n wọ tẹle nitori oun tikararẹ ko ni ẹni to mọ igba to fi aye rẹ fun Jesu, tabi ta ni pasitọ rẹ. Ara ijọ Synagogue Church of All Nations, to ti tun jẹ ọrẹ timọ timọ si TB Joshua, Oye Ogunwale ni ahesọ ni gbogbo ọrọ ti awọn eniyan miran n sọ nipa rẹ, paapaa awọn pasitọ ni Naijiria. Ogunwale ni eniyan Ọlọrun ni TB Joshua, ti ko si ni ohun ikọkọ tabi agbara okunkun kankan nitori oun ti mọ lati bi ọdun mẹwaa ṣẹyin. O ni awọn to n sọrọ rẹ ni aida ni awọn ti ko ri iwosan gba nigba ti wọn lọ si ile ijọsin rẹ, amọ o fi n da awọn eniyan loju wi pe o kere tan, TB Joshua n wo awọn alaisan HIV/Aids bii mẹwaa san ni ọṣẹ kan. Ogunwale ni o ṣe ni laanu wi pe ọrọ TB Joshua dabi ti oloye Obafemi Awolowo, to jẹ wi pe lẹyin iku rẹ ni awọn eniyan ṣẹṣẹ rii gẹgẹ bi olori to dara. O ni igbagbọ ni wọn fi n ri iwosan gba ni ọdọ TB Joshua, amọ ẹni ti ko ba ri idariji gba lati ọdọ Ọlọrun, ko le e ri iwosan gba lọdọ rẹ. Amọ, awọn miran fi ẹsun kan TB Joshua wi pe, ẹmi okunkun lo fi n ṣe iwosan fun awọn eniyan nitori ti wọn ba ri iwosan gba lẹṣẹkẹṣẹ, aisan naa yoo tun pada pa eniyan bẹẹ ni, laipẹ si ara wọn.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57376560
yor
religion
Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab
Awọn musulumi ati Kristiẹni ti wọn wa ni ti salaye ohun to tun fa akọtun ija ẹsin ni ile ẹkọ Oyun High School to wa nilu Ijagbo, nipinlẹ Kwara. Nigba ti BBC Yoruba kan silu Ijagbo nipinlẹ Kwara nibi ti akọtun ija ẹsin tun ti suyọ laipẹ yii, awọn asaaju Kristiẹni ati Musulumi salaye idi ti wọn se gboju agan sira wọn. Ninu ọrọ ti wọn ba wa sọ, irin kan ko tẹ fun ekeji, ti ko si si eyikeyi ninu wọn to gba pe igbesẹ ti ẹnikeji gbe tọna. Koda, wọn n di ẹbi aawọ lilo Hijab naa ru ijọba pe ko se ojuse rẹ bo se yẹ, to si tun yẹ adehun to wa nidi gbigba awọn ile ẹkọ lọwọ awọn ẹlẹsin. Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, alaga fun ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi (CAN) ni ilu Ijagbo, Ẹni-ọwọ Olanrewaju Ajayi salaye pe ohun to n fa ija ju ọrọ lilo Hijab lọ ni awọn ile ẹkọ Kristiẹni. O ni awọn ti gbọ pe ijọba fẹ yi awọn orukọ awọn ile ẹkọ to jẹ ti Kristiẹni pada ni amọ o kan kọkọ bẹrẹ pẹlu lilo Hijab ni. “Ijọba n lo agbara oselu le wa lori nitori pe musulumi ni gomina wa, o si wa n lo agbara rẹ fawọn musulumi. A mọ ibi ti wọn n lọ pe ibi ti wọn ti fẹ duro lori ọrọ naa kọja lilo Hijab, wọn kan n fi se bojuboju ni. O ni adehun ti wa laarin awọn Kristiẹni ati ijọba nigba ti wọn fẹ gba ile ẹkọ lọwọ awọn ẹlẹsin pe akoso awọn ile ẹkọ yoo maa wa mi ikawọn awọn ẹlẹsin. O fikun pe lati ẹyin wa, awọn Kristiẹni lo maa n sọ ẹni ti yoo di ọga ile ẹkọ ni awọn ile ẹkọ to jẹ ti awọn Kristiẹni naa. Ti wọn ba fi gbe ọrọ Hijab wọle tan, diẹdiẹ ni wọn yoo yan ọga ile ẹkọ to jẹ Musulumi sawọn ile ẹkọ Kristiẹni lati maa se akoso ibẹ. Ogun wa ni ile ẹkọ ti Kristiẹni yii jẹ, a ko si setan lati yọnda rẹ fun ẹnikẹni.” Ajayi ni ọgbọn ẹwẹ ni ijọba n lo, awọn mọ ibi ti wọn n lọ, ki wọn si lọ jawọ ninu asẹ pe kawọn akẹkọ maa lo Hijab lawọn ile ẹkọ Kristiẹni . BBC Yoruba tun tẹsiwaju lati ba awọn obi to jẹ musulumi to ni ọmọ ni ile ẹkọ Oyun High School sọrọ. Mallam Ajibola Yusuf, lasiko to n ba BBC sọrọ ni oun ri ẹda iwe tijọba fi ọwọ si pe awọn akẹkọ to ba jẹ Musulumi le lo ibori, taa mọ si Hijab lọ sile ẹkọ wọn to ba wa labẹ akoso ijọba. Ẹda iwe yii lo ni awọn obi ri tawọn akẹkọ musulumi fi n lo Hijab sugbọn ti awọn ọga ile ẹkọ to jẹ ti Kristiẹni n kọ fun wọn lati lo. “Lootọ ni wọn ko mu awọn ọmọ wa nipa lati se ẹsin Kristiẹni ni ọna ti gbogbo aye yoo fi mọ, amọ wọn n mu wọn nipa labẹnu, ara rẹ si ni kikọ lati jẹ ki wọn lo Hijab. Apẹrẹ jijẹ Musulumi ni lilo Hijab, ti ẹ ko ba si jẹ ki wọn lo, yatọ si igba ti wọn ba fẹ kirun, ẹ ti mu wọn nipa niyẹn. A wa n rọ ijọba lati lo gbogbo agbara to ba wa ni ikawọ rẹ, ko fi paarọ orukọ awọn ile ẹkọ ẹlẹsin yii nitori abẹ akoso ijọba ni wọn wa. Ohun to si le dẹkun aawọn ilẹ yii ni ki wọn fi asẹ lilo Hijab mulẹ ni awọn ile ẹkọ naa fawọn akẹkọọ to jẹ Musulumi.” Yusuf ni awọn ko mọ ohun ti aawọ lilo Hijab yii le bi lọla, ti ijba ko ba gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ. Ọdun 1974 la gbọ pe ijọba ipinlẹ Kwara gba akoso awọn ile ẹkọ girama ti awọn ẹlẹsin Kristiẹni ati Musulumi kọ lori awijare pe awọn ile ẹkọ ti ijọba kọ ko to. Ijọba si ba awọn ẹlẹsin naa se adehun pe awọn yoo maa san owo awọn olukọ ti wọn ba n sisẹ lawọn ile ẹkọ ẹlẹsin naa, ti akoso ile ẹkọ yoo si wa lọwọ awọn ẹlẹsin. Amọ ni bi ọdun kan sẹyin ni ariwo ta pe awọn ile ẹkọ kan nipinlẹ Kwara to jẹ ti Kristiẹni ko gba awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi laaye lati lo Hijab, eyiun ibori wa sile ẹkọ. Ọrọ naa fa rogbodiyan nla, ti ọpọ eeyan si se lese, ti aimọye dukia si bajẹ bakan naa. Idi ree ti ijọba ipinlẹ naa se se ofin pe awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi ni asẹ lati maa lo Hijab lawọn ile ẹkọ ijọba to n jẹ tawọn ẹlẹsin Kristiẹni. Wahala naa ti lọ silẹ di ni ipinlẹ Kwara lati igba ti ijọba ti se ofin naa amọ se ni laasigbo naa tun dede su yọ ni ile ẹkọ Oyun High School to wa nilu Ijagbo. O ti le ni ọdun kan bayii ti aawọ ẹsin ti n da omi alaafia ru ni awọn ile ẹkọ to jẹ ti Kristiẹni nipinlẹ Kwara. Koda, aawọn naa ti mu ọgbẹ nla ba awọn eeyan kan lasiko rogbodiyan to waye ni ọdun to kọja. Bakan naa ni ọpọ ile ẹkọ ni ijọba gbe ti pa nitori rogbodiyan naa, to si se ipalara fun eto ẹkọ lasiko naa.
https://www.bbc.com/yoruba/agbaye-60314293
yor
religion
Kwara Hijab Crisis: Ìjọbá ńi akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Mùṣùlùmí le lo ìbòrí gẹ́gẹ́ bó ṣe ń wáyé l‘Eko, Osun, Oyo
Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe kawọn ileewe mẹwa to gbe ti pa tẹlẹ nitori aawọ lilo Hijab di sisi pada. Atẹjade kan tijọba fisita lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe bi ijọba se fọwọsi ilana pe akẹkọọbinrin to ba nifẹ lati lo Hijab lawọn ileẹkọ ijọba le lo yoo mu ki alaafia jọba, ti ibagbepọ alaafia yoo si wa. "Igbesẹ alaafia ta gbe yii yoo mu ibọwọfunraẹni, agbọye ati alaafia pada sawọn ileẹkọ, paapaa niwọn igba ti ẹkun ariwa Naijiria ati ọpọ ipinlẹ lẹkun iwọ oorun guusu bii Eko, Osun, Ekiti ati Oyo ti fara mọ pe kawọn akẹkọbinrin maa lo Hijab." "Nibayii tawọn akẹkọ n wọle pada si kilaasi, ijọba n sakiyesi isoro ti ọpọ awọn akẹkọjade to fẹ sedanwo WAEC n koju. A si ti pasẹ pe kawọn ile ẹkọ ti wọn ti pa tẹlẹ naa maa se afikun lẹsinni wakati meji fawọn akẹkọjade naa lẹyin ti akoko eto ẹkọ ba pari lojoojumọ, tijọba yoo si tun pese ipanu fun wọn." Ijọba ipinlẹ Kwara wa gbosuba fawọn asaaju Kristiẹni ati Musulumi fun agbọye wọn ati aayan lati jẹ ki alaafia jọba lagbegbe wọn lati ọsẹ diẹ sẹyin ti rogbodiyan naa ti bẹrẹ. Gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ kan nípìnlẹ̀ Kwwara lo ti n sọ ìwòyè wọ́n lórí rúkèrúdò tó n wáye ní ìpínlẹ̀ Kwara Sáájú ni égbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kriténi ti sọ èrò wọ́n, bákan náà ni BBC Yoruba bá akọwé ẹgbẹ́ IEDPU nílùú Ilorin sọ̀rọ̀ Lásìkò tó n bá wá sọ̀rọ̀ ó sàlàyé pé ìgbésẹ̀ ìjọba tọ̀nà ó sì bá òfin mú, nítorí pé kò sí ǹkan tó tako òfin nínú ǹkan to ti n wáyé tẹ́lẹ̀. O ní gbogbo eniyan lo ni ẹtọ lati peju si ibikibi ninu awujọ gẹ́gẹ́ bi ofin se sọ. Ẹtọ ọmọ Musulumi ni lati lo Hijab nítori ilana lati sin ẹsin to wú wọ́n jẹ́ ọkan lara ẹtọ ọmọniyan, bákan náà ni wọ́n le wọ irú asọ to bá wù wọ́n. Ọjọgbọn Oba Abdulhamid salaye pe ti eniyan ba ti wa ni iru ẹtọ yii, gbogbo ibi to ba ti jẹ ìta gbpangba ni, wọn lẹtọ lati wọ ibẹ̀. "Àwọn ilé iwé yìí owó ori ni wọn fi n san owo àwọn olùkọ tó wà nibẹ, nítori naa nkan ijọba ni." Ọ̀rọ̀ Hijab kìí se ǹkan tuntun n\itori náà kò yẹ kí ó jẹ́ ǹkan ti yóò maa dí ọja ọla àwọn ọmọ lọ́wọ́ "Ẹlẹ́sìn méjèèjì ló ti jọ n gbé pọ̀ lálàfíà láti ẹ̀yìn wá tí kò sì sí wàhálà, "láyèé ti ọ̀pọ̀ ń sáré láti gbé àwọn ǹkan mere mere ṣe yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹsin ló yẹ lásìkò yìí" Ọ̀jọ̀gban náà ni kò pé kí ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ máa dá wà pàápàá jùlọ ni àwọn ilé iwé, ó sọ èyí nítorí àwọn tó n sọ pé ki àwọn tó bá jk musùlùmí máa lọ sí ilé ìwé tí Musulumi bá dá síll kí àwọn Kiristẹ́nì sì má lọ sí ibi tí wọ́n. Ó ní ó ṣe pàtàkì kí àwọn ọmọ náà mọ bi à ti 'se n gbépọ̀ láti àsìkò yìí kìí ṣe ìgbà ti wọ́n bá dàgbà tan ni wan yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa gbìyànjú láti bárawọn ṣe. A ni ǹkan ti a fẹ́ kọ́ lọ́dọ̀ ara wa. "Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ọmọ mi Janet ni orúkọ rẹ̀, emi funra mi a ma bá pé ó sì má n wá sí ilé wa" bí ó ṣe yẹ kí o rí níyẹ̀n. Ó wá sàlàyé pé, tí àwọn kristẹni bá le gba àwọn ilé ìwé yìí padà lọ́wọ́ ìjọba, ìgbà yẹ ni yóò se gbọ́ nítorí wọ́n le gbé òfin kalẹ̀. Sùgbọ́n títí dí àsìkò yìí, àti ìjọba apapọ àti tí ìpínlẹ̀ kò sí ẹni tó dáhun láti dá ilé ìwé padà fún wọ́n. IEDPU jẹ́ ẹgbẹ́ ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbàsókè , ibásepọ àti ìrẹ́pọ̀ ọmọ bíbí ìlú Ilorin to wà ni ìjọba ìbílẹ̀ márùn ní ìpínlẹ̀ Kwara. Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni ipinlẹ Kwara ti fesi si bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan se pejọ si ileewe ti ijọba Kwara sọ pe ko wa ni titi pa nitori wahala wiwọ Hijab. CAN sọ pe ko si ohun to buru ti ẹnikẹni ba fi ẹhonu han lori lilo Hijab paapa lawọn ileewe Kristẹni nitori ofin faye gba iwọde. Ẹgbẹ naa sọ pe lopin igba ti ko ba ti mu ija wa ko saburu nibẹ. Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa to ba BBC Yoruba sọrọ lo fidi ọrọ yi mulẹ. Aposteeli Sina Ibiyemi to jẹ oludari eto ofin f'ẹgbẹ CAN Kwara ṣalaye pe awọn ko ni ki eeyan kankan ma ṣẹsin tirẹ. O ni awọn ko ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni fa ọrọ yi ati pe nkan meji pere lawọn fẹ. Akọkọ, ki ijọba Kwara da ileewe ti wọn gba lọwọ awọn pada ki awọn eeyan si maa lo Hijab nileewe awọn. ''Awọn eeyan kan lo fẹ funkun mọ Gomina ki wọn fi le fofin lilo Hijab lawọn ileewe rinlẹ mọ wa lori.'' O tẹsiwaju pe bi ijọba ti ṣe ti awọn ileewe yi pa, alaafia ni wọn wa ṣugbọn ki wọn ṣe ohun to ba tọ ki alaafia le jọba. Ibiyemi tẹsiwaju pe olu ilu ipinlẹ Kwara kii ṣe ti ẹnikan nitori naa ko yẹ ki awọn kan maa jẹ gaba lori awọn araalu to ku. ''Ijọba ni lati sayẹwo ẹtọ gbogbo eeyan nipinlẹ yi, ẹnikẹni to ba fẹ ki awọn ọmọ wọn lo Hijab nileewe, ki wọn gbe wọn lọ si Mọdirasa tabi awọn ileewe ti musulumi ba da ni'' Akọroyin BBC to kaakiri awọn ileewe ti ijọba tipa jabọ pe titi pa lawọn ileewe naa wa. Yatọ si ni ileewe Baptist Secondary School ti awọn kan ti dana sun taya, pupọ awọn ileewe yi ni o wa ni titi pa ti ko si si wahala kankan. Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe awọn ileẹkọ ti wọn gbe ti pa nitori wahala lilo Hijab yoo ṣi wa bẹẹ nitori aabo. Ileeṣẹ eto ẹkọ ipinlẹ naa lo fi atẹjade sita lọjọ Aiku. Ninu atẹjade ọhun ti arabinrin Kemi Adeosun to jẹ akọwe agba buwọlu, wọn ni awọn gbe igbesẹ naa nitori aabo. Lọjọ Aje tii ṣe ọjọ Kẹjọ oṣu Kẹta lo yẹ ki wọn ṣi awọn ileewe girama mẹwaa yi pada. Wahala ọrọ Hijab yi ti n rugbo bọ o to ọjọ mẹta ki ijọba to wa kede pe ki wọn ti awọn ileewe mẹwaa kan ti awọn Kristẹni sọ pe awọn lawọn n ṣe akoso wọn. Lọjọ kọkandilogun Osu keji ni wọn gbe aṣẹ yi jade nitori iwọde tawọn akẹkọọ ati ẹgbẹ musulumi kan ṣe pe awọn alakoso ileewe naa ko jẹ ki awọn ọmọbinrin lo Hijab. Awọn ileewe ti wọn ti pa naa wa bẹẹ ti ijọba si gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣagbeyẹwo ọrọ naa. Ababọ igbimọ naa ni pe ijọba paṣẹ pe awọn ọmọ musulumi lẹtọ lati lo Hijab ni eyikeyi ileewe nipinlẹ naa. Ọrọ yi ko dun mọ ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi CAN ti wọn si leri pe awọn ko ni gba ki awọn ọmọ musulumi wọ Hijab nile ẹkọ wọn. Kaakiri loju opo Whatsapp ati loju opo ayelujara awọn ikọ mejeeji, musulumi ati Kristẹni ti n leri leka pe awọn ko ni gba. Pẹlu ohun ti ijọba wa ṣe yi, o daju pe wọn ko fẹ ki wahala bẹ silẹ nigba ti wọn ba ṣi awọn ileewe yi pada ni wọn fi ni ki wọn ṣi wa ni titi pa.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56317499
yor
religion
Imam Fuad Adeyemi: Mọ̀wádà - Ìfẹ́ òtítọ́ gbudọ̀ wà nínú ìgbéyàwó
Ọ̀rọ̀ lori iwa ipá ninu ididle lo gbe BBC wa agba ọ̀jẹ̀ Imaamu lọ́ pe kini Kurani sọ nipa rẹ̀? Ìwà ipá nínú ilé ti rìn jìnà gẹ́gẹ́ bíi kòkòrò ajẹnirun tó ti ń tú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé ká. Ṣùgbọ́n àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn sọ pé ohun àá ṣeé ṣì kù. O ni igbesẹ ti lọkọlaya yẹ ki wọn gbe ninu Islam tile ba fẹ maa daru. Imam Fuad Adeyemi ti Mosalasi nla rẹ̀ wa ni Abuja to je olu ilu Naijiria salaye kikun lori koko yii Imam Fuad Adeyemi ti mọṣalaṣi Al-Islabiyah sọrọ ni kikun lori ohun ti Islam faaye gba fun alaafia lati jọba ninu ile.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-45518445
yor
religion
Àwọn olùfẹ́hónúhàn dáná sun ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́ta àti mọ́ṣáláṣí ní Ethiopia
Awọn eeyan kan ti dana sun ọpọ ṣọọṣi ati mọṣalaṣi ni iha ariwa ati gusu Ethiopia. Wahala naa bẹrẹ lẹyin ti awọn kan ti kọkọ ṣekupa ogun Musulumi, nigba ti ogunlọgọ awọn mii si farapa nibi eto isinku kan niluu Gondar, to wa lagbegbe Amhara. Agbẹnusọ awọn Musulumi lorilẹ-ede naa sọ fun BBC pe mọṣalaṣi mẹrin ni wọn dana sun. Bẹẹ naa ni agbẹnusọ fun awọn ọmọlẹyin Kristi ṣalaye fun BBC pe wọn dana sun ṣọọṣi mẹta ni iha gusu orilẹ-ede naa. Iroyin ni o ṣeeṣe ki iṣẹlẹ naa jẹ ẹsan fun awọn ogun Musulumi ti wọn ti kọkọ pa ṣaaju nibi eto isiniku to waye ni Amhara. Ijọba orilẹ-ede naa ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọọdunrun ati aadọrin eeyan ti wọn funra si pe wọn lọwọ ninu rogbodiyan ọhun. Wọn ni awọn ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iṣẹlẹ naa, nitori naa awọn yoo fi imu ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n fa wahala lawọn ilu mi danrin. Ẹwẹ, awọn Musulumi ni olu ilu orilẹ-ede naa, Addis Ababa ti n mura lati korajọ lọna ati fẹhonuhan lori ifẹmiṣofo naa. Nnkan bii ida mẹrinlogoji ni awọn Musulumi to n gbe ni Ethiopia.
https://www.bbc.com/yoruba/media-61282072
yor
religion
Samuel Ajayi Crowther: Baba nlá Herbert Macaulay, tó túmọ̀ Bíbélì sí Yorùbá
àlùfáà tó túmọ̀ Bíbélì sí Yorùbá , tó tún jẹ́ baba nlá Herbert Macaulay Kii se igba akọkọ ree ti a gbọ orukọ Bisọọbu Samuel Ajayi Crowther nilẹ Yoruba ati ni orilẹ-ede wa Naijiria lapapọ. Odu ni, kii se aimọ fun oloko paapaa ninu itan ẹsin awọn ọmọlẹyin Kristi ni orilẹ-ede Naijiria ati iwa imunilẹru jake-jado agbaye. Ogbontagi ọmọ Oodua to gbe ogo ilẹ Adulawọ ga ni, ko si yẹ ka ma mọ itan igbesi aye rẹ, ati ọgbọn ta lee ri kọ ninu rẹ. Gẹgẹ bi a ti se akojọpọ itan igbe aye Samuel Ajayi Crowther lori itakun agbaye, ololufẹ oniruuru ede ni, to si kọ ẹkọ nipa ede to to mẹrin. Awọn ohun to yẹ ko mọ nipa Samuel Ajayi Crowther: Wòlíì Kasali ní Dolapo Awosika kò lé ìyàwó òun jáde 'Alífábẹ́ẹ́tì Ohùn Oduduwa di ìtẹ́wọ́gbà ni Ajaṣẹ' Ṣẹ gbọ́ nípa Alájọ Ṣómólú, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́? Yorùbá dùn lédè, ẹ máa sọọ́ O yẹ ki gbogbo wa ri ọgbọn kọ ninu itan igbe aye akọni ọmọ Oodua yii, ẹni to jẹ ẹru, amọ to ta ara rẹ yọ. Ipokipo ti a ba wa, o yẹ ka maa ri daju pe a sa ipa wa, lati fi ọgbọn ori wa han, ka si se iwọn ti a lee se.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-47135688
yor
religion
Coronavirus: Ìjọ kò ní tilẹ̀kùn ilé ìjọsìn nítorí Coronavirus - Ondo PFN
Alaga ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ti ijọ igbalode PFN ni ipinlẹ Ondo, Joshua Kolawole Opayinka ti sọ pe, ijọ ko ni gbe kọkọrọ sẹnu ile ijọsin nitori arun Coronavirus. Biṣọbu ọhun sọ fun BBC Yoruba pe adura nikan ṣoṣo lo le dẹkun arun Coronavirus, kiiṣe titi ile ijọsin pa. O ni "A ko le sọ pe ka ti ile ijọsin nitori Coronavirus, nitori ori bibẹ kọ ni ogun ori fifọ." Opayinka sọ pe Ọlọrun mọ si gbogbo ohun to n ṣelẹ patapata, ati pe Ọlọrun nikan lo le yanju gbogbgo iṣorọ ati aisan to ba n ba aye finra lọwọ yii. Aṣoju PFN naa sọ pe ohun to yẹ ki awọn ọmọlẹyin Kristi ṣe ni pe ki wọn gbohun adura soke ju ti atẹyinwa lọ. Alufa naa tẹsiwaju pe Ọlọrun lo le aisan Ebola lọ, nitori naa Ọlọrun nikan naa lo le ṣegu arun Coronavirus. Nipa pe ọna ti ajakalẹ arun fi n tan kalẹ ni kikorajọ ọpọ eeyan, o ni ẹmi eṣu ko le raye laarin awọn ọmọ Ọlọrun. Opayinka sọ pe "Ẹmi eṣu to n kaakiri ninu afẹfẹ ni Coronavirus, ti ẹni to ba ni arun ọhun ba ti n wọle sinu ile ijọsin, ẹmi naa ko ni ba wọle. "Ti eeyan ba wọle sinu ile ijọsin pẹlu ẹmi naa, ẹmi naa ko ba iru ẹni bẹ jade, bẹẹni ko ni ko arun naa ran elomiran." Nigba to n sọrọ lori pe ti ijọba ba paṣẹ pe ki wọn ti awọn ile ijọsin, Opayinka sọ pe ijọ yoo tẹlẹ aṣẹ ti ijọba ba pa lori arun naa. Opayinka rọ ijọba ni ipari ọrọ rẹ pe, ko ma gbe agadagodo ṣenu ọna ile ijọsin latari arun Coronavirus nitori ijọ nikan ṣoṣo ni ọna abayọ si araun naa to n tan kaakiri agabaye.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51949985
yor
religion
Dare Adeboye burial: Pásítọ̀ Adeboye bẹ̀bẹ̀ fún àdúrà fún ìdílé rẹ̀ àti ẹbí olóògbé Dare Adeboye
Oludari ijọ Redeem(RCCG), Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti bẹbẹ adura fun idile rẹ nigba to n sọrọ nibi eto isinku ọmọkunrin rẹ, Pasitọ Dare Adeboye to d'oloogbe. Baba Adeboye sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan nibi eto isinku naa to wa ni ọgba ''Redeem camp'' to wa ni opopona ilu Eko si Ibadan. Alufaa Adeboye sọ pe ikku ko mọ ọmọde, bẹẹ ni ko mọ agba nitori bi ọmọde ṣe n ku naa ni awọn agbalagba n ku. ''Iku ko niiṣe pẹlu ọjọ ori eeyan, ṣugbọn ẹ dẹkun lati maa gbadura fun mi. Ẹ maa gbadura fun iyawo mi, ẹ maa ranti aya oloogbe atawọn ọmọ rẹ naa ninu adura yin. Eleyii to ju gbogbo rẹ lọ ni pe e maa gbadura fun ara yin ki ẹyin naa le pari irinajo yin laye yii daradara,'' Pasitọ Adeboye lo sọ bẹẹ. Baba Adeboye ṣalaye pe ko si ọna ti aye yii fi le da bi ọrun laelae. ''Mo mọ ohun ti mo n sọ nipa rẹ tori pe mo rii fun ra mi. Ti ẹ ba ri mi ti mo n ṣiṣẹ takuntakun fun Oluwa, nitori mo mọ pe ere mi n duro de mi lọrun ni. Mo rọ yin wi pe ki ẹ tẹsiwaju ninu ereeje igbagbọ. Ohun ti mo mọ nipe iyanu nla ti iru rẹ ti aye ko tii ri ri yoo ṣẹlẹ ninu aye yin laipẹ,'' Pasitọ Adeboye lo sọ bẹẹ. Baba Adeboye tun sọ pe oun yoo tubọ tẹra mọ ọrọ awọn ọdọ ninu ijọ RCCG ju ti atẹyinwa lọ. Àwọn àwòrán láti ibi ètò ìsìnkú olóògbé Dare Adeboye ni Redemption Camp Eto isinku oloogbe Dare Adeboye, to jẹ ọmọ kẹta to tun duro fun ọmọkunrin keji adari ijọ Redeemed Christian Church of God, RCCG, Pasito Enoch Adejare Adeboye ti bẹrẹ. Gbogbo ẹbi, ara ọrẹ ati ojulumọ ni ireti wa pe wọn yoo peju pesẹ sibi isin naa loni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu karun un, ọdun 2021. Pẹlu Hashtag #PDee ati #NotTodaySatan, I'm not leaving God, ni wọn n lo lati fi aworan wọn sita pẹlu bi wọn fa irun wọn lori ayelujara. Lana ni wọn ti kọkọ ṣe isin idagbere ni ile ijosin House of Favour ni Redemption Camp ni Mowe ni ipinlẹ Ogun. Eyi si waye leyin isin iyẹ oloogbe si to kọkọ waye ni ọjọ Aiku nil ipinlẹ Akwa Ibom ti oloogbe ti ṣiṣẹ iranṣẹ gbẹyin ki ọlọjọ to de. Ọjọ Isẹgun ọjọ Kọkanla osu Karun ọdun 2021: Isin idagbere yoo waye ni aago mẹwa owurọ ni ibudo awọn ọdọ, Youth Centre, to wa ni Redemption Camp ni Mowe, nipinlẹ Ogun. Lẹyin naa ni wọn yoo sin oloogbe Dare Adeboye si ibẹ. Lẹyin isin fun oloogbe ni RCCG House of Favour ni Redemption Camp ni Mowe ni ipinlẹ Ogun laarọ oni ni wọn yoo gbe ara oloogbe Oluwadamilare Temitayo Adeboye lọ si itẹ̀ oku ni Redemption Camp. Nibẹ ni wọn yoo ti fi eruku fun eruku ati iyẹpẹ fun iyẹpẹ ti wọn yoo si fi ara naa silẹ lọ. Iyawo kan, Temiloluwa ati ọmọ mẹta, Oluwatise, IreOluwa, ati Araoluwa lo gbẹyin oloogbe naa yatọ si Obi, ẹgbọn, aburo, ara ati ọrẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57067581
yor
religion
Attempted Murder: Ọwọ́ sìkún àjọ ọlọ́pàá ba Wòlíì Akute, Pasitọ Ayodele Omope tó yìnbọn lu ẹní tó sá wọ ilé ìjọsìn rẹ̀
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti kede pe awọn ti mu wolii ile ijọsin kan fẹsun pe o gbiyanju lati pa eniyan ati pe o ni nkan ija oloro lọwọ lọna aitọ. Wolii ile ijọsin Cele kan to wa ni orita Olambe, Akute ni ipinlẹ Ogun la gbọ pe o dabọn bo arabinrin kan lẹsẹ lasiko to sa asala wọ ile ijọsin rẹ. Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun DSP Abimbola Oyeyemi ti ṣe sọ,awọn mu Pasitọ Ayodele Omope lẹyin ti eeyan kan pe awọn nipe pajawiri. Ki lo fa ati wolii yinbọn mọ alaiṣẹ? Ohun taa ri ka ninu atẹjade ọlọpaa ni pe arakunrin to kesi awọn lori ago, Deji Olaketan jẹ alabaṣiṣẹpọ pẹlu arabinrin ti Pasitọ naa yinbọn lu lẹsẹ. Olaketan sọ fun awọn ọlọpaa pe oun ati arabinrin Kemi Johnson n dari pada sile lẹyin tawọn lọ ja ọga wọn si papakọ ofurufu nibi to ti wọ baalu lọ si irinajo. O ni bawọn ṣe n pada bọ lẹyin ti awọn gbe ọkọ lọ si ile mọlẹbi ọga wọn awọn gbọ pe awọn oloro wa ni agbegbe Olambe. Nitori pe ilẹ ti ṣu ,Deji sọ pe awọn sa asala wọ ile ijọsin Cele kan ti wọn ti nṣe aisun isọji.Ẹnu ọna lo s pe awọn duro si ti wahala fi bẹ silẹ. Gẹgẹ bi o ṣe sọ,afurasi wolii ti ọlọpaa mu yi ṣadede jade to si yinbọn lu arabinrin Kemi Johnson lẹsẹ. Awọn ọlọpaa ẹka Ajuwon lo sare wa sibi iṣẹl naa lẹyin ipe lati ọdọ Deji. Wọn mu wolii ti wọn si gba ibọn ati ọta ibọn marun un ti ko ti yin lọwọ rẹ. Lọwọlọwọ, arabinrin Kemi n gba itọju nile iwosan Igbobi to wa nilu Eko.Ṣaaju wn ti gbe lọ si ile iwosan nla Ijaye ati ile iwosan fasiti ilu Eko. Ẹwẹ Kọmisana ọlọpaa Lanre Bankole ti ni ki wọn gbe afurasi yi lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ki iwadii si tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yi.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60543386
yor
religion
Àpẹrẹ ìrẹ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan mùsùlùmí àti Krìstẹ́nì là fí hàn ní Ijomu Oro-Venerable tó ṣadura sí ọkọ̀ Ìmáàmù
Aworan to ṣafihan awọn ẹlẹsin meji to jijọ duro sara ọkọ ni awn ọmọ Naijiria n sọrọ lori rẹ loju opo ayelujara. Ṣugbọn kii ṣe gbogbo eeyan naa lo mọ pato nkan to waye ti Venerable ijọ Kristẹni kan ati Imaamu ilu Ijọmu Oro ni ipinlẹ Kwara ti ṣe n dọwẹkẹ lori ọkọ ti Imaamu ra. BBC Yoruba tẹsiwajulati t pinpin nkan tiowaye nibẹ la si ti ri aridaju pe lootọ ni Imaamu gbe ọkọ tuintun to ṣẹṣẹ ra lọ sọdọ alagba ijọ Kristẹni pe ko ṣadura si. Iṣẹlẹ yi ti mu ki ọpọ ọmọ Naijiria maa kan saara si awọn mejeeji pe iru awokọṣe to yẹ re lasiko yi ti ija ẹlẹsinmẹsin ati ẹlẹyamẹya gbode ni Naijiria Orukọ Venerable ti ọrọ yi kan ni Ebenezer Oyeleye Oyedalu ti wọn si jẹ oludari ijọ Christ Anglican Church,ni Ijọmu Oro . Gẹgẹ bi alaye ti o ṣe fun BBC Yoruba o loun kii ṣe ọmọ Ilu Ijomu Oro ṣugbọn lati igba ti iṣẹ Ọlorun ti dari rẹ wa si ilu naa ni irẹpọ ti wa laarin oun ati Imaamu ilu naa. ''Laarọ ọjọ Isinmi to kọja ni nkan bi ago mẹjọ ni mo kọja lẹgbẹ mọsalasi. O jẹ igab akọkọ ti emi ati Imaamu yoo ri ara wa lẹyin ti wọn ti ṣe ọdun tan. O beere pe akoko wo laa pari ijọsin mo si ṣalaye fun. Amọ o ni nkan bi ago mẹwaa loun le wa yọju si mi. Mo ni ko buru'' ''Sadede ni a n ṣe ijọsin lọwọ ni nkan bi ago mẹwaa owuro to si gbe ọkọ wa bawa ni ile ijọsin.Nigba ti mo jade si , o ni oun ṣẹṣẹ ra ọkan naa ni oun si fẹ ki n gbaura si.Inu mi dun, mo si gbaura pe ẹmi rẹ ni yoo lo ọkọ naa.'' ''Ibẹ la wa tawọn ọdọ ijọ ti jade ti wọn si ya aworan .Mi o mọ pe awọn eeyan tiẹ ti ri aworan naa loju ayelujara.'' Orukọ Imaamu ti o wa ninu aworan taa n wi yi ni Imaam Ibrahim Bashir Adewara oun si ni Imaamu agba ilu Ijomu Oro. Ninu alaye ree, o ni ohun ti oun ṣe nipa fifi ọkọ naa han Venerable pe ko ṣe adura si kii ṣe nkan to jẹ tuntun nitori awọn ko ṣẹṣẹ maa ba ara wọn ṣe. ''Ki n to ra ọkọ naa ni Venerable ati awọn olori ẹlẹsin mii to jẹ musulumi ati Kristẹni ti n fi adura ran mi lọwọ pe ki Ọlọrun pese ọkọ fun mi.'' ''Nigba ti mo si ti wa ra ọkọ naa tan, ṣe ko yẹ ki gbogbo wọn ṣadura si ni?'' Imam Adewara sọ pe ibaṣepọ alaafria lo wa laarin awọn ẹlẹsin gbogbo ni Ilu Ijomu Oro ati pe bẹẹ lawọn ṣ n ṣe ni gbogbo Oke Mesan Oro patapata. O fi kun ọrọ rẹ pe ohun ti ẹsin kọ oun ni pe ki oun ṣe daada si alabagbe oun ko si si iyasotọ laarin Kristẹni ati musulumi ninu alabagbepọ. Lafikun ọrọ rẹ, o ni eleyi to dara ju ni pe ki awọn olori ẹlẹsin fi apẹrẹ daada lelẹ fun awọn to n tẹle wọn ati pe ''awọn oloṣelu lo de ti wọn mu iyapa wa laarin gbogbo wa. Ninu ilu wa,musulumi ati Kristẹni ọkan naa ni gbogbo wa.''
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ckd71ejqjqvo
yor
religion
TB Joshua: Ọba Arigidi ní àwọn kò ní ró òkú wòlíì náà torí ó tí sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ ikú rẹ̀ sẹ́yìn
Kabiyesi ilu Arigidi Akoko, to jẹ ilu abinibi oloogbe Temitọpẹ Joshua ti sọ pe ifẹ gbogbo ọmọ ilu naa ni pe ki wọn o sin oku gbajugbaja wolii naa sibẹ. Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Zaki ilu Arikidi, Ọba Yisa Olanipekun sọ pe awọn iranṣẹ Ọlọrun nla bi Mose Orimọlade, Ayọdele Babalọla, Samson Ọbadare, ni wọn sin si ilu abinibi wọn. O ni lootọ awọn ko ti i ba iyawo oloogbe sọrọ, ṣugbọn dandan ni ki wọn o gbe wa sile. Lori iroyin to n lọ ni ori ayelujara pe awọn ara ilu Arigidi fẹ ẹ wa idi iku to pa Joshua, Ọba sọ pe ko si nkan to jọ iwadii kankan. O ni "ko si idi ti ẹnikẹni fi fẹ ẹ pa, a gba pe o ti pari iṣẹ ti Ọlọrun ran wa si aye lati ṣe ni, paapaa ninu ọrọ to sọ ni ọjọ diẹ sẹyin. "Ṣugbọn nkan ti a n sọ ni ẹ ba wa gbe oku ẹ wa si Arigidi fun isinku." O ni ilu naa yoo di ibi ti gbogbo agbaye yoo ma a wa, lati wa gbadura nibi iboji rẹ, ti wn ba sin sibẹ. O ni lootọ ni iyawo rẹ kii ṣe ọmọ Arigidi, bẹẹ ni awọn ọmọ rẹ ko de ilu Arigidi ri. "Ti wọn ko ba fi sin si ile, ko si bi awọn ọmọ tabi iyawo rẹ yoo ṣe de ilu wa mọ. "Oun (Joshua) kọ lo ni ara rẹ mọ, awa la ni ọmọ wa. Ọmọ ologo wa ni, ko si gbọdọ sun sita." Kabiesi sọ pe nkan ti gbogbo ọmọ ilu fẹ ni oun sọ, ti oun ko si ni i fẹ ki ọrọ ibi ti wọn yoo sin oloogbe si da wahala silẹ. Abẹwo si ilu Arigidi, ipinlẹ Ondo, to jẹ ilu abinibi oloogbe Woli T. B Joshua fihan pe, ẹni to dara nita, dara nile ni. Ọkan lara awọn agbaagba ni agboole rẹ to ba BBC Yoruba sọrọ, Solomon Olotu, sọ pe awọn mọ iku rẹ lara pupọ. "A ko ti mọ ẹni ti ọlọrun yoo fi rọpo fun wa, nitori pe oun ni imọlẹ ilu yii. T.B Joshua ti ma n sọ tẹlẹ pe oun yoo ku, oun ni imọlẹ ilu yii, ibanujẹ lo jẹ fun wa pe o papa ku. Nigba to n tọka si awọn nkan to ṣe fun ilu Arigidi, Olotu naa sọ pe Joshua lo ra ẹrọ amunawa transformer fun ilu naa, to si tun ma n ko ounjẹ fun awọn arugbo ati alaini loore-koore. Ẹlomiran to tun sọrọ, ọgbẹni Isaac Olumọfẹ sọ pe, oun ati Joshua jọ gbe papọ ni ilu Eko ni, ko to o dipe aisan da oun pada si ilu Arigidi. O ni owo ti Joshua fun oun lo da oun pada si aye. Bakan naa ni Oloye mii sọ pe Joshua lo mu ki ọpọlọpọ ọmọ ilu Arigidi da baalu mọ, nitori pe o ti gbe ẹlikọpita wa si ilu ri, to si gbe si ibi ti gbogbo ara ilu ti ni anfaani lati wọ inu rẹ fun igba akọkọ. Ọba alade ilu naa, Zaki ti Arigidi, Ọba Yisa Olanipekun sọ pe ilu abinibi rẹ ni awọn fẹ ki wọn o wa sin oku rẹ si. Ọkan lara awọn ẹbi oloogbe to ba BBC sọrọ, Arabinrin Bọsẹ Balogun sọ pe, iku rẹ dun oun pupọ, ki Ọlọrun si gba a si afẹfẹ rere. "Baba mi lo jẹ, bo tilẹ jẹ pe aburo lo jẹ fun mi. Amọ o dun mi pe iku mu u lọ ni ọsan gangan."
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57384382
yor
religion
Emmanuel Folorunso Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina jáde láyé lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀
Pasitọ Elijah Abina, to jẹ adari ijọ Gospel Faith Mission International, GOFAMINT, ti padanu ọmọ rẹ ọkunrin, Emmanuel Folorunso. Iroyin iku ọmọ Pasitọ Abina jade lẹyin ọjọ diẹ ti ọmọkunrin Pasitọ agba ijọ Redeem, Enoch Adeboye naa jade laye. Iroyin sọ pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ni Emmanuel Abina ku nilu Eko. Eyi to jẹ ọjọ kẹjọ ṣaaju iku ọmọ Adeboye. Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ pato nkan to pa Emmanuel, iroyin sọ pe aisan ọlọjọ diẹ lo pa a. Ṣaaju iku rẹ, oun ni pasitọ ẹka ijọ GOFAMINT, Kingdom House Assembly to wa ni Festac Town nilu Eko. Bakan naa lo tun jẹ oludari ẹka igbohunsafẹfẹ ijọ naa. Ninu atẹjade kan ti Akọwe Agba fun ijọ GOFAMINT , Pasitọ S.O Omowumi fi sita ni ọjọ keji, oṣu Karun-un, lo ti kọkọ kede iku naa. O ni "pẹlu ẹdun ọkan, ṣugbọn ni itẹriba fun aṣẹ Ọlọrun Olodumare, ni a kede iku arakunrin wa, pasitọ wa, ati ọkan lara ọmọ igbimọ oludari ijọ... Pasitọ Emmanuel Abina, to ku l'Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2021. O ni awọn yin Ọlọrun, fun igbeaye oloogbe ati ipa to ni ninu ijọ, paapaa laarin awọn ọdọ. "Ki Jesu Kristi, Oluwa wa, ko tu Oludari wa, idile, ati ẹbi, to fi mọ ijọ ninu."
https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-57047149
yor
religion
Imam ìjọ Shafaudeen in Islam, Sabit Olagoke gbàdúrà pé kò sí olólùfẹ́ BBC Yorùbá tó máa ṣìrìn lọ́dùn 2023
Ko si ẹni ti ko ni lu aluyọ lọla Eledua ni 2023 yii. Bi ọdun 2023 ṣe ti wọle de wẹrẹ yii, BBC Yoruba kan si Imam agba ninu ijọ Mosalasi Shafaudeen In Islam lati sadura ọdun fun gbogbo ololufẹ BBC Yoruba pẹlu ilana musulumi. Imam Sabiat Olagoke ni pe ayọ lo ku lọdun 2023. Ati pe Allahurabi yoo fun ijọba Naijiria lọgbọn ati agbara lati ṣe ẹtọ to yẹ fun awọn oṣiṣẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/64143321
yor
religion
Àtìmọ́lé ni Pásítọ̀ 'Ondo Church' tó kó àwọn ọmọ ìjọ pamọ́ sí àjà ilẹ̀ yóò ti ṣe ọdún iléyá
Ile ẹ̀jọ Majisireeti to n gbọ ẹjọ pasitọ ijọ The Whole Bible Church nilu Ondo, Pasitọ David Anifowoṣe, igbakeji rẹ Josiah Peter atawọn mẹta miran ti wọn fi ẹsun kan pe wọn fi tipa ko awọn eeyan kan pamọ sinu ile ijọsin wọn tun tẹsiwaju igbẹjọ lọjọ Ẹti. Ile ẹjọ naa sun igbẹjọ rẹ siwaju di ọjọ kejidinlogun oṣu keje ọdun 2022. Onidajọ Majisireeti Rashidat Yakubu to gbọ ẹjọ naa ṣalaye pe oun sun un siwaju lati lee fun ile ẹjọ naa laaye ati farabalẹ yẹ ẹbẹ fun beeli awọn olujẹjọ naa ti agbẹjọro wọn gbe ka iwaju ile ẹjọ naa wo. Nigba ti igbẹjọ naa bẹrẹ lọjọ Ẹti, agbẹjọro fun olupẹjọ, Leo Ologun rọ ile ẹjọ lati wọgile abala ikarun un ati ikẹfa ẹbẹ naa, ki wọn si ri atimọle ti wọn fẹ fi awọn olujẹjọ naa si gẹgẹ bi ọna kan lati daabo bo wọn nitori inu ṣi n bi awọn eeeyan to wa lagbegbe ijọ wọn. Amọṣa agbẹjọro fun olujẹjọ, Ọladele Ayọọla tako eyi. O ni ohun to ṣini lọna patapata ni Olupẹjọ sọ. Pasitọ ile ijọsin Whole Bible Believers Church nilu Ondo ti wọn fi ẹsun kan pe wọn ri agidi ko awọn ọmọ ijọ pamọ si ajalẹ ni wọn foju ba ile ijọ loni. Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ondo lo pẹjọ tako alufaa ijọ The Whole Bible Church ti ọpọ mọ si "Ondo Church" Pasitọ David Anifowoṣe ati awọn mẹrin miran niwaju ile ẹjọ majisireeti kan nilu Akurẹ. Ẹsun ifipa gbenipamọ ni wọn fi n kan awọn afurasi naa. Kọmiṣọna feto idajọ nipinlẹ Ondo to tun jẹ agbẹjọro agba fun ijọba ipinlẹ naa, Amofin Charles Titiloye lo lewaju ikọ olupẹjọ nigba ti Amofin Oladele Ayoola si jẹ agbẹjọro fun awọn olujẹjọ. Awọn ọlọpaa ya bo ile ijọsin kan ti orukọ rẹ n jẹ The Whole Bible Church lagbegbe Valentino nilu Ondo lọjọ Ẹti lẹyin ti arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Elizabeth Rueben pariwo sita pe awọn adari ijọ kan ti ọmọ oun nlọ ti gbe e pamọ si ahamọ wọn ko si fẹ ko ṣe idanwo aṣekagba girama WAEC. Arabinrin naa ni ohun ti wọn n sọ fun ọmọ oun ati ọpọlọpọ awọn ọmọ ijọ to wa nile ijọsin naa ni pe Jesu yoo de ni ọdun yii nitori naa ki wọn pa gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe ti nitori bi Ọlọrun ṣe fẹẹ niyi. Ni kete ti wọn mẹnuba ẹjọ ọun ni agbẹjoro fawọn olujẹjọ ti rawọ ẹbẹ si onidajọ Magistrate R.O. Yakubu ki o fun ohun laaye lati lọ yẹ iwe ẹsun ti wọn fi kan awọn onibara ohun wo finnifinni, leyi ti yoo gba ohun to ọjọ meji. Ẹwẹ Magistrate Yakubu ni o wipe aaye ọjọ meji ko le yọ nitoripe ọla ni ọjọ ẹti to jẹ ọjọ iṣẹ to kẹyin lọsẹ yi ati pe isinmi lẹnu iṣẹ le wa lọjọ aje ọsẹ to n bọ. O waa sun igbẹjọ si ọla ọjọ ẹti ọjọ kẹjọ oṣu keje ọdun yi lati fun agbẹjọro awọn olujẹjọ laaye lati le fesi si iwe ẹsun ti wọn fi kan awọn onibara rẹ. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo SP Olufunmilayọ Ọdunlami ṣalaye fun BBC News Yoruba nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹ pe Alufaa ijọ naa, Pasitọ Anifowoṣe ati Igbakeji rẹ, Josiah Peter Asumosa “sọ fun awọn ọmọ ijọ naa pe Jesu yoo pada de ni oṣu kẹrin ọdun 2022, ki o to tun yii pada lati sọ pe o ti di oṣu kẹsan an ọdun 2022, ti o si sọ fun awọn ọdọ inu ijọ naa lati maṣe gbọran si awọn obi wọn lẹnu mọ, ati pe awọn obi wọn ninu oluwa nikan ni ki wọn maa gbọ ọrọ si lẹnu.”
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cn35pem4l09o
yor
religion
Sotitobire: Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá olùkọ́ èwe ṣọ́ọ̀ṣì Sotitobire, Magaret Oyebola sílẹ̀
Ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Akurẹ ti wọgile idajọ ẹwọn gbere ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo gbe le arabinrin Magaret Oyebọla, olori awọn ṣọọsi ọmọde nile ijọsin Sotitobirẹ Praising Chapel nilu Akurẹ. Adajo Oluṣẹgun Oduṣọla ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo ran Oyebọla, Wolii Babatunde Alfa atawọn miran lọ si ẹwọn gbere fun ẹsun jiji ọmọdekunrin Gold Kọlawọle gbe ni ijọ naa losu kọkanla ọdun 2019. Ninu idajọ rẹ eyi ti onidajọ, James Gambo Abundaga sọ pe awijare ti ile ẹjọ giga gbe idajọ rẹ le lori ko fidi mulẹ to lati fihan pe wọn ji ọmọ naa gbe ni. Bakan naa lo ni igbẹjọ naa ti ṣe yajoyajo jubii ina alẹ niwọn igba ti iwadii ṣi n lọ lọwọ ti gbogbo rẹ si n fihan pe ẹri ti wọn n gbe kalẹ ko rinlẹ to, bẹẹsi ni ko si idi fun riran wọn lẹwọn laisi ẹri to daju. Agbẹjọro fun olupẹjọ naa, Ọladele Oke dupẹ lọwọ ile ẹjọ naa fun itusilẹ arabinrin Oyebọla, ṣugbọn adari ẹka ipenilẹjọ nijọba ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Leonard Ologun ṣalaye pe ijọba yoo gbe idajọ naa yẹwo lati gbe igbesẹ to ba kan. Oyebọla ni ẹnikeji ti yoo gba itusilẹ lara awọn olukọ ile ijọsin awọn ọmọdemarun un ni ṣọọṣi Sọtitobirẹ ti wọn ran lọ si ẹwọn gbere loṣu kẹwaa ọdun 2020. Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti kọkọ tu Motunrayọ Egunjọbi silẹ ninu idajọ rẹ ni ọjọ kini oṣu kejila ọdun 2021. Loni ni idajọ olukọ agba ileejọsin awọn ọmọde ni ṣọọsi Sọtitobirẹ yoo waye. Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni ọdun 2020 ni ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Ondo da ẹjọ ẹwọn gbere fun Oludasilẹ ijọ naa, Wolii Alfa Babatunde lori ọmọdekunrin, Gold Kọlawọle to sọnu ninu ijọ naa. ArabinrinMagareth Oyebọla ni adari ẹka awn ọmọde ni ileejọsin Sọtitobirẹ Praising Chapel nilu Akurẹ. O wa lara awọn ti wọn da ẹjọ ẹwọn gbere fun pẹlu adari ijọ naa. Oun pẹlu tọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ lati wọgile idajọ naa eleyi ti idaj yoo waye le lori loni.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59725136
yor
religion
Kwara Hijab Crisis: Kí ni ọ̀nà àbáyọ sí wàhálà ìgbà gbogbo lórí híjàbú wíwọ̀ láwọn iléẹ̀kọ́ Kwara?
Ọrọ Hijaabu wiwọ ni awọn ileẹkọ ijọba nipinlẹ Kwara tun ti n da wahala silẹ pada. Lọjọbọ, ija waye laarin awọn obi ati akẹkọọ kan ti wọn se iwọde lọ si ileẹkọ Girama Oyun Baptist Secondary School ni Ijagbo lori pe awọn alasẹ ile ẹkọ naa ko jẹ ki awọn ọmọ wọn to wọ Hijaabu wọ kilaasi. Ọrọ yi lo di wahala ti ikọlu si waye laarin awọn ọdọ musulumi ati Kristẹni to doju ija kọ ara wọn. Ni bayi, ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe ki wọn ti ileẹkọ naa pa titi ti alaafiayoo fi pada sibẹ. Ijọba Kwara to gbẹnu Kọmisana feto ẹkọ Hajia Sa'adatu Modibo Kawu sọrọ sọ pe awọn bẹnu atẹ lu ikọlu to waye ni Ijagbo yi. Kini Komiṣọnna sọ lori iṣẹlẹ yii? Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọnna fi sita lỌjọbọ, ijọba sọ pe awọn lawọn ni ile ẹkọ Oyun Baptist Secondary School tori naa nkan to sẹlẹ yi awọn ko faramọ rara. "Ijọba Kwara fi tọkantọkan koro oju si idẹyẹsi ẹnikankan paap awọn ọmọde nitori ẹsin.A ko ni faramọ iwa yi ni eyikeyi ileesẹ ijọba eleyi ti o ba jẹ ti ijọba''. Kọmiṣọnna naa tẹsiwaju pe ''Pẹlu bi ijọba ati awọn ajọ rẹ se n jiroro pẹlu awọn olori ẹsin mejeeji, a ti wa pasẹ bayi pe ki wọn ti ile ẹkọ naa pa tti ti ọrọ yi yoo fi lojutu'' ''A rọ awọn agbofinro lati se iwadii lori ọrọ yi ki wọn si mu ẹnikẹni to ba lọwọ ninu isẹlẹ yi kawọn eeyan baa le kọgbọn lara rẹ.Ijọba n beere fun alaafia nitori wahala kii so eso rere''. Ki lawọn ọlọpaa sọ? Ileesẹ ọlọpaa fi ọrọ sita ninu atẹjade lati ọwọ agbẹnusọ wọn Ajayi Okasanmi pe awọn fẹ fi da araalu Kwara loju pe alaafia ti pada si agbegbe naa. O ni ''ikọ kogberegbe ati awọn ọlọpaa to wa nilẹ ni ijagbo ti da alaafia pada si agbegbe naa ti wọn si duro digbi la ti ri pe wahala kankan ko waye nibẹ'' Agbofinro se alaye pe ọrọ hijaabu lo da wahala silẹ laarin awọn musulumi ati Kristẹni ti o ti n waye ti pẹ nipinlẹ Kwara. ''Eleyi to kan wa ni ọrọ wahala to bẹ silẹ laarin awọn eeyan ijagbọ ati awọn obi musulumi ti wọn n se iwọde.Wọn pada wa doju ija kọ ara wọn pẹlu ohun ija oloro'' Igba akọkọ kọ ni yi ti iru nkan bayi n waye: Ni Naijiria,ọrọ wiwọ hijaabu yi ko sẹsẹ maa waye. Ni ipinlẹ Kwara ni paapa ilu Ilorin, ọrọ yi da wahala silẹ laipẹ eleyi to mu ki ijọba ti awọn ileẹkọ mẹwaa kan ti awọn Kristẹni n se akoso rẹ. Awọn oludari ile ẹkọ Kristẹni yi sọ pe awọn ko le gba ki wọn maa wọ hijaabu wa si ile ẹkọ awọn nitori o tako ilana ẹsin awọn. Nigba naa lọhun, Victor Dada to jẹ olori ijọ itẹbọmi sọ pe awọn kọdi awọn akẹkọọ yi lati wọ ile ẹkọ awọn nitori awọn ko faaye gba iru imura bayi Ni tawọn musulumi, wọn ni ile ẹkọ wọnyi kii se ti awọn Kristẹni bi kii se pe ijọba lo da wọn silẹ. Nigba ti awọn Kristieni sọ pe awọn lo da awọn ileẹkọ naa silẹ pẹlu owo awọn ọmọ ijọ ki ijọba to gba a lọwọ wọn nigba naa. Ọrọ naa di ranto ti ikọlu si waye laarin awọn musulumi ati Kristẹni ni ile ẹkọ Baptist to wa ni Surulere. Ijọba gbe igbesẹ pe ki wọn ti ile ẹkọ naa paa ti wọn si pada wa si lẹyin ti wọn ni ile ẹjọ giga ati kotẹmilọrun ti fun awọn ni akoso ile ẹkọ naa tipẹ. Alaafia pada sugbọn o da bi ẹni pe ikunsinu yi ko ti tan nilẹ. Ninu awọn ile ẹkọ ti ijọba lawọn gba pada lọwọ awọn Kristẹni la ti ri. Cherubim & Seraphim College Sabo Oke ST. Anthony College, Offa Road ECWA School, Oja Iya, Surulere Baptist Secondary School Bishop Smith Secondary School, Agba Dam. CAC Secondary School Asa Dam road. St. Barnabas Secondary School Sabo Oke. St. John School Maraba. St. Williams Secondary School Taiwo Isale, ati St. James Secondary School Maraba. Ni nkan bi ọsẹ to kọja ni wahala tuntun ti ile ẹkọ Baptist Oyun yi bẹrẹ si ni rugbo ko to wa di pe o di ranto. Ko si sẹyin bi awọn olukọ ti se da awọn akẹkọọ kan pada sile nitori pe wọn lo hijaabu wa si ileẹkọ. Ọrọ yi di nkan tawọn musulumi kan se fidio ti wọn si ya aworan awọn akẹkọọ yi soju opo ayelujra. Nitori ariwo lori ọrọ yi, ileesẹ eto ẹkọ Kwara kan si ile ẹkọ naa ti wọn si kilọ fawọn olukọ ati alasẹ ileẹkọ naa pe ki wọn maa se doju le akẹkọọ kankan lori wiwọ hijaabu tabi pọn dandan pe ki ọmọ wọ hijaabu tabi fila gẹgẹ bi imura. Lẹyin ikilọ yi lawọn obi akẹkọọ musulumi naa se iwọde lọ si ile ijọba Kwara pe awọn ile ẹkọ naa ko tẹle asẹ ijọba.
https://www.bbc.com/yoruba/agbaye-60256748
yor
religion
Dare Adeboye: Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní olóògbé yóò wọ káà ilẹ̀ ṣùn ní Redemption Camp
Idile Baba Enoch Adejare Adeboye to sẹsẹ padanu ọkan lara ọmọkunrin rẹ, Pasitọ Dare Adeboye, ti sọrọ sita fun igba akọkọ lẹyin isẹlẹ ibanujẹ naa. Atẹjade kan ti mọlẹbi naa fisita lọjọ Ẹti, eyi ti Pasitọ Leke Adeboye fọwọsi lo dupẹ lọwọ gbogbo eeyan fun ibanikẹdun wọn. Bakan naa lo tun salaye ilana bi iku oloogbe naa yoo se lọ. Leke Adeboye ni "Pẹlu ẹmi imoore la fi n mọ riri yin bẹ se duro ti ẹbi wa lasiko idanwo yii, amọ a tu ara wa ninu pe ọmọ wa ọwọn pada lọ sile ni lati lọ sinmi lọdọ baba ati ẹlẹda rẹ. Igboya wa lo fidi mulẹ ninu igbe aye ifiraẹnijin ati aimọ tara ẹni nikan ti ọmọ wa gbe ninu Jesu Kristi, Olugbala wa. Adura wa ni pe ki gbogbo wa dijọ pade nile ologo lorukọ Jesu." Bakan naa ni ẹbi Adeboye tun salaye ilana ti eto isinku oloogbe naa yoo gba waye. Bi eto isisnku Dare Adeboye yoo se lọ ree: Akanse isin yoo waye ninu ijọ Redeem, City of David Youth Church to wa ni Eket nipinlẹ Akwa Ibom nibi ti oloogbe naa ti jẹ ojisẹ Ọlọrun, to si ku si. Akanse isin orin idupẹ ati ọrọ imọyi nipa oloogbe yoo waye ni ijọ Redeem, House of Favour to wa ni Redemption Camp nilu Eko. Isin idagbere yoo waye ni aago mẹwa owurọ ni ibudo awọn ọdọ, Youth Centre, to wa ni Redemption Camp ni Mowe, nipinlẹ Ogun. Lẹyin naa ni wọn yoo sin oloogbe Dare Adeboye si ibẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57003877
yor
religion
Arafat Day: Wo ohun márùn-ún tí ayájọ́ òní fi lọ́lá jùlọ nínú Islam
Ọjọ Aje oni, tii se Ọjọ Kọkandinlogun osu Keje ọdun 2021 ni ọjọ Arafa fun ọdun yii. Ọjọ Arafa ni ọjọ kẹsan oṣu Zul-Hijjah, ni onka oṣù ojú ọrun. Ní ayajọ oni ni awọn Alhaji ati Alhaja tuntun máa ń kórajọ pọ sí oke Arafat tó wà ní ìlú Makkah lọdọdún. Láti ìgbà tí ìrun àílà bá ti to, titi di ìgbà tí òòrùn bá wọ, ni wọn yoo maa gun oke Arafa, láti ṣe ọkan lára àwọn koko iṣẹ hajj naa. BBC ṣe ifọrọwerọ pẹlú agba Alfa ẹsìn Islam kan ní Nàìjíríà, Ọmọwe Ibrahim Disina, lóríi àwọn nǹkan tó se pataki to yẹ kí àwọn èèyàn ṣe ni ọjọ Arafa. Ní irú ayajọ ọjọ yìí lasiko hajj ìdágbére láyé Anabi Muhmmad (S.A.W.), ni Ọlọrun parí sísọ àwọn òfin ẹsin Islam kalẹ. Láti ọjọ náà, kò sí ìdájọ kan tó sọkalẹ mọ, eléyìí gan ló fàá tí Sayyidina Umar fi sọ pé: "Nitori àjùlọ tó wà fún ọjọ yìí, tó bá jẹ àwọn Yahúdí ni, ki sọ ọjọ yìí di ọjọ tí wọn ó máa ṣe ayẹyẹ lọdọdún", Gẹgẹ bí Ọlọrun ṣe gba ẹmí Anabi Muhammad (S.A.W.) ní ọjọ kọọkanlelọgọrin lẹyìn ìgbà náà. Gbígba àdúrá nígbà tí èèyàn bá wà l'Árafat ni àdúrà tó lọlá jù lágbáyé. Gẹgẹ bí Annabi (S.A.W) se sọ pé "Àdúrà tó lọlá jù ni àdúrà tí wọn ṣe lọjọ Arafat" Ní ọjọ Arafat ni Ọlọrun máa n yọ àwọn eeyan kúrò nínú ọmọ iná jùlọ. Eléyìí wá nínú ẹgbàwá ọrọ Imam Muslim pé: Anabi (S.A.W) sọ pé: "Kò sí ijọ tí Ọlọrun máa ń yọ àwọn eeyan kúrò nínú ọmọ iná bíi ọjọ Arafa" Gbígba ààwẹ lọjọ Arafa máa ń pa ẹṣẹ oṣù méjì rẹ, gẹgẹ bí Anabi (S.A.W) ti sọ pé: "Àwẹ ọjọ rana Arafat máa ń pa àwọn ẹṣẹ ọdún tó kọja àti ti ọdún tó ń bọ." Muslim ló gba ọrọ yìí wá bákan náà. Ọlọrun máa fi àwọn Alhaji tó lọ sí Arafat yangàn Arafat ní ọjọ yìí. Imam Ahmad gba ẹgbàwá ọrọ wá pé: Anabi ni: "Ọlọrun máa ń fi àwọn tó lọ sí Arafa yangàn lójú àwọn tó wà lọrun. " Ọjọ Arafa bọ si Ọjọ Kẹsan ti awọn musulumi n pe ni Dhul-Hajjah, to jẹ ọjọ keji Hajj. Ọjọ nla ni Ọjọ yii jẹ ninu irinajo awọn musulumi lọ si ilu Mecca, ilẹ mimọ, to si jẹ ọkan ninu awọn ọjọ to se pataki si wọn. Ti oorun ba ti jade ni ọjọ yii, ni awọn musulumi ti wọn lo bi ilẹ mimọ yoo bẹrẹ irinajo lọ si Oke Arafa to wa ni Mecca.
https://www.bbc.com/yoruba/49307006
yor
religion
Pásítọ̀, ẹ pèsè ẹ̀rọ CCTV sílé ìjọsìn yín torí ìkọlù agbébọn - Oriade l‘Ogun
Oba Eselu ti ilu Iselu ni ipinlẹ Ogun ti fi iwe ranṣẹ si olori ẹgbẹ ọmọ lẹyin Kristi Naijiria,Rev Supo Ayokunle,lori ikọlu sawọn ọmọ lẹyin Kristi ni ile ijọsin St. Francis Catholic Church Owo nipinlẹ Ondo. Oba Akintunde Akinyemi ninu iwe naa da laba pe ki aarẹ ẹgbẹ yi kesi awọn ile ijọsin lati ṣamulo ẹrọ kamẹra CCTV lati le fi mọ awọn to ba n wọle tabi jade ninu ile ijọsin wọn ni gbogbo igba. Gẹgẹ bi oriade yi ti ṣe sọ, fidio lati inu ẹrọ CCTV yi yoo jẹ ranwọ fawọn olori ijọ lati le tete kesi awọn agbofinro ti wọn ba nilo iranwọ wọn. Oba y ni CAN tun gbọdọ pa laṣẹ lasẹ fawọn ile ijọsin lati ra awọn irinṣẹ aabo ki wọn si lo irufẹ irinṣẹ naa lati fofin si ipakupa awọn ọmọ ijọ ni ile ijọsin wọn. Kabiyesi to ba kan jẹ lori iṣẹlẹ ikọlu si ile ijọsin naa sọ pe iṣẹlẹ naa buru ''ti gbogbo eeyan si gbọdọ dide ni itako ikọlu si awọn ile ijọsin lati ọwọ awọn agbebọn ti wọn ko mọ'' Eselu tẹnumọ pe ki CAN ma sinmi lati bẹnu atẹ lu pipa ẹnikankan, yala musulumi tabi Kristẹni ni paapa labẹ awawi pe wọn sọrọ odi si ẹsin. O ni iru iwa yi jẹ́ iwa ẹranko ti wọn ko si gbọdọ ba lọwọ awọn eeyan lawujọ ode oni. O tun parọwa si gbogbo ọmọ Naijiria lati ''mu opin ba iwa ẹhanna yi lorileede Naijiria'' ''Ọlọla julọ, o da lootọ pe ki a gbadura,iwe mimọ sọbẹ ṣugbọn a ko tun gbọdọ sun asunpiye gẹgẹ bi iwe mimọ ṣe sọ fun wa''
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c6pl23g1993o
yor
religion
Catholic protest: Ìjọ Aguda ṣèwọ́de l'Abuja, ó ní àwáwí ìjọba ṣú òun lórí ààbò tó mẹ́hẹ
Yoruba ni agba ti ko ba kẹhun sọrọ, afaimọ ko ma kẹtan sare, idi ree ti awọn ọmọ ijọ Aguda fi tu jade kẹti-kẹti nilu Abuja lọjọ Aiku, lati ṣe iwọde tako awọn iṣẹlẹ iṣekupani to n waye ni Naijiria. Ẹgbẹ awọn biṣọpu ijọ naa to se agbatẹru iwọde ọhun sọ pe, ijọba ko ṣe to lati daabo bo ẹmi awọn araalu, ti awawi rẹ pe, oun ti sẹ eegun ẹyin ikọ asẹrubalu Boko Haram, si ti su awọn. Aṣọ dudu ni awọn to wọde naa wọ, eyi to tumọ si pe asiko ọfọ tabi ibanujẹ ni akoko naa jẹ fun wọn. Awọn alaṣẹ ijọ naa sọ pe, iwọde naa waye lati gbadura ati lati bẹbẹ fun alaafia ati aabo ni orilẹ-ede Naijiria. "Iwa ika gbaa ni ka pa eniyan, bẹẹ si ni kikuna lati daabo bo ẹmi alaisẹ lọwọ iku aitọjọ gan, iwa ika ni. Ọpọ isinku apapọ lo n waye ni Naijiria, ijinigbe awọn arinrinajo ati ọmọ wẹwẹ to fi mọ ikọlu awọn eeyan ninu ile wọn, sọọsi, mọsalasi ati ileẹkọ oniwaasu." Bẹẹ ba gbagbe, o ti to bi igba melo kan ti awọn ajinigbe ti ji awọn alufaa ijọ Aguda gbe, ti ijọ naa si sọ pe, awọn kan gba ominira lẹyin ti ijọ san owo. Ṣugbọn, awọn ajinigbe pa awọn kan. Oṣu Keji ni awọn ajinigbe tun pa ọkan lara awọn akẹkọọ Alufaa ijọ naa nipinlẹ Kaduna, Michael Nnadi, lẹyin ti wọn ti ji gbe fun igba diẹ. Ẹni ọdun mejidinlogun ni. Laipẹ yii naa ni ijọ irapada Kristi, Redeemed Christian Church of God, naa ṣe iwọde lati tako ipaniyan ni orilẹ-ede Naijiria.
https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-51702059
yor
religion
Ṣé pé àwọn "Revrend Sisitá náà ń wo "Blue" fíìmù lórí ayélujára? – Pope Francis dá sọ̀rọ̀
Poopu ijọ Aguda, Pope Francis ti kilo fun awọn alufaa ijọ naa, lọkunrin ati lobinrin lati sọra fun wiwo awọn fiimu ibalopọ lori ayelujara nitori irufẹ iwa bẹẹ yoo pa ina ẹmi ninu wọn. Poopu lo sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan lori bo ṣe yẹ ki awọn eeyan maa lo ikanni ibaradọrẹ lori ayelujara niluu Vatican. O ni wiwo fiimu ibalopọ ko dara rara, ọpọ eeyan lo si n wo irufẹ awọn fiimu bẹẹ laye ode oni. Gẹgẹ bii ohun ti poopu Pope Francis sọ, “O lewu fun ọpọ eeyan… to fi mọ awọn alufa ọkunrin ati obinrin.” O sọ fun fun awọn alufa na pe “Ẹmi Eṣu maa n gba ibẹ wọ inu aye eeyan.” Nipa bo ṣe ki awọn eeyan maa lo oju opo ayelujara lọna ti yoo so eso rere, Pope Francis ni ki wọn maa lo ni iwọntuwọnsi, ki wọn si maṣe fi akoko ṣofo lori rẹ. O ṣalaye pe “Ọkan mimọ, to n fun Jesu laaye lojojumọ ko le maa wo fiimu ibalopọ ko si wa bakan naa.” Lẹyin naa lo gba awọn eeyan naa niyanju lati fa awọn fidio ibalopọ yọ kuro lori foonu wọn, ki wọn ma ba ko sinu idanwo.” Yatọ si ijọ Aguda, pupọ ni awọn ijọ kaakiri agbaye lo koro oju si wiwo gbogbo ohun to jọmọ fiimu ibalopọ.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c2j0eyx8pr1o
yor
religion
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ Musulumi láṣẹ láti máa wọ Hijab nílé ẹ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko - Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ
Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti sọ pe awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi le maa wọ ijaabu lawọn ile ẹkọ to wa nipinlẹ Eko lai si idẹyẹ si kankan. Inu yara ile naa to wa niluu Abuja ni idajọ ọhun ti waye lọjọ Ẹti. Ṣaaju ni ile ẹjọ kotẹmilọrun kan ti kọkọ dajọ pe awọn akẹkọbinrin to jẹ Musulumi le maa wọ ijaabu naa lawọn ile ẹkọ nipinlẹ Eko lọjọ kọkanlelogun, oṣu Keje, ọdun 2016, amọ idajọ naa ko tẹ ijọba ipinlẹ Eko lọrun. Eyii lo mu ijọba Eko gba ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lọ ninu oṣu Keji, ọdun 2017, lati tako idajọ ti ile ẹjọ kọtẹmilọrun naa da. Iwe ẹjọ naa to ni nọmba CA/L/135/15lo n waye laarin ijọba ipinblẹ Eko ati arabinrin kan, Aisat Abdulkareem, arabinrin Moriam Oyeniyi ati ẹgbẹ awọn akẹkọọ tojẹ Musulumi ni Naijiria. Igbẹjọ laarin awọn obinrin yii ati ijọba Eko waye lẹyin ti adajọ Mudupe Onyeabo ti ile ẹjọ giga kan ni Ikeja, nipinlẹ Ekọ ti kọkọ fofin de lilo ijaabu lawọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ girama kaakiri ipinlẹ naa. Ẹgbẹ awọn Musulumi ọhun sọ pe ofin ti ile ẹjọ naa fi de ijaabu lilo n ṣafihan idẹyẹsi awọn akẹkọọbinrin to jẹ Musulumi l’Eko, ko si tẹ awọn lọrun. Ẹwẹ, nigba ti ile ẹjọ to ga julọ naa yo gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni ọrọ ẹsin ni ijaabu jẹ fun awọn Musulumi, o si jẹ ọna kan gboogi ti wọn fi n sin Ọlọrun. O ni ijaabu lilo fun awọn Musulumi ko ni da iyapa silẹ laarin awọn akẹkọọ Musuli naa atawọn akẹgbẹ wọn, bakan naa ni ko tumọ si pe awọn Musulumi n dẹyẹ si awọn akẹkọọ to ku ti kii ṣe Musulumi. Lara awọn adajọ to wa ninu igbimọ to gbe idajọ ile ẹjọ giga julọ naa kalẹ ni; Olukayode Ariwoola, Kudirat Kekere-Ekun, John Inyang Okoro, Uwani Aji, Mohammed Garba, Tijjani Abubakar, ati adajọ Emmanuel Agim. Nigab ti wọn sọrọ lori idajọ naa, Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi ni Naijiria, MSSN, Miftahudeen Thanni, sọ pe idajọ naa n tumọ si pe awọn Musulumi lawọn ile ẹkọ l’Eko le maa wọ ijaabu bayii lai si idẹyẹsi kankan lati ọdọ awọn akẹgbẹ wọn. O ni idajọ ọhun yoo mu ki igabgbọ awọn eeyan gbilẹ si ninu ẹka eto idajọ Naijiria. Lẹyin naa lo kilọ fun awọn olukọ atawọn araalu mii lati dẹkun idẹyẹsi awọn Musulumi nitori bi wọn ṣe yan lati maa mura ni ilana ẹsin wọn.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c51v719507jo
yor
religion
Kwara Hijab crisis: ìgbìmọ̀ olùwádìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ohun tó ṣokùnfà wàhálà hìjáàbù
Ìgbìmọ̀ olùwádìí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ṣe àgbékalẹ̀ láti ṣèwádìí ohun tó ṣokùnfà làásìgbò tó bẹ́ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ girama Oyun Baptist High School, Ijagbo, ti bẹ̀rẹ̀ ìjókòó ní ìlú Ilorin, olú ìpínlẹ̀ Kwara. Níbi ìjókòó wọn àkọ́kọ́, alága ìgbìmọ̀ náà, Dókìtà Shehu Omoniyi ṣàlàyé pé ìgbìmọ̀ náà kìí ṣe láti dúnkokò mọ́ ẹnikẹ́ni bíkòṣe láti fìdí ohun tí ó wáyé níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ gan. Omoniyi tẹmpẹlẹ mọ pé kókó ohun tí àwọn yóò ṣiṣẹ́ lé lórí ni láti mọ kí ló ṣẹlẹ̀, báwo ni ọ̀rọ̀ lílo ìjáàbùṣe di yánpọnyánrin àti láti ṣe àgbékalẹ̀ ìmọ̀ràn tó yẹ fún ìjọba kí irúfẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ má bá a lè wáyé lọ́jọ́ iwájú. Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀, kí wọ́n sì sọ òótọ́ lójúnà àti lè gbé ìmọ̀ràn tó da kalẹ̀ fún ìjọba. Ó fi kun pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni àwọn yóò fi ṣe iṣẹ́ tí tọ̀tún tòsì yóò sì dunnú sí èsì àbájáde ìwádìí àwọn. Bẹ́ẹ̀ náà ló pé fún fífi àyè gba ara ẹni pàápàá tó bá ti jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, kí ìbágbápọ̀ àláfíà le wà ní àárín ìlú. Olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé Nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Oyun Baptist High School, Ijagbo ní ọjọ́rú ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kìnní, àti ọjọ́bọ̀ ọjọ́ kẹta, oṣù kejì ọdún 2022, olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà, Francis Lambe ṣàlàyé bií iṣú ṣe kú àti bí ọ̀bẹ ṣe bẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Lambe ní ọ̀rọ̀ náà bá ẹ̀yìn yọ nígbà tí àwọn Kìrìsìtẹ́nì ìlú Ijagbo fárígá wí pé àwọn kò ní gbà kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mùsùlùmí lo hìjáàbù ní ilé ẹ̀kọ́ náà mọ́. Ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ilé ẹ̀kọ́ ìjọba ní ilé ẹ̀kọ́ náà àti pé ipa tí ìjọ Onítẹ̀bọmi ń kó ni láti fún ìjọba lámọ̀ràn lórí ẹni tí yóò bá jẹ olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà. Bákan náà ló ní gbogbo ìpàdé àti ìjíròrò tí àwọn ṣe pẹ̀lú àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ni kò so eso rere. Lambe wa rọ ìjọba láti pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kìrìsìtẹ́nì, CAN àti àwọn olórí ẹlẹ́sìn mùsùlùmí fún ìjíròrò láti lè jẹ́ kí wọ́n mọ gbogbo òfin ìlànà ìjọba lórí ètò ẹ̀kọ́. Ó ní ó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún àwọn pé ilé ẹ̀kọ́ àwọn wà ní títì pa pẹ̀lú ìdánwò WAEC ṣe ń súnmọ́ etílé. Àwọn wo ló wà nínú ìgbìmọ̀? Yàtọ̀ sí Dókítà Shehu Omoniyi tó jẹ́ alága, Akọ̀wé àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ijagbo, Emmanuel Adebayo Fatola náà jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ alága. Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ni Pásítọ̀ Modupe Oreyemi Agboola, Ọ̀mọ̀wé Saudat Baki, Alhaji Ibrahim Zubair Danmaigoro, Ẹni ọ̀wọ̀ Timothy Akangbe, tí Onídàjọ́ Ishola Olofere sì jẹ́ akọ̀wé. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn? Ọrọ Hijaabu wiwọ ni awọn ileẹkọ ijọba nipinlẹ Kwara tun ti n da wahala silẹ pada. Lọjọbọ, ija waye laarin awọn obi ati akẹkọọ kan ti wọn se iwọde lọ si ileẹkọ Girama Oyun Baptist Secondary School ni Ijagbo lori pe awọn alasẹ ile ẹkọ naa ko jẹ ki awọn ọmọ wọn to wọ Hijaabu wọ kilaasi. Ọrọ yi lo di wahala ti ikọlu si waye laarin awọn ọdọ musulumi ati Kristẹni to doju ija kọ ara wọn. Ni bayi, ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe ki wọn ti ileẹkọ naa pa titi ti alaafiayoo fi pada sibẹ. Ijọba Kwara to gbẹnu Kọmisana feto ẹkọ Hajia Sa'adatu Modibo Kawu sọrọ sọ pe awọn bẹnu atẹ lu ikọlu to waye ni Ijagbo yi. Kini Komiṣọnna sọ lori iṣẹlẹ yii? Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọnna fi sita lỌjọbọ, ijọba sọ pe awọn lawọn ni ile ẹkọ Oyun Baptist Secondary School tori naa nkan to sẹlẹ yi awọn ko faramọ rara. "Ijọba Kwara fi tọkantọkan koro oju si idẹyẹsi ẹnikankan paap awọn ọmọde nitori ẹsin.A ko ni faramọ iwa yi ni eyikeyi ileesẹ ijọba eleyi ti o ba jẹ ti ijọba''. Kọmiṣọnna naa tẹsiwaju pe ''Pẹlu bi ijọba ati awọn ajọ rẹ se n jiroro pẹlu awọn olori ẹsin mejeeji, a ti wa pasẹ bayi pe ki wọn ti ile ẹkọ naa pa tti ti ọrọ yi yoo fi lojutu'' ''A rọ awọn agbofinro lati se iwadii lori ọrọ yi ki wọn si mu ẹnikẹni to ba lọwọ ninu isẹlẹ yi kawọn eeyan baa le kọgbọn lara rẹ.Ijọba n beere fun alaafia nitori wahala kii so eso rere''. Ki lawọn ọlọpaa sọ? Ileesẹ ọlọpaa fi ọrọ sita ninu atẹjade lati ọwọ agbẹnusọ wọn Ajayi Okasanmi pe awọn fẹ fi da araalu Kwara loju pe alaafia ti pada si agbegbe naa. O ni ''ikọ kogberegbe ati awọn ọlọpaa to wa nilẹ ni ijagbo ti da alaafia pada si agbegbe naa ti wọn si duro digbi la ti ri pe wahala kankan ko waye nibẹ'' Agbofinro se alaye pe ọrọ hijaabu lo da wahala silẹ laarin awọn musulumi ati Kristẹni ti o ti n waye ti pẹ nipinlẹ Kwara. ''Eleyi to kan wa ni ọrọ wahala to bẹ silẹ laarin awọn eeyan ijagbọ ati awọn obi musulumi ti wọn n se iwọde.Wọn pada wa doju ija kọ ara wọn pẹlu ohun ija oloro'' Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60754507
yor
religion
MURIC pè fún ìwọ́de lẹ́yìn Jumat láti tako ìgbésẹ̀ ISI lórí Hijab wíwọ̀
Ọrọ lori gbigba ibori Hijab lori awọn akẹkọ ileewe girama ISI ni fasiti Ibadan ti fa ọpọ awuyewuye sẹyin. Amọṣa, titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ọrọ naa ko tii jẹ rodo lọ momi. Ni bayii, ẹgbẹ kan to n ja fun ẹtọ awọn musulumi, MURIC ti pe fun iwọde lati fi ẹhonu han lori ọrọ naa. Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, olori ẹgbẹ MURIC, Ọjọgbọn Ishaq Akintọla ṣalaye pe, gbogbo ọna to tọ lawọn ti gba lati yanju ọrọ naa ni tubinubi, ṣugbọn kaka ki ewe agbọn rẹ dẹ, pipele lo n pele sii. Ọjọgbọn Ishaq Akintọla ni ẹgbẹ MURIC ti ke sawọn musulumi kaakiri ẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria, lati gunle iwọde alaafia lẹyin isin Jumat ni ọjọ ẹti pẹlu aṣọ funfun lati fi ẹhonu han lori iṣẹlẹ naa. O ni ko si awijare fun igbesẹ ti awọn alaṣẹ ileewe girama ISI ni fasiti ilu Ibadan n gbe, labẹ ofin nipa fifofin de elo ibori Hijab ni ileewe naa. Oloyede ni kaakiri agbaye ni awọn ọmọbinrin ẹlẹsin musulumi ti n lo ibori Hijab sinu imura wọn, ati pe, ọgbọn ati fi ẹtọ ẹkọ dun awọn ọmọbinrin to jẹ ẹlẹsin musulumi ni ileewe naa. Ni ọdun 2018 ni wahala lori wiwọ ibori Hijab bẹrẹ ni ileewe girama ISI ni fasiti ilu Ibadan, eleyi ti o tilẹ ti de ile ẹjọ pada.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-48967303
yor
religion
Pastor Adeboye: Ariwo lórí ayélujára nítorí ọ̀rọ̀ ìkíni kú ọjọ́ọ́bí tí Pásítọ̀ Adeboye kọ sí ìyàwó rẹ̀, Folu
Pasitọ ijọ Redeem tun ti m'oke patapata lara awọn ti wọn n ka atẹjade wọn ju lori ayelujara. Ọpọlọpọ igba ni orukọ alufa yii ti sun soke lori ayelujara to si tun jẹ ọkan lara awọn gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọrun lagbaye amọ ọrọ tirẹ a maa fa ọpọlọpọ ọrọ jade lori ayelujara paapaa lẹnu awọn ọmọ Naijiria. Ọna ti Baba Adeboye gba ṣe ayẹsi ọjọ ibi iyawo rẹ, Folu Adeboye lọtẹ yii to pe ọdun mejilelaadọrin ma nii- ni awọn ọdọ Naijiria ba tu sita loju opo Twitter Adeboye lati da si ọrọ naa yala ni ti ṣiṣi fila fun ohun ti Pasitọ yii ẹni ọdun mẹtalelọgọrin funrararẹ sọ nipa iyawo rẹ, Folu Adeboye tabi tita ko o. Ninu aduru ọrọ to fi sita, eyi ti awọn eniyan han ni bi o ti ni " Oni lọjọ ibi iyawo mi mo si fẹ́ ki awọn obinrin kọ awọn ẹkọ kan latara rẹ paapaa ọpọlọpọ awọn ọdọ. "Bi iṣẹ ṣe pọ fun un to, iyawo mi lo ṣi n da ina ounjẹ to si n bu ounjẹ ti mo n jẹ, koda o ṣi maa n ge eekana fun mi. Ọpọlọpọ obinrin ode oni lo n fi gbogbo iṣẹ lẹ fun ọmọ ọdọ..." Baba Adeboye ni koda lasiko kan, iyawo oun ti gẹ irun fun oun nitori ilu ti iṣẹ iranṣẹ gbe wọn lọ lasiko naa. Fun ọpọlọpọ, ṣe ni awọn ọrọ naa wu awọn eeyan lori bi ifẹ to jinlẹ to eyi ṣi ṣe wa laarin awọn lọkọ laya iranṣẹ Ọlọrun yii pẹlu bi wọn ṣe dagba to - afi bii ifẹ ti kii ti tabi d'ogbo. @benmichael4ever fi fidi sita ninu eyi to ti gboriyin fun Pasitọ Adeboye to si wọ eebu le awọn obinrin to n bu u lori pe wọn ko lọpọlọ. Wọn ni ọpọlọpọ awọn to n tẹle wọn lori Facebook ati Twitter ṣugbọn wọn ko reeyan kankan tẹle wọn lọ sile baba wọn pe o fẹ fẹ wọn gẹgẹ bi ọkọ tabi aya. Ni ti awọn ti ko gba ti ọ̀rọ̀ ti Pasitọ Adeboye fi sita yii, ṣe ni wọn n bu ẹnu atẹ lu u. Ṣe ko si b'ọmọ ṣe dara to ti ko ni ni ọta. @solomon__c bu ẹnu atẹ lu u pe gbogbo ọrọ naa loju toun da bi ẹni to n keree gbogbo ipo ati iyi nla ti wọn ti gba ni. Koda ọpọlọpọ fidio lawọn ọmọ Naijiria fi ranṣẹ si Mama Adeboye gẹgẹ bi ikini ku ọjọ ibi to fi mọ awọn oṣere adẹrinpoṣonu gan atawọn ọmọ ijọ irapada naa. Haa, aṣe Baba Adeboye ko lee da ounjẹ jẹ, ko si lee da eekanna ara rẹ ge laisi iyawo rẹ lariwo ti awọn eeyan kan n pa bayii lori ayelujara ni kete ti iranṣẹ Ọlọrun Adejare Enoch Adeboye ki aya rẹ ku ọjọ ibi rẹ to waye ni ọjọ kẹtala oṣu keje. Ẹni ọdun mejilelaadọrin ni iyaafin pasitọ Folu Adeboye da lọdun yii ọrọ ikini ti baba Adeboye si fi ranṣẹ sii lori ayelujara ti n fa wahala. Ni kete to gbe ọrọ rẹ yii jade ni awsn ọmọ Naijiria kan ti fọn sori ayelujara lati fi ero wọn han lori ọrọ naa. Ọkan lara awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan loju opo Twitter @Mochevious kọọ soju opo naa pe, baba Adeboye i ba ti sọ pe " Ku ọjọ ibi ẹran ninu ẹran ara mi" ko si fi mọọ bẹẹ. Ni bayii a ti mọ pe ko lee ṣe awọn nnkan pẹ-pẹ-pẹ bii ko dana fun ara rẹ ati ko ge eekanna rẹ.TMI." Bakan naa, @Benxta_ naa sọ pe "Mi o lee gbagbọ pe Adeboye yoo joko o si wa ọna lati lo anfani ọjọ ibi iyawo rẹ fi sọrọ lori ara rẹ ati agbara to ni lori rẹ. Dipo ko kuku ti laa mọlẹ pe 'ku ọjọ ibi ifẹ mi' Amọṣa bi awọn wọnyii ṣe n sọ tiwọn lawọn kan naa n gbe sẹyin baba Adeboye pe otitọ ọrọ lo sọ. @TifeOfficial nitirẹ kọọ pe "tẹlẹ, o yẹ kawọn obinrin maa tẹriba fun awọn ọkọ wọn. Pasitọ Adeboye kan n sọ ododo ọrọ ni lati fi imoore han fun iyawo rẹ fun itẹriba to ni, nitori naa iwa oponu patapata gbaa ni lati maa fi ẹnu tẹmbẹlu rẹ, nitoripe ootọ ọrọ lo sọ." @OgbeniDipo kọọ soju opo tirẹ pe: "Njẹ o lee pe baba to bi ọ lọmọ ni oponu nitori pe o ko fara mọ ohun to sọ? Ki lo de ti ti Pasitọ Adeboye fi yatọ?" Pasitọ ijọ Redeem tun ti m'oke patapata lara awọn ti wọn n ka atẹjade wọn ju lori ayelujara. Ọpọlọpọ igba ni orukọ alufa yii ti sun soke lori ayelujara to si tun jẹ ọkan lara awọn gbajugba ojiṣẹ Ọlọrun lagbaye amọ ọrọ tirẹ a maa fa ọpọlọpọ ọrọ jade lori ayelujara paapaa lẹnu awọn ọmọ Naijiria. Ọna ti Baba Adeboye gba ṣe ayẹsi ọjọ ibi iyawo rẹ, Folu Adeboye lọtẹ yii to pe ọdun mejilelaadọrin ma nii- ni awọn ọdọ Naijiria ba tu sita loju opo Twitter Adeboye lati da si ọrọ naa yala ni ti ṣiṣi fila fun ohun ti Pasitọ yii ẹni ọdun mẹtalelọgọrin funrararẹ sọ nipa iyawo rẹ, Folu Adeboye. Ninu aduru ọrọ to fi sita, eyi ti awọn eniyan han ni bi o ti ni " Oni lọjọ ibi iyawo mi mo si fẹ́ ki awọn obinrin kọ awọn ẹkọ kan latara rẹ paapaa ọpọlọpọ awọn ọdọ. "Bi iṣẹ ṣe pọ fun un to, iyawo mi lo ṣi n da ina ounjẹ to si n bu ounjẹ ti mo n jẹ, koda o ṣi maa n ge eekana fun mi. Ọpọlọpọ obinrin ode oni lo n fi gbogbo iṣẹ lẹ fun mọ ọdọ..." Baba Adeboye ni koda lasiko ohun, iyawo oun ti gẹ irun fun oun nitori ilu ti iṣẹ iranṣẹ gbe wọn lọ lasiko naa. Fun ọpọlọpọ, ṣe ni awọn ọrọ naa wu awọn eeyan lori bi ifẹ to jinlẹ to eyi ṣi ṣe wa laarin awọn lọkọ laya iranṣẹ Ọlọrun yii pẹlu bi wọn ṣe dagba to - afi bii ifẹ ti kii ti tabi d'ogbo. @benmichael4ever fi fidi sita ninu eyi to ti gboriyin fun Pasitọ Adeboye to si wọ eebu le awọn obinrin to n bu u lori pe wọn ko lọpọlọ. Wọn ni ọpọlọpọ awọn to n tẹle wọn lori Facebook ati Twitter ṣugbọn wn ko reeyan kankan tẹle wn lọ sile baba wọn. Ni ti awọn ti ko gba ti ọ̀rọ̀ ti Pasitọ Adeboye fi sita yii, ṣe ni wọn n bu ẹnu atẹ lu u. Ṣe ko si b'ọmọ ṣe dara to ti ko ni ni ọta. @solomon__c bu ẹnu atẹ lu u pe gbogbo ọrọ naa loju toun da bi ẹni to n keree gbogbo ipo ati iyi nla ti wọn ti gba ni. Koda ọpọlọpọ fidio lawọn ọmọ Naijiria fi ranṣẹ si Mama Adeboye gẹgẹ bi ikini ku ọjọ ibi to fi mọ awọn oṣere adẹrinpoṣonu gan atawọn ọmọ ijọ irapada gan.
https://www.bbc.com/yoruba/53400033
yor
religion
RCCG Congress 2020: Pásítọ̀ ní owó Naira yóò sì tún gbé pẹ́ẹ́lí lẹ́ẹ̀kàn síi
Alabojuto gbogbogbo fun ijọ Redeemed Christian Church of God, RCCG, Pasitọ Enoch Adeboye ti sọ pe owo Naira yoo si tun pada niyi lawujọ awọn owo orilẹ-ede to gbe pẹẹli julọ lagbaye. Adeboye lo sọ ọrọ naa laarọ ọjọ Abamẹta nibi ipade adura Holy Ghost Congress to maa n waye lọdọdun ni Olu ijọ naa to wa lọna marosẹ Eko si Ibadan. Ẹni ọdun mejidinlaadọrin ọhun gbadura pe ki Ọlọrun da si eto iṣuna Naijiria, ko si tun yi ọkan awọn alaṣẹ to n mọọmọ ṣe awọn eto to n pa owo Naira lara pada. Adeboye sọ itan kan fun awọn eeyan to wa nibi ipade adura naa pe, ni ọpọ ọdun ṣeyin, oun nilo ẹgbẹrun marun un naira pere lẹyin ti oun pe ọpọ ero sibi ipade adura pẹlu ileri pe oun yoo gbọ bukata jijẹ ati mimu wọn. Bo tilẹ jẹ pe ko ni owo naa lọwọ, o ni Ọlọrun pese owo ọhun lọna iyanu. Pasitọ naa ni "owo Naira niye lori lọdun naa lọhun, yoo si tun niye lori lẹẹkan sii." "Gbogbo awọn to n mọọmọ rẹ owo naira silẹ, Ọlọrun yoo da si ọrọ wọn ki ilẹ ọla to mọ." Ọpọ ọmọ Naijiria to ti n lọgun pe owo naira ko niyi mọ lati nkan bi ọdun diẹ sẹyin, paapaa lẹyin ti owo dollar kan parada di ẹẹdẹgbẹta naira. Awọn to maa n ṣẹ owo ilẹ okere, Bureau De Change, sọ pe idi ti owo naira ṣe n lọ soke silẹ ko ṣẹyin awọn eeyan kan. Ẹwẹ, banki apapọ Naijiria, CBN, ni owo dollar kan ko to irinwo naira, gẹgẹ bi iṣiro to wa loju opo wọn lori ayelujara. Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti ṣalaye pe, oludari ijọ Redeemed Christian Church of God, Enoch Adeboye gbadura foun, o si tun sọ asọtẹlẹ pe oun yoo wọle ibo gomina ipinlẹ Edo fun saa keji. Gomina Obaseki sọrọ yii lasiko to n jẹri nibi akanṣe eto ọlọdọọdun ijọ Redeem, RCCG Holy Ghost Congress ti ọdun 2020 yii lọjọ Ẹti. Obaseki ni ''nigba ti ogun gbona giri giri, emi ati iyawo mi ṣabẹwo si Daddy G.O. ni ipagọ ijọ Redeem to wa lopopona ilu Eko si Ibadan. ''Lẹyin ti mo ṣalaye ipenija mi lagbo oṣelu tan, pasitọ Adeboye sọ pe ''ọmọ mi, ma foya, iwọ ni yoo bori, wa si wọle ibo gomina lẹẹkeji,'' Obaseki lo sọ bẹẹ. Gomina ni oun pada lọ ri alufaa Adeboye nigba ti idibo gomina ọhun ku diẹ, o si tun sọ foun pe gbogbo rẹ maa dara lẹyin ''to gbadura fun mi tan.'' Ẹgbẹ oṣelu APC lo gbe Obaseki wọle fun saa kinni gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Edo. Ṣugbọn ẹgbẹ APC ko fun un lanfaani lati jẹ oludije ẹgbẹ ọhun ninu idibo ọdun 2020, lẹyin rogbodiyan to ṣẹlẹ pẹlu alaga gbogbo-gboo ẹgbẹ oṣelu naa tẹlẹ, Adam Oshiomole. Pasitọ Osagie Eze-Iyamu ni APC fun lanfaani lati dije fun ipo gomina, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa dipo Obaseki. Eyi lo mu ki Obaseki lọ sinu ẹgbẹ oṣelu PDP, nibi to wọle ibo gomina ipinlẹ lẹẹkeji.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55285323
yor
religion
TB Joshua: Wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí òkú wòlíì yọ sí òṣèrébìnrin, Jaiye Kuti
Gbajugbaja oṣerebinrin, Jaiye Kuti sọ iriri rẹ nipa bi òkú Woli Temitope Joshua ṣe yọ si. Oṣerebinrin, Jaiye Kuti ni oku oloogbe, Woli Temitope Balogun Joshua, to jẹ oludasilẹ ile ijọsin Synagogue Church of All Nations, yọ si oun lẹyin iku rẹ. Ninu ọrọ to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ, Kuti sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun pe TB Joshua yọ si oun, bo tilẹ jẹ pe oun ko ri loju koroju ri nigba to wa laye. Ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa ni Woli naa jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta. Oṣerebinrin naa sọ pe nise ni ori oun dide jan-in lasiko ti oku TB Joshua yọ si oun, ti oun si ri to rọra kọja lọ jẹjẹ. "Mi o ri ri lojukoroju, sugbọn oku rẹ yọ si mi nigba to ku. Emi nikan ni mo wa ninu yara mi ni ilu Offa, ti mo deede ri to kọja. Ori mi dide. Nkankan to dara wa nipa ẹ̀mí naa." "Alaini ni Kristi, sugbọn o bọ́ awọn eniyan, o si n tọju gbogbo eeyan. Bẹẹ ni ìwọTB Joshua naa ṣe fun ọpọlọpọ. Eeyan meji ni mo mọ to fi aye wọn fun Jesu ni tootọ nipasẹ rẹ̀." Jaiye Kuti ni oun gbadura pe ki Ọlọrun tẹ Woli T. B Joshua si afẹfẹ rere. Bakan naa, nigba to n fesi si awọn ọrọ ti awọn ololufẹ rẹ kọ si abẹ awọn nkan to sọ nípa T. B Joshua, paapaa nipa nkan ti awọn eniyan sọ nipa oloogbe nigba aye rẹ. Jaiye Kuti sọ pe awọn erokero naa ko yọ oun silẹ. O ni oun naa gbagbọ bi awọn eeyan ṣe sọ pe Joshua kii ṣe iranṣẹ Ọlọrun tootọ. "Gbogbo wa la jẹbi awọn ọrọ naa nípa rẹ, nitori pe a ko ri aridaju nipa iru eniyan to jẹ." Oserebinrin naa wa n beere pe ta ni eeyan Ọlọrun gan bikose ẹni to se awọn ofin rẹ, to si jẹ pe awọn ojisẹ Ọlọrun nkan wa, to jẹ pe owo ni wọn n wa. "Wọn ko ni fi ọrọ Ọlọrun gan bọ wa debi pe a mọ ẹni ti Ọlọrun jẹ, okoowo ni wọn n fi ẹsin Kristiẹni se. Ni Italy, wọn maa fun wa lowo tori pe a wa sile ijọsin, wọn yoo fun wa lowo lati wa sin Ọlọrun ni amọ nibi yii, ohun gbogbo ta ni la fi n sin awọn ojisẹ Ọlọrun." O fikun pe ọpọ eeyan ni ko mọ ofin orilẹede yii amọ wọn le ka bibeli lori lati ibẹrẹ de opin. O wa kede pe wọn kan n fi ẹsin tu wa jẹ lasan ni, to si jẹ pe ọtẹ ati tẹmbẹlẹkun lo kun inu ọpọ eeyan to n fi ara rẹ we Kristi.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57490131
yor
religion
Hajj: Àjọ alálàájì ní owó Hajj ọdún yìí yóò tó N2.5m fún arìnrìnàjò kọ̀ọ̀kan
Ajọ Alalaji to n se kokari irinajo lọ silẹ mimọ Hajj, (NAHCON) ti kede pe arinrinajo silẹ mimọ kọọkan le san to miliọnu meji ati aabọ naira. Owo ti wọn yoo fi lọ si Mecca lọdun yii si lo fi idaji le si iye ti arinrinajo kọọkan san lọdun 2019 ti wọn seto Hajj kẹyin, ki arun Coronavirus to wọle de. Eyi fihan pe o le ni miliọnu kan naira to owo Hajj tọdun 2022 ta wa yii fi le si iye ti arinrinajo kọọkan san lọdun 2019. Alaga ajọ alalaaji NAHCON labẹ ijọba apapọ, Alhaji Zikrullahi Hassan lo sisọ loju ọrọ yii ni Ọjọbọ nibi ipade igbimọ alasẹ ajọ naa. Ipade ọhun lo wa fun ipalẹmọ feto Hajj fọdun ta wa yii. Nigba to n salaye idi ti alekun fi ba owo Hajj naa, Hassan ni pasipaarọ owo naira ilẹ wa si tilẹ okeere to mẹhẹ lo sokunfa alekun owo Hajj naa. Bakan naa lo ni awọn owo ọja to gbẹnu soke pẹlu ida mẹẹdogun ninu ọgọrun owo ori ọja ti wọn n san eyi tawọn alasẹ ilẹ Saudi Arabia n beere fun naa sda kun alekun owo Hajj naa. "Tẹlẹtẹlẹ lọdun 2019, naira mẹfalelọọdunrun ni a n sẹ owo naira si dọla amọ o ti di naira mẹwalenirinwo naira si dọla kan bayii. Gẹgẹ bi gbogbo wa se mọ pe ida mẹtadinlọgọrun pasipaarọ owo ilẹ wa si tilẹ okeere ni isẹ Hajj n ko eyi ta n na lori ounjẹ, owo baalu atawọn nnkan miran. "Ni afikun eleyi, awọn alasẹ ilẹ Saudi Arabia tun ti se afikun owo ori ọja tiwọn lati ida marun si mẹẹdogun. A tiraka ni iha tiwa lati mu adinkun ba awn isoro to le fẹ koju awọn arinrinajo nitori awọn ipenija naa." Hassan salaye pe ninu aaye arinrinajo bii ẹgbẹrun lọna mtalelogoji ati mẹjọ (43,008) tijọba Saudi fun Naijiria lọdun yii, aaye arinrinajo ẹgbẹrun lọna mẹrinlelọgbọn o din mẹrinlelogun (33,976 ) ni wọn yoo fun awọn ipinlẹ lapapọ. O ni ipinlẹ Kaduna ati Sokoto ni yoo gba ipin aaye Hajj to pọ ju, Kaduna yoo gba aaye ẹgbẹrun meji aabo din diẹ (2491), ti Sokoto yoo si gba ẹgbẹrun meji abọ o din diẹ naa (2404) Bakan naa lo salaye pe awọn ipinlẹ bii Bayelsa, Imo ati Rivers ko ni ipin aaye Hajj kankan lọdun 2022 yii nitori wọn ko ba ilana to yẹ nidii to de sise Hajj mu.
https://www.bbc.com/yoruba/media-61180966
yor
religion
Pastor Paul Adefarasin: Bí Naijiria kò bá rọrùn láti gbé ẹ gba orílẹ̀-èdè míì lọ
Bó ṣe nípasẹ̀ ọkada ni tàbí ọkọ̀ ojú omi tàbí láti inú ihò ilẹ̀, ẹ wá ọ̀nà láti fi Naijiria sílẹ̀- Pasitọ Paul Adefarasin Oluṣọagutan agba ati oludasilẹ ijọ House on The Rock, pasitọ Paul Adefarasin ti gba awọn ọmọ ijọ rẹ nimọran pe ki wọn fi Naijiria silẹ lọ ilẹ miran ti aye rẹ ba ṣi silẹ. Ninu iwaasu rẹ to ṣe lọjọ Aiku lo ti sọ ọrọ naa nibi to ti sọ pe awọn to ti n ṣejọba Naijiri bọ latẹyinwa ati lọwọ yii ko kọbi ara si bi nnkan ṣe lọ. Pasitọ naa ni bo tilẹ jẹ pe oun ni igbagbọ pe Naijira ṣi maa dara, oun ti wa wọrọkọ fi ṣ'ada lati fi Naijiria silẹ ti nnkan ba pada yiwọ. O ni "Mo mu ikinni wa fun yin lati ọdọ pasitọ Ifeanyi to n ṣeto ọna abayọ wa… mo mọ pe ẹ ni igbagbọ o, emi naa ni igbagbọ, ṣugbọn mo ti wa abayọ lati fi orilẹ-ede yii silẹ." Adefarasi ṣalaye pe oun le ṣe iwaasu fun awọn ọmọ ijọ naa lati ibikibi lorile¬̣-ede agbaye pẹlu imọ ẹrọ, nitori naa lo ṣe ṣe pataki ki awọn eeyan naa tete wa ọna abayọ lati sa kuro ni Naijiria nitori gudugbẹ to ṣeeṣe ko ja lọjọ iwaju. O ni "Bo ṣe nipasẹ ọkada ni tabi ọkọ oju omi tabi lati inu iwo ilẹ, ẹ wa ọna abayọ lati fi Naijiria silẹ nitori awọn adari Naijiria ko ni afojusun rere fun araaalu." Pasitọ naa tun ke si awọn adari ijọba ni Naijiria lati tun Naijiria ṣe ki ogun abẹle keji ma baa bẹ silẹ. Gẹgẹ bo ṣe sọ "Iṣoro Naijiria ti pọ ju ti tẹlẹ lọ, o si yẹ ki a ṣe iwadii awọn iṣoro naa lati ipinlẹṣẹ igba ti a gba ti ominira, bi bẹẹ kọ, ko si ohun ti a le ṣe lati yanju iṣoro ti a n koju." Pasitọ naa pari ọrọ rẹ pe ko si orilẹ-ede kankan to le farada ogun abẹle meji. Lẹyin naa lo rọ awoon adari lati pe ipade apero ki wọn si jiroro bi Naijiria yoo ṣe ni ilọsiwaju lawujọ awọn akẹgbẹ rẹ. Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ọrọ ti pasitọ naa sọ. Bi awọn kan ṣe n kiin lẹyin pe ootọ ọrọ lo sọ lawọn mii n sọ pe kii ṣe irufẹ iwaasu to yẹ ko maa ṣe fun awọn ọmọlẹyin rẹ niyẹn.
https://www.bbc.com/yoruba/57068055
yor
religion
Àwọn Krìstẹ́ní Yoruba Nation kọ̀wé sí CAN láti pínyà!
Ẹgbẹ Yoruba Nation Christian Association (YORNCA), awọn Kristẹni to wa laarin awọn ajijagbara fun orilẹede Yoruba yii n pe fun didaduro gedegbe ati kikuro labẹ akoso apapọ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria CAN. Eyi lo mu ki wọn kọ iwe ti wọn si dari si Aarẹ ẹgbẹ CAN, Alufa agba, Daniel Chukwudumebi Okoh, lati fi to gbogbo ẹgbẹ leti pe asiko ile ti to fun awọn ọmọm Yoruba to wa laarin CAN. Wọn kọ sinu rẹ pe “koko iwe na ni lati sọ fun ẹgbẹ CAN pe ẹgbẹ Yoruba Nation Christian Association (YORNCA) to ko gbogbo ọmọlẹyin Kristi atawọn ile ijọsin to wa nilẹ Yoruba to darapọ mọ awọn nile ati lẹyin odi pe awọn ti fẹ kuro lara ẹgbẹ CAN. Ohun ti eleyi tumọ si ni wipe wọn n fẹ ki awọn Kristẹni ẹya Yoruba yọra kuro labẹ idari ati akoso ẹgbẹ CAN. Nigba ti BBC Yoruba kan si akọwe agba ẹgbẹ naa, Pasitọ E.A Agboola, o jẹ ko di mimọ pe Ọlọrun alaaye ni awọn kọkọ fẹyinti ti awọn ṣe gbe igbesẹ yii, bakan lo sọ pe ẹgbẹ apapọ Yoruba Self Determination Movement (YSDF) to jẹ asia nla ti gbogbo ẹgbẹ to n ja fun iran Yoruba wa labẹ rẹ to si ni Ọjọgbọn Banji Akintoye jẹ baba fun awọn naa. “Baba wa Ọjọgbọn Banji Akintoye lo fi ẹgbẹ wa lọlẹ”, Agboola sọ fun BBC Yoruba. "Iran ti kii korira tabi ṣe ẹlẹyamẹya ni Yoruba torinaa la ṣe gba awọn ẹsin ti oyinbo mu wa laye atijọ lai ja tabi ni ẹnikẹni lara lati yan eyi ti o ba fẹ ṣe." Akọwe ẹgbẹ naa jẹ ko di mimọ pe bi ẹnikẹni ba n reti ki orukọ awọn ilumọọka Pasitọ wa lara awọn, ko lee ri bẹẹ toripe wọn ti baba wa labẹ akoso CAN amọ sibẹ sibẹ, awọn adari ijọ ti wọn si jẹ Pasitọ to to mẹrinlelogun lo jẹ alakoso ẹgbẹ YORNCA. Agboola ṣalaye pe kii ṣe pe awọn ni nkankan lodi si ẹgbẹ CAN to wa ni Naijiria amọ bi lẹta wọn ṣe sọ, oju awọn ọmọlẹyin Kristi ti ri ọpọlọpọ idamu ninu orilẹede Naijiria ti wọn si gbagbọ pe awọn to fẹ pa ilu run lo wa nidi eyi paapaa bi wọn ṣe ni wọn n doju le ẹya Yoruba. Bakan naa wọn tọka si bi awọn agbesunmọmi ṣe n pa awọn Kristẹni kaakiri orilẹede Naijiria ti wọn si ni awọn ni ọpọlọpọ ẹri bii ti Deborah Samuel ti wọn pa ni ọjọ Kejila Oṣu Karun ọdun 2022 ti awọn kan sọ ni okuta ti wọn si tun dana sun un ni ilu Sokoto. Lafikun, o mẹnu ba ikọlu to waye si ijọ Katoliki ti ilu Owo lọsan gangan nipinlẹ Ondo ni ọjọ Karun Osu Kẹfa ọdun yii kan naa. Ẹwẹ, wọn ni awọn o na ika abuku si ẹsin tabi ẹya kankan o toripe ọpọlọpọ eekan Naijiria lo jade lati bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa. “Torinaa ni awa Kristẹni nile ati lẹyin odi to jẹ ọmọ Yoruba ṣe kọ lati jẹ ẹru ni ilu tiwa ti Ọlọrun fun wa. Awa ajọ Kristẹni ọmọ Yoruba yoo yapa kuro patapata lorilẹede Naijira ni kete ti wọn ba ti kede Yoruba Nation gẹgẹ bi orilẹede ara rẹ, eleyi ko si ni pẹ rara si akoko yii”. “A fọwọ ati ẹsẹ si gbogbo akitiyan ti Baba wa ati adari, Ọjọgbọn Banji Akintoye n ṣe a si mọ pe wọn ti kọ iwe ranṣẹ ni ilana ofin si Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lati fi ifẹ iran Yoruba han lati yapa kuro lorilẹede Naijria.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c4nrxxjr7yeo
yor
religion
Fake Pastors: Bunmi àti Rukayat ni agbódegbà àwọn afurasi pasitọ náà
Awọn òṣìṣẹ́ ọ̀tẹlẹ́múyẹ́ to n rí si ìwádìí ọ̀dáran nípinlẹ̀ Eko ti mú àwọn mẹ́rin kan tọ fi mọ olùsọ́aguntan méji. Wọn fẹ̀sun kan pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ amí ati iṣẹ ìyanu èké ti wọ́n si n purọ gbówó lọ́wọ́ àwọn olùgbé Lekki àti Epe nípínlẹ̀ Eko. Àwọn pásìtọ tí wọ́n fẹ́sùn kan ní Favour David ati Favour Chimobi pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Rukayat Folawewo àti Bunmi Joshua, láti maa ṣe ìṣẹ́ jìbìtì wọ́n. Agbẹ́nusọ ọlọpàá ní ìpínlẹ̀ Eko Bala Elikana, sọ nínú àtẹjáde kan pe àwọn afurasí náà maa n wá ọmọ ìjọ fún ìjọ Wonders Assembly Ministry to waà ni àdojúkọ Lagos Business School ní márosẹ̀ Lekki/Epe ni Ajah. Elkana ni "a mú afurasí mẹ́rin ti wọ́n maa n fi iṣẹ́ ìyanu òfége lo gbájuẹ̀ fún àwọn ara ilú ti ko fúra, wọ́n ṣe asọtẹlẹ, awọ́n miran a jẹri èké, èyi ni wọn n lò láti gbowó lọ́wọ wọ́n ti wọ́n a sì tún maa lo àwọn ọna miran láti kó ọrọ̀ jo." Elkana ni lẹ́yin ti ará ìlú tàwọn lolobó ni àwọn gbé ìgbésẹ̀ ti àwọn si mú àwọn obinrin méji, Rukayat Folawewo àti Bunmi Joshua ti wọ́n n ṣe bi ọmọ ìjọ naa ti wọ́n sì ri iṣẹ́ ìyànú ìwòsàn gbà láti ọwọ pásìtọ lẹ́yìn ìjàmba ọkọ̀. "Ní ti Bunmi Joshua nítirẹ, oun jẹ́ri èké fún àwọn ọmọ ìjọ naa pé ọmọ oun to ti kò gbọ́ran ti ko si lè sọrọ ri ìwòsàn gbà. O tun ni o sì ti n gbọ́ran àti sọ̀rọ̀ báyìí lábẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ pásìtọ Favour Chimobi ti ìjọ Elijah Ministry ní Port Harcourt ti oun ati pasitọ David Favour jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Elkana sàlàyé pé ìwádìí fihan pé ìrọ panbele ni gbogbo ẹ̀rí náà, ti wọ́n si mu àwọn afurasi náà lásìkò ìṣọ́ oru.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50654916
yor
religion
Yoruba Nations Vs Islamic petetioners: Àwọn Mùsùlùmí kan bẹ̀rẹ̀ ìpẹ̀jọ́ lòdì sí Oodua Republic, Igboho fèsì
Olori ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede Yoruba Nations, Sunday Igboho ti fi esi sita pe irọ nla ni awọn to gbe igbesẹ kikọwe ipẹjọ lori ayelujara pe orilẹede Oduduwa Republic ko ni faaye gba ẹtọ awọn musulumi. Ninu ọrọ ti agbẹnusọ Sunday Igboho, Olayomi Koiki fi sita lori ayelujara, o bi wọ́n ni ibeere pe ṣe ni orilẹede Naijiria ni aabo ti wa fun Musulumi? Koiki ni "bi ẹ ba ti ri iru ipẹjọ yii, kẹẹ bere ibere yii lọwọ wọn". O fi kun un pe Yoruba Nation yoo faaye gba gbogbo ẹsin gẹlẹ bii ti orilẹede UK, USA, Germany, France atawọn orilẹede mii to faaye gba ẹtọ eeyan lati ṣe ẹsin rẹ. Awọn ẹgbẹ ẹlẹsin Musulumi naa ni iha Guusu-Iwọ Oorun eyi tii ṣe ilẹ Yoruba lo n tọwọ bọwe lori itakun ayelujara kan ipetitions.com. Wọn ni eyi wa lati tapa si ijagbara to n waye pe ki iran Yoruba da ni orilẹede tirẹ lọtọ ki wọn si yapa kuro lorilẹede Naijiria. Gẹgẹ bi awọn kan to buwọ lu iwe ọhun ṣe sọ, ko si eto to jọ mọ pe wọn yoo gbọ ti awọn Musulumi nilẹ Yoruba ninu ija ti wọn n ja fun Yoruba Nation. Ipejọ ori ayelujara yii bẹrẹ lati ọwọ Oyedeji Owoseni ni Ọgbọnjọ oṣu karun to si ti ko itọwọbọwe to fẹrẹẹ to ọọdunrun ati esi ọrọ to fẹrẹẹ to igba ninu iroyin ti a ti ri ikede yii. Koko ọrọ ti wọn si kọ sinu iwe ipẹjọ ori ayelujara ọhun ka bayii pe: Ọrọ to kan awọn Musulumi ko ṣe pataki si awọn ajafẹtọọ Oodua; wọn ko tilẹ fi ti awọn Musulumi ṣe rara ninu ilana wọn, Musulumi ko ni aabo labẹ aato wọn. Ileeṣẹ iroyin Naijiria kan woye latinu iwe ori ayelujara ti wọn n tọwọ bọ pe ọpọlọpọ awọn to tọwọ bọ iwe naa lo jẹ Musulumi ọmọ orilẹede Naijiria ti awọn diẹ mii naa si tọwọ bọ ọ lati orilẹede Amẹrika, Burkina Faso, Sweden, Saudi Arabia ati London. Ọkan lara wọn, Abibat Adebisi Sanusi ni "O dara ki a wa papọ gẹgẹ bi orilẹede kan, Naijiria. Ohun taa ni lati ṣe ni ka fi aaye silẹ fun anfani to pọ". Adesina Kareem ni tirẹ kọ pe, "inu mi ko dun si awọn to n dari eto naa. Ọpọlọpọ wọn o ṣee fọkan tan pẹlu agbara". Sulaiman Abdul Majeed ko si ibi kankan to han pe wọn ti faaye gba mi ninu eto ijijagbara Oodua /republic. Baba Moshood ni "mi o ti Oodua nation lẹyin tori awọn to n ja fun un, janduku ni wọn, afipamuni ati ọdaran". Olawuyi Abdul Akeem ni, "mi o gbagbọ ninu Oodua Nation. Mo fura si i, o ni ọwọ ẹgbẹ okunkun ati ẹsin Kristẹni ninu". Sanusi Ibrahim ni wọn ko ni faaye gba ẹtọ oun lati ṣe ẹsin oun, o ni wọn ti n dena awọn ọmọbinrin Musulumi lati lo Hijaabu lawọn ileewe ijọba, wọn o tun gba awọn obinrin to fẹ tẹle ofin Quaran laye. Adeniyi Liadi Oyedele sọ pe "Afojusun awọn ajijagbara naa ni lati tẹ ksin Islam ati awọn Musulumi ri mọlẹ ni iha Guusu - Ila Oorun ki wọn ba le gbe eto ikọkọ wọn jade" o si ni Musulumi ododo kankan o gbọdọ ti wọn lẹyin. Ẹwẹ, agbẹnusọ fun olori ajijagbara Yoruba Nations, Sunday Igboho iyẹn Olayemi Koiki ti fi esi sita pe irọ nla ni awọn to gbe igbesẹ yii n pa. O wa gba imọran pe ki wọn ma gba "awọn eeyan perete kan to n ri jẹ nidi ibajẹ ati iwa ajẹbanu orilẹede ti wọn n pe ni Naijiria lati sọ fun wa pe ko ni si aabo fun awọn Musulumi ni orilẹede tuntun naa".
https://www.bbc.com/yoruba/57323823
yor
religion
Yoruba traditon: Ohun tí Yorùbá ń pè ní Èṣù yàtọ̀ sí Sàtánì nítorí Èṣù ní iṣẹ́ rere lọ́wọ́ -Ejùgbọ̀nà ìlú Rẹ́mọ
Ọpọlọpọ igba ni adapọ ati edeaiyede maa n waye lori Esu. Ta ni, bawo lo ṣe jẹ ninu itan iṣẹdalẹ Yoruba ati pe ṣe lootọ ni pe idi iṣẹ buruku la ti maa n ri? Edeaiyede yii lo mu ki ọpọ maa daa pe ni Satani, sugbọn awọn baba mọnimọni ṣalaye pe iyatọ pọnbele lo wa laarin Esu ti iṣẹṣe Yoruba ati Satani ti ọps awọn iwe ẹsin miran n fihan. Ninu igbagbọ Yoruba, aṣeburuku ṣe rere ni Esu jẹ, bẹẹni ko si irumslẹ kankan nilẹ Yoruba ti kii fi ti Eṣu laalu ogiri oko ṣe. BBC News Yoruba tọ awọn agba lọ lagbegbe Ijẹbu lati mu ẹkunrẹrẹ ims ati alaye lori Eṣu, ojuṣe rẹ laarin awọn igba irumọlẹ, ati ohun to faa ti ọps maa fi n pariwo iṣẹ Eṣu ni bi iṣẹlẹ buburu kan ba ti ọdọ wọn jade.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58278044
yor
religion
Imam Abubakar: ìdí tí mi ò fi fi méní pe méjì láti ṣí Mọ́sálásí fáwọn Krìstẹ́nì
"Lẹ́yìn ìrun, ló ṣẹlẹ̀, a ṣí Mọ́sálásí fún àwọn Krìstẹ́nì láti sá pamọ́". Akọroyin BBC ba Imam Abubakar to gba awọn ẹlẹsin Kristẹni lalejo labule Ngargerwa, ipinlẹ Jos. Imam ni oun ko la ala iru ayẹsi ti oun n ri gba bayii ri laye oun bẹẹ si ni oun ko tilẹ ronu ohun ti yoo tẹyin rẹ wa nigba ti oun ṣeranwọ fawọn Kristẹni lọjọ naa. "Mo sọkún bíi ọmọ́dé nígbà tí à ń gbé òkú àwọn ti wọn pa sita". Imam ṣalaye bi jinijini ṣe bo gbogbo eniyan ti wọn ko roju wo ẹsin kan ni tẹnikan tabi omiran. Bakan naa, Pasitọ atawọn Kristẹni to ku sọ ohun toju wọn ri ti wọn fi gbudọ maa dupẹ lọwọ Imam Abubakar titi di oni.
https://www.bbc.com/yoruba/49930545
yor
religion
Prophet Israel Oladele: Kilo gbe e de ijọ Celestial?
Idile ẹlẹsin musulumi ni wọn bi Woli Israel Oladele si. Orukọ abisọ rẹ ni Wasiu. O si jẹ ọmọ ilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun. Awọn obi rẹ pada di ẹlẹsin Kristiẹni, ti wọn si n lọ sinu ijọ kan ni agbegbe Oshodi nipinlẹ Eko. Gẹgẹ bi akọsilẹ itan igbesi aye rẹ to wa lori ayelujara itakun agbaye ijọ naa, genesisglobal.org, idile ti ko ri ọwọ rọri lo ti wa, nitori oju owo pọn awọn obi rẹ pupọ. O kiri ọja bi mọin-mọin ati burẹdi, bakan naa lo sẹ awọn iṣẹ pẹẹpẹẹpẹ lati ran awọn obi rẹ lọwọ gẹgẹ bi akọbi. Iṣẹ ati oṣi to ba awọn obi rẹ finra ko jẹ ko lọ si ileewe tayọ ileewe girama. Koda, ko kẹkọọ pari ti ko fi lọ mọ. Itan igbesi aye Wooli Oladele Ogundipe sọ pe idile rẹ ko fẹran ijọ alaṣọ funfun, nigba to wa ni kekere. Igbagbọ wọn ni pe awọn to n lọ si awọn ijọ naa maa n ṣe oogun, ati awọn nkan ti ko tọ gẹgẹ bi Kristiẹni to jẹ atunbi. Ijọ Aposteli Kristi, CAC, ni oun ati awọn obi rẹ n lọ. Iwaju ile wọn si ni ile ijọsin naa wa. O sọ pe awọn kan riran si iya oun nigba to loyun pe ọmọ inu rẹ yoo ṣiṣẹ fun Ọlọrun, amọ iṣẹ alfa tabi imaamu ni awọn obi rẹ n fọkan si nitori ẹlẹsin Musulumi ti wọn jẹ lasiko naa. Ṣugbọn iṣẹlẹ buruku kan waye ni ọjọ kan. Iya Oladele jẹ ẹnikan lara awọn obinrin inu ijọ naa ni owo, ti ko si ri i san. Ni obinrin naa ba wa sile wọn, to si pariwo le iya rẹ lori lati san owo naa. Ibi ti ariwo ti n waye ni obinrin naa ti ya aṣọ kan ṣoṣo ti iya Oladele maa n wọ jade, mọ ọ lọrun. Oladele sọ pe iṣẹlẹ naa mu itiju ati ibanujẹ ba oun. Eyi lo si mu ko pinnu lati ma lọ si ṣọọṣi naa mọ, nitori itiju. Eyi lo mu ko darapọ mọ ijọ Cele kan ti ko jinna si ile wọn. Gẹgẹ bi ẹni to mọ ilu lilu, Oladele bẹrẹ si ni ba wọn lu ilu ninu ijọ naa. Kẹrẹ-kẹrẹ, lo ba di ọmọ ijọ Celestial. O ni kii ṣe idaamu, tabi aisan lo gbe oun de inu ijọ alaṣọ funfun. Nibẹ lo ti bẹrẹ si ni 'gun oke ẹmi', ti ko si ni mọ nkan to n lọ ni ayika rẹ fun bi ọjọ meje, lai mu omi tabi jẹun, to si sọ n sọ asọtẹlẹ. O si ti n ṣiṣẹ alufaa ijọ Cele fun ọdun mẹrinla gbako. Afojusun rẹ si ni lati da yatọ si awọn ijọ Cele yooku, nipa iwaasu ati isẹsi wọn. Wòlíì Genesis kan yẹra díẹ̀ ni, ó máa tó wọlé padà bí olè lóru- Adelé pásítọ̀ Oladele Adelé pásítò Oladele ní wòlíì Genesis kan yẹra díẹ̀ ni, ó máa tó wọlé padà bí olè lóru Adaba o naa ni a n kungbẹ, ina n jo ẹyẹ oko n lọ ni ijọ Celestial Church of Christ Genesis Global fi ṣe lẹyin ti ileẹjọ dajọ ẹwọn ọdun meji fun alakoso ijọ naa, Woli Israel Oladele lori ẹsun gbajuẹ. Niṣe ni ijọ naa kun fọfọ ni isin ọjọ isinmi akọkọ to waye ninu ijọ ọhun lẹyin ti woli naa rẹwọn he. Adele oluṣọ woli Oladele, Samuel Oba sọ ninu iwaasu rẹ pe ohun to ṣẹlẹ ko le fa iwariri ninu ijọ naa. O ni Woli Genesis kan yẹra diẹ ni, ''ti akoko ba to, yoo wọle pada bi ole loru.'' ''Ṣugbọn awọn ọta lo kan n polongo ohun ti ko ṣẹlẹ kaakiri,'' Pasitọ Oba lo sọ bẹẹ ninu iwaasu rẹ. Pasitọ Oba tun fi igboya sọrọ pe ''mo wa nibi ti ẹ ba fẹ gbe mi, ẹ wa gbemi.'' Alufaa ọhun tun sọ pe ko si ohun ti awọn fẹ ki ọlọrun ṣe fun Woli Genesis ti ko tii ṣe fun tẹlẹ. O rọ gbogbo awọn ọmọ ijọ CCC Genesis Global wi pe ki wọn kun fun ayọ, ki wọn si maa ṣe bi ẹni ti ibanujẹ ba nitori ohun to ṣẹlẹ si alufaa Oladele. Israel Oladele Ogundipe (GENESIS) ni oludari ati alakoso ijọ Celestial Church of Christ, Genesis Global, ọkan ninu awọn ẹni ifami ororo yan tawọn ololufẹ rẹ n warii fun gẹgẹ bí ajinrere fun ijọ CCC lagbaye. Olusọaguntan ni pẹlu, ó jẹ olukọ ati onisesẹ Aposteli. Ọmọ ilu Igboore ni ilu Abeokuta ipinlẹ Ogun ni woli Israel Oladele ṣugbọn ọmọ atapata dìde ni to si jẹ iya ki o to de ipo to wa. Ẹni ọdun marundinlaadọta ni Israel Oladele Ogundipe. Ṣaaju, awọn ọmọ ijọ rẹ ti ba BBC Yoruba sọrọ pe:
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55012450
yor
sports
Mikel Arteta: Wọ́n ti kéde Mikel Arteta gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Arsenal tuntun
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti kede Mikel Arteta gẹgẹ bi akọnimọgba rẹ tuntun. Ninu adehun iṣẹ naa, Arteta yoo dari ikọ Arsenal fun ọdun mẹta ati aabọ. Idunu ati ayọ ni Arteta fi gba iṣẹ naa to si sọ pe "O jẹ iyi nla fun mi lati dara pọ mọ ikọ Arsenal." O tẹ siwaju pe "Inu mi dun nitori Arsenal jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu to tobi ju lagbaye." Arteta ti n ṣe iṣẹ tẹlẹ gẹgẹ bi adari labẹ Pep Guardiola ni Manchester City lẹyin to darapọ mọ ikọ ọhun lọdun 2016. Ọmọ ọdun mẹtadinlogoji naa ti fi igba kan ṣe iṣẹ ni ikọ Arsenal yii ati ikọ Everton ri. Awọn adari ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ko tii kede awọn ti yoo ba Arteta ṣeṣẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50871297
yor
sports
Anthony Joshua: Kí ni abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Anthony Joshua fi n wu àwọn ọmọ Naijiria tí gbogbo wọn fẹ́ tan mọ́ ọ?
Ibẹrẹ Anthony Joshua Wọn mọ ẹbi Joshua daadaa ni ilu Sagamu, ti wọn si mọ itan awọn baba nla rẹ daadaa. Baba-baba-baba rẹ ni Daniel Adebambo Joshua, ọlọrọ onilẹ ati oniṣowo ti wọn gbagbọ pe o yan orukọ kẹta rẹ nigba to di ọmọlẹyin Kristi. Daniel ran ọmọ rẹ kan nileewe nilẹ Britain, nibẹ lo ti fẹ obinrin Irish kan to ba a wale pada si Naijiria nibi ti wọn ti tọ ọmọ meje. Ọkan lara awọn meje ọhun ni Robert to fẹ Yeta Odusanya lati ilu Sagamu kan naa, ohun si ni baba Anthony ati aburo rẹ, Janet. Orukọ mii ti Anthony n jẹ ni Olaseni. Awọn aṣeyọri rẹ ninu jija ẹṣẹ fihan pe idile rẹ gbajumọ tayọ ilu wọn nikan de gbogbo orilẹede Naijiria. Pẹlu iyi lo fi maa n pọn orilẹede rẹ le nibikibi to ba wa, asia Naijiria ko le ma fẹ lẹlẹ nibi to ba ti n ja, koda aworan Afirika wa gbagada lapa rẹ. O maa n fihan pe oun fẹran awọn ounjẹ ibilẹ Naijiria gan Bi o ṣe fẹran Naijiria to, o ko ounjẹ ranṣẹ sile fun awọn idile ti Coronavirus ṣakoba fun. O jẹ ẹni to lẹkọ ile pẹlu ọrọ pẹlẹ lẹnu ati ẹrin musẹ to maa n di ẹrin keekee. O nira ki Anthony ma bori to ba ja ẹṣẹ tori naa irawọ to tan jade wa lati Naijiria ni ọpọ ka a si, eyii si mu ki ọpọlọpọ ololufẹ rẹ lati Naijiria fẹran rẹ gan. Ero maa n wọ ni nibi iworan ti wọn ti maa n wo ija Anthony Joshua ni Sagamu, koda Joshua tun ni ẹgbẹ awọn alatilẹyi n tirẹ ni Sagamu. O to ẹgbẹrun mẹwa ololufẹ rẹ to wo ija kan, koda awọn kan rinrinajo lọ wo o. Bi Joshua ko tilẹ ṣe raye ri ipade ṣe pẹlu awọn ololufẹ rẹ nigba to wale ninu oṣu keji, ko sẹni to binu si i, ṣugbọn o ri ọba ati awọn ijoye ko to pada. "Ko si iyọnu, ọmọ wa naa ṣi ni, aṣoju wa si ni," ọkan lara wọn, Okunore lo sọ bẹẹ. "Mo mọ pe o tan mọ Watford amọ ọmọ ilu wa ni baba ati baba baba rẹ ati babaa babaa babaa rẹ". Iwuri ni Joshua Ọpọ ọdọ ni ẹkun Guusu-Ila Oorun lo ti n fi Joshua ṣe awokọṣe pẹlu bi wọn ṣe n wo o ti wọn si n farabalẹ kọ bo ṣe n goke. Ẹni ọdun mọkanlelogun kan, 'Lekan the Engine' Muibi to jẹ mọkaliiki ni Ooṣa ni Joshua jẹ si oun. "Mike Tyson gangan lo mu mi fẹran jija ẹṣẹ amọ Joshua lo n ti mi soke pe mo lee moke tori ọmọ Naijiria bii emi loun".
https://www.bbc.com/yoruba/55282407
yor
sports
Benin vs Nigeria: Mínísítà ní kí Super Eagles lọ lu Benin mọ́lé nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àti pegedé fún AFCON 2021
Minisita ere idaraya ati ọrọ idagbasoke awọn ọdọ, Sunday Dare ti rọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria pe ki wọn lọ lu alatako wọn wọn, Benin Republic mọle. Super Eagles gunlẹ si Benin Republic lọjọ Ẹti fun ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ere bọọlu ilẹ Afirika, AFCON 2021. Ninu ọrọ iyanju rẹ sawọn agbabọọlu Naijiria, minisita só fun wọn pe ''aileja lojude ile baba mi o de bi, ẹ bẹrẹ daadaa, ṣugbọn ni bayii, ẹ gbọdọ pari daadaa bakan naa. Ko si ere bọọlu to rọrun, nitori naa, ẹ maa foju di awọn agbabọọlu Benin Republic tori pe ko si ọbọ kan ni dere mọ lagbo ere bọọlu afẹsẹgba,'' minisita lo sọ bẹẹ. Ọgbẹni Dare sọ fawọn agbabọọlu Naijiria pe ki wọn sa gbogbo ipa wọn lati fo bi ẹyẹ idi ti orukọ inagijẹ wọn n jẹ. Naijiria lo si wa loke tente lori isọri kejila awọn orilẹede to n gba ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije AFCON 2021. Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti jawe olubori ni meji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ti wọn ti gba nigba ti wọn ta ọmi meji bakan naa. Orilẹede Benin lo wa ni ipo keji lẹyin tawọn naa jawe olubori ninu ere bọọlu meji ṣugbọn wọn fidi rẹmi ninu ọkan nigba ti wọn ta ọmi ninu omiran. Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo ri ifẹsẹwọnsẹ naa wo loju opo Twitter rẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-56548138
yor
sports
FA Cup final Arsenal vs Chelsea: Lampard laná! Arsenal fa Chelsea ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ gba ife FA Cup
Ami ayo meji si odo ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal fi ja ife idije FA Cup mọ Chelsea lọwọ. Nkan gbona janjan bi amala gbigbona lasiko ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Arsenal koju ara wọn ni aṣekagba idije FA Cup. Papa iṣere Wembley to jẹ ti Chelsea ni idije na ti waye. Nigba ti yoo fi di ọgbọn iṣẹju ti idije naa bẹrẹ, Chelsea ati Arsenal ti ku eruku ami ayo kọọkan si ara wọn l'oju. Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lo kọkọ gba bọọlu wọle, lati ọwọ ọmọ ilẹ America, Christian Pulisic. Oun si ni ọmọ ilẹ America akọkọ to gba bọọlu sinu àwọn ni aṣekagba idije FA Cup. Ṣugbọn Cesar Azpilicueta ṣe aṣiṣe, eyi to mu ki Arsenal o gba pẹnariti. Pierre-Emerick Aubameyang lo gba bọọlu wọle fun Arsenal, niṣe lo fi bọọlu ju goli si ibi ti ẹgbẹ kan. Oun naa lo si tun gba bọọlu keji wọle fun wọn ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa. Chelsea ti kọkọ gba kaadi yẹlo ni abala akọkọ, ti wọn si tun gba omiran laipẹ ti abala keji bẹrẹ. Ni bayii, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti yege lati kopa ni idije Europa.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-53624967
yor
sports
Lesotho vs Nigeria: Nàìjíríà lu Lesotho lu lálùbolẹ̀ mọ́lé wọn
Alubolẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Naijira, Super Eagles lu Lesotho mọle wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ere bọọlu ilẹ Afirika, 2021 AFCON qualifiers. Lesotho kọkọ ta biọbiọ lẹyin ti Masoabi Nkoto gbayo sawọn Naijiria lẹyin mọkanla ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Ṣugbọn a ju ara wa lọ bi ti ijankadi kọ o, Alex Iwobi lo dayo naa pada lẹyin iṣẹju mẹẹdogun tawọn Lesotho gbayo wọle Naijiria. Ko pẹ ko jina ni elege ara, Samuel Chukwueze fọba lee fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles. Ẹlẹsẹ ayo, Victor Osimhen eleyi tawọn Lesotho bẹru ki ifẹsẹwọnsẹ naa to bẹrẹ lo gba goolu ẹlẹẹkẹta wọle. Osimhen tun ṣe bẹẹ gbayo ẹkẹrim wọle ni Naijiria ba jawe olubori pẹlu ami ayo mẹrin si meji. 'Osimhen àti Aribo ni Lesotho bẹ̀rù jù nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà' Bi ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ti ṣetan lati koju Lesotho, akọnimọọgba Lesotho, Thabo Senong ti sọ pe ẹlẹsẹ ayo, Victor Osimhen ati Joe Aribo lawọn bẹru ju. Ẹgbẹ agbabọọlu Lesotho ti wọn n pe ni Crocodiles ta ọmi 1-1 pẹlu Sierra Leone l'Ọjọru ninu ifẹsẹwọnsẹ lati pegede fun idije 2021 AFCON. Akọnimọọgba Senong ni Lesotho ko gbọdọ fun Osihmen ati Aribo laye, ti wọn ba fẹ bori Naijiria. Senong ṣalaye pe ''Super Eagles ni awọn agbabọọlu to dantọ to to gbangba sun lọyẹ, amọ Lesotho le fagba han Naijiria ti wọn ba mura gidigidi.'' Akọnimọọgba Lesotho ni Osihmen ati Aribo ti fakọyọ fẹgbẹ agbabọọlu wọn loke okun, idi niyii ti fi gbọdọ mu wọn daadaa. Naijriria lo wa loke tente ni isọri ''L'' lẹyin ti wọn pokọ iya fun Benin pẹlu ami ayo meji sodo l'Ọjọbọ niluu Uyo. Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria lo gba ipo kẹta ninu idije 2019 AFCON ti waye lorilẹede Egypt.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-50452637
yor
sports
Báyìí ni àwọn alátìlẹ́yìn Super Eagles ṣe ń dá músò ṣáájú ìdíje tòní
Ẹgbẹ alatilẹyin ikọ Super Eagles lorilẹede Egypt n fi idunu wọn han pe ifẹsẹwọnsẹ oni yoo ṣẹnu 're fun Nàìjíríà.
https://www.bbc.com/yoruba/48891803
yor
sports
Kí ló pa dókítà àjọ FIFA tó kú níbí ìdíje Ghana vs Nigeria ní Abuja? Àjọ NFF sọ̀rọ̀
Ajọ bọọlu ni Naijiria, NFF ti fi ẹdun ọkan rẹ han lori iku oṣiṣẹ eto ilera kan, Dokita Joseph Kabungo, to ku lẹyin ifẹsẹwọnsẹ Ghana ati Naijiria nilu Abuja lọjọ Iṣẹgun. Ṣaaju iku rẹ, Dokita Kabungo to wa lati Zambia, wa lara awọn oṣiṣẹ ilera to ṣe ayẹwo fun awọn agbabọọlu lati mọ boya wọn lo oogun oloro. Atẹjade kan lati ẹka iroyin ajọ NFF sọ pe lootọ ni iku dokita naa jẹ ẹdun ọkan, ṣugbọn o ṣe pataki ki oun sọrọ lori nkan to fa iku rẹ. Ṣaaju ni iroyin ti n tàn kiri pe lasiko ti awọn ero iworan to jẹ ololufẹ Super Eagles ti Naijiria yawọ ori papa lati fẹhonu han nitori ifidirẹmi ẹgbẹ agbabọọ̀lu naa ni wọn lu oloogbe Kabungo pa. Awọn ero iworan naa wọ ori papa, ti wọn si bẹrẹ si ni ju oriṣiriṣi nkan mọ awọn agbabọọlu Super Eagles nitori wọn fi idi rẹmi. NFF ni dokita ajọ naa ti FIFA yan lati wa nibi ifẹsẹwọnsẹ naa, Dokita Onimisi Ozi Salami, sọ pe awọn kan lo ri oloogbe Kabungo nibi to ti n pọkaka iku, nitori ko le mi daadaa. Eyi lo waye nitosi yara ti ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede ghana ti n wọ aṣọ. "Awọn to ri oloogbe sọ nkan to n ṣẹlẹ fun mi. Mo si paṣẹ pe ki wọn o tete ma a gbe lọ sileewosan. "Ṣugbọn bi wọn ṣe n de ẹnu ọna ileewosan lo kú." Dokita Ozi Salami sọ fun awọn aawọn alaṣẹ ajọ NFF pe lasiko ti Dokita Kabungo fẹ ẹ lọ pe awọn agbabọọlu orilẹ-ede Ghana lati wa ṣe ayẹwo ni iṣẹlẹ naa waye. "Emi naa fẹ ẹ lọ pe awọn agbabọọlu Naijiria, ni ẹni to jẹ oludari eto gbogbo, Kabore Hubert Bosilong, lati South Africa, pe akiyesi mi si bi Dokita Kabungo ko ṣe le mí daadaa mọ lojiji." O ni iṣẹlẹ naa ṣoju oṣiṣẹ alaabo ajọ FIFA, Dixon Adol Okello lati Uganda. NFF sọ pe aisan ọkan ti wọn n pe ni 'heart attack' tabi 'cardiac arrest' lo pa oloogbe. Ọmọ orilẹ-ede Zambia ni Dokita Kabungo. Gbajumọ si ni pẹlu nitori pe gbogbo idije bọọlu ni orilẹ-ede Zambia lo ti ma n ṣiṣẹ gẹgẹ bi eleto ilera. Aarẹ ajọ bọọlu ni Zambia, Andrew Kamanga, ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi ọkan pataki ni lagbo bọọlu orilẹ-ede naa, paapaa bo sẹ wa lara ikọ to gba ife idije AFCON lọdun 2012.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-60931025
yor
sports
Mo yá $50k fún ìgbáradì ìdíje 2022 World Championships – Tobi Amusan
Tobi Amusan to gba ami ẹyẹ idije ere sisa ọlọgọrun mita (Women 100m hurdles) ti sọ iriri rẹ ati bo ṣe di alami ẹyẹ naa. Amusan, to sọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, ni oun gba ẹyawo to le ni ẹgbẹrun lọna aadọta Dọla ($50,000) lati ṣe igbaradi fun igbaradi idije ere sisa lagbaye (World Athletics Championship). Ọjọ Iṣẹgun ni wọn ṣe atunṣe si iye akoko to lo lati fi sare nigba akọkọ to lọ sare. Dipo iṣẹju aaya 12s. 06ms ti wọn kọ silẹ fun pe o lo nigba to kọkọ sare naa lati gba ami ẹyẹ, 12s.12ms ni wọn kọ silẹ fun bayii pe o lo lati fi sare naa, lati pari idije agbaye naa. Amusan lo di ọmọ Naijiria akọkọ yoo gba ami ẹyẹ lanti lanti naa, ti aarẹ Buhari si ti fun ni ami ẹyẹ idanimọ. Lasiko to n sọrọ nigba igbaradi rẹ, o ni oun ṣiṣẹ takun takun saaju idije naa. Amusan to fakọ yọ ni Oregon lo ni, oun saba ma n farapa nitori ere idaraya ti oun yan laayo. O ni nitori naa ni oun se gba ẹyawo lati ri pe ara oun duro kampe lati wa ni ipo to yẹ fun idije naa. "Bẹẹ ni mo n ṣèṣe ni ọpọlọpọ igba, ti mo si mọ pe ilera mi ku diẹ kaato. Ati wa loke tente ninu iṣẹ ti mo yan laayo nilo owo, nitori naa, ni mo se ya owo lati ri pe ilera mi wa nibamu, ki idije to bẹrẹ." Ọṣẹ to kọja ni aarẹ Buhari fun Tobi Amusan ni ami ẹyẹ Officer of the Order of the Niger (OON) ti orilẹede Naijiria. Ninu ọrọ rẹ, Amusan ni idunnu ati ayọ lo jẹ fun oun lati ri pe Aarẹ Buhari fun oun ni ami ẹyẹ naa ati pe oun gbe orukọ orilẹede Naijiria ga.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c2e18633m87o
yor
sports
Liverpool vs Chelsea: Ayé àkámarà! Liverpool laná ní Anfield, Chelsea pa òkúta sí gaàrí wọn
Ogun laye, ọmọ araye le! Ijamba mii tun ṣe ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lalẹ Ọjọbọ lẹyin ti Chelsea lu wọn mọle. Eyi ni igba ifẹsẹwọnsẹ karun un ti Liverpool yoo fidi rẹmi ninu rẹ ni papa iṣere wọn ni Anfield. Kete ti wọn bẹrẹ ere bọọlu naa ni Chelsea ti bẹrẹ si ni gbiyanju lati gba bọọlu sawọn Liverpool nigba ti Liverpool ko si le ta putu. Ẹlẹsẹ ayo, Timo Werner lo kọkọ gba goolu sawọn Liverpool nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun de iṣẹju mẹrinlelogun. Amọ, ẹrọ oloju aṣa VAR wọgile goolu naa pe o ti wọ ''off side'' ko to gba bọọlu sawọn. Ṣugbọn agbabọọlu aarin gbungbun, Mason Mount gba goolu miran wọle nigba ti ipele akọkọ ku iṣẹju mẹta ko pari. Liverpool gbiyanju titi lati da ayo naa pada ṣugbọn omi pọ ju ọka lọ fun wọn. Ni bayii, ipo keje ni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool wa lori tabili idije Premier League. Chelsea ti wa ni ipo kẹrin lẹyin ti wọn ko fidi rẹmi ninu ere bọọlu mẹwaa ti wọn ti gba lati igba ti Thomas Tuchel ti di akọnimọọgba wọn. Ẹwẹ, agbabọọlu Liverpool tẹlẹ ri, Jamie Carragher ti rọ ẹgbẹ agbabọọlu naa lati ra awọn agbabọọlu tuntun to dantọ. Carragher ni Liverpool nilo awọn agbabọọlu tuntun lati sọji pada.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-56289975
yor
sports
AFCON 2019 final: Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ Algeria là kìnìún Senegal mọ́ lẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì gba ife
Ikilọ kẹlẹgbẹ mẹgbẹ rẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Algeria fi ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije AFCON 2019 ṣe fun ikọ Senegal lẹyin ti wọn rọ ojo iya le wọn lori lẹẹkeji ti wọn si gba ife ẹyẹ AFCON mọ wọn lọwọ. Lẹyin iṣẹju meji pere ti ere bọọlu naa bẹrẹ ni ọkan lara awọn agbabọọlu Algeria, Baghdad Bounedjah gba goolu aramọnda kan wọ le, eyi to mu Algeria siwaju. Bo tilẹ jẹ pe ogbontarigi adilemu fun Senegal, kalidou koulibaly ko lanfani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun nitori o ti gba kaadi olomi ọsan(yellow card) meji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta, ikọ Senegal ṣi ja fitafita isbẹsibẹ. Ilumọọka agbabọọlu Liverpool, Sadio Mane ati awọn akẹgbẹ gbiyanju agbara wọn lori papa, ṣugbọn awọn agbabọọlu Algeria duro wamuwamu bi ologun ti wọn. Igba keji ree ti Algeria yoo gba ife ẹyẹ AFCON lẹyin ti wọn gbaa fun igba akọkọ lọdun 1990. Bakan naa, igba keji ree ti ẹgbẹ agbabọọlu Senegal yoo gba ipo keji(fadaka) ninu idije AFCON lẹyin ti wọn kọkọ gbaa lọdun 2002 nigba ti wọn gbalejo idije naa.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-49053293
yor
sports
English Premier league: Liverpool gun Chelsea bí ẹṣin lójúde rẹ̀ ní Stamford bridge
Awọn agba bọ wọn ni bi ale iya ẹni ba ju baba ẹni lọ, baba laa pe. Bẹẹ lọrọ ri fun Chelsea nigba ti wọn gbalejo Liverpool ni ifẹsẹwọnsẹ kẹfa, saa idije liigi ti ọdun yii ni ilẹ Gẹẹsi. Trent Alexander-Arnold lo kọkọ gba goolu wọle fun Liverpool nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinla ki Roberto Firmino to dee lade funwọn. Amọṣa lẹyin ọpọlọpọ jija raburabu, Ngolo Kante da ẹyọ kan pada fun Chelsea. Gbogbo akitiyan atamatase Chelsea, Tammy Abraham lati yọ ikọ rẹ jade ninu ọfin Liverpool lo ja si pabo. Pẹlu esi yii, ifẹsẹwọnsẹ meji pere ni Chelsea ṣi bori ninu mẹfa ti wọn ti gba ninu liigi saa yi labẹ akoso olukọni wọn tuntun, Frank Lampard. Esi yii si n fi Liverpool silẹ loke tente tabili liigi ilẹ Gẹẹsi. Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti gba, Liverpool nikan ni ko tii padanu ifẹsẹwọnsẹ kankan bayii.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49786168
yor
sports
NGA vs RSA: 'Bode Thomas' àti àwọn àṣà mííràn tó jẹyọ nínú ìdíje AFCON
Igbakiigba ti ọrọ ba ti pa Naijiria ati South Afrika pọ,bi igba pe wọn jọ fẹ doju ija kọ ara wọn ni o maa n jẹ. Lori papa ere bọọlu papa julọ, wọn kii fi oju ọrẹ wo ara wọn tabi ọmọ ilẹ adulawọ kanna. Awọn mejeeji fi ifigagbagba yi han nigba ti Naijiria ati South Afrika pade ninu idije AFCON 2019 Naijiria bori South Afrika pẹlu ami ayo meji sookan ti o si tumọ si pe wọn yoo tẹ siwaju lọ abala to kangun si aṣekagba. Loju opo Twitter ati Facebook, iroyin aṣeyọri Naijiria ti mu ki awọn ọmọ ile naa ati awọn akẹgbẹ wọn lati South Afrika ma fọrọwerọ. Nibi ọrọ yi ni awọn aṣa kan ti jẹyo eleyi ti o gba ori ayelujara kan. Ọmọ Yoruba to ba n gbe ilu Eko yoo ti gbọ orukọ Bode Thomas ri. Opopona kan nilu Eko lo n jẹ Bode Thomas lagbegbe Surulere amọ lẹyin ti Naijiria fi ẹyin South Afrika janlẹ, o gba itumọ miiran Lati oju opo Twitter, diẹ lara awọn itunmọ tuntun ti awọn eeyan fun orukọ yi re e: Lotitọ ati ododo, ọtọ ni nnkan ti olorin to kọrin rẹ jẹjẹ sọ ninu orin ti awọn ọmọ Naijiria yi itumọ rẹ pada si Bode Thomas. T'oun ti pe wọn mọ itunmọ rẹ, awọn ọmọ Naijiria ni ko kan awọn nitoripe asiko ree fawọn lati fi South Afrika ṣe yẹyẹ. Idẹyẹ si awọn ọmọ Naijiria lati ọwọ awọn eeyan South Afrika kan ko jẹ tuntun mọ. Amọ bayii ti Naijiria ti gbewuro soju South Afrika, nnkan ti yi pada ti awọn ọmọ Naijiria si ni asiko to bayi ki awọn naa ṣe idẹyẹ si sawọn ọmọ Naijiria. Samuel Chukwueze ẹlẹsẹ ayo to ge awọn ọmọ South Afrika lori papa ni wọn ni o n bawọn deye si South Afrika pada Ossai Joshua tilẹ ni Super Eagles fi aṣeyọri wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ naa jẹ ogede South Afrika ni. Lakotan gbogbo awọn nkan ti awọn eeyan n sọ ko ju ere lọ irufẹ eleyi ti o ma n waye laarin awọn alatilẹyin ere boolu jakejado agbaye.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-48946704
yor
sports
Nigeria Basketball: Buhari yọ ikọ̀ D'Tiger, D'Tigress kúrò nídíje bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ lágbáyé fún ọdún méjì, ohun tó fàá nìyí
Ijọba apapọ Naijiria ti pinnu lati yọ ikọ agbabọọlu alapẹrẹ, (Basket ball) Naijiria ko gbọdọ kopa ni idije agbaye kankan fun ọdun meji Bakan naa nijọba tun fẹ tu ajọ bọọlu alapẹrẹ NBBF ka nitori wahala adari to n suyọ nibẹ. Ileeṣẹ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ lorilẹede Naijiria lo paṣẹ yii ti aarẹ Muhaamadu Buhari si buwọlu u. Lẹta kan ti ileeṣẹ ere idaraya ijọba apapọ Naijiria kọ ṣalaye ohun top ṣokunfa igbesẹ naa. O ni pe wọn yọ ọwọ awọn ikọ ọkunrin ati obinrin agbabọọlu apẹrẹ naa kuro lawọn idije bọọlu alapẹrẹ lagbaye nitori"oniruuru wahala ati awuyewuye to n waye eyi to ti "fẹrẹ sọ ere idaraya bọọlu alapẹrẹ di ẹdunarinlẹ" ni Naijiria. "Eyi yoo fun Naijiria laaye lati tun ile rẹ to lẹka bọọlu alapẹrẹ bẹrẹ lati ẹsẹ kuku titi kan awọn liigi abẹle rẹ gbogbo. Ohun to han si BBC ni pe wọn gbe igbesẹ yii lati dena ipinnu awọn agbabọọlu apẹrẹ Naijiria lati wọde lawọn idije agbaye kan tako ajọ naa ati ijọba. Bakan naa ni inu awọn alakoso ileeṣẹ ere idaraya ni Naijiria ko dun si bi awọn agbabọọlu alapẹrẹ ṣe n da siedeaiyede to n waye laarin awọn adari lajọ ere bọọlu alapẹrẹ Naijiria ti wọn si n gbe lẹyin igun kan ninu edeaiyede naa. Labẹ ofin ajọ ere bọọlu alapẹrẹ lagbaye, FIBA, ajọ naa koro a maa koro oju si awọn orilẹede yoowu ti ijọba ba ti n da si ọrọ iṣakoso awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ nibẹ. Igbesẹ ti ijọba orilẹede Naijiria gbe yii lee mu ki ajọ FIBA gbegile orilẹede Naijiria lagbo ere idaraya bọọlu alapẹrẹ lagbaye- eyi si lee tumọ̀ si pe aikọ agbabọọlu alapẹrẹ orilẹede Naijiria, awọn ẹgbẹ agbabọọ̀lu alapẹrẹ gbogbo atawọn oṣiṣẹ rẹ gbogbo ko ni lanfani si awọn idije agbaye gbogbo ati ipade wọn. BBC ti kan si ajọ FIBA fun alaye lori eyi. Itumọ eyi ni pe ikọ agbabọọlu alapẹrẹ obinrin Naijiria ko ni lee kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye fawọn obinrin agbabọọlu alapẹrẹ ti yoo waye lorilẹede Australia loṣu kẹsan an ọdun 2022. Kan lara awọn agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, Upe Atosu ni ibanujẹ ọkan nla ni igbesẹ naa jẹ fun wọn ati pe o yẹ ki ijọba atawọn alaṣẹ ere idaraya ni Naijiria o mọ pe ere idaraya kii ṣe ayo ọlọpọn ti eeyan a daaru ki o to tun un to. "Ọna to dara julọ lati yanju ọrọ yii kọ niyi." Awuyewuye eto idibo sipo awọn alakoso ajọ ere bọọlu alapẹrẹ orilẹede Naijiria, NBBF to waye lọdun mẹfa sẹyin lo ṣokunfa wahala laarin awọn alakoso nibẹ. Lọpọ igba si ni wahala ti fẹrẹ da igbaradi awọn agbabọọlu alapẹrẹ naa fun awọn idje agbaye gbogbo ati liigi rẹ labẹle ru. Wahala naa tun ṣe akoba fun owo oṣu akọnimọọgba ikọ obinrin agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, Otis Hugley to ko ikọ naa lọ kopa fun ati pegede fun ere idaraya agbaye Tokyo 2020, ife ẹyẹ ilẹ adulawọ fawọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ ati ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2022 titi kan bibori France pẹlu. Bakan naa lawọn agbabọọlu alapẹrẹ lobinrin pẹlu n waako pẹlu ajọ to n ṣakoso ere bọọlu alapẹrẹ ni Naijiria, NBBF ati ileeṣẹ ere idaraya lori kikuna lati san owo ajẹmọnu wọn tawọn wahala to nii ṣe pẹlu iṣakoso ikọ naa lasiko ti wọn lọ kopa ni idije Olimpiiki lorilẹede Japan.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61433893
yor
sports
Tọkọtaya wọ “jẹsí” Messi àti Mbappe lọ́jọ́ ìgbéyàwó
Onírúurú àrà ni àwọn olólùfẹ́ eré ìdárayá máa ń dá tí ọ̀rọ̀ bá di ti ẹni tí wọ́n ń fẹ́ràn pàápàá lágbo eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò kí ń lè pa ìdúnnú wọn mọ́ra nígbà tí ọ̀rọ̀ eré bọ́ọ̀lù bá dá lórí agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n bá  fẹ́ràn jùlọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lọ̀rọ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kerala, níbi tí àwọn olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá pọ̀ sí jùlọ ní orílẹ̀ èdè India. Ní India, eré ìdárayá Cricket ló gbajúmọ̀ jùlọ, tí àwọn ibẹ̀ sì máa ń ṣe àtìlẹyìn fún àmọ́ àrà ọ̀tọ̀ ni ìfẹ́ tí àwọn ará ìpínlẹ̀ yìí ní sí eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá. Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2022 tí àṣekágbá ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé wáyé láàárín orílẹ̀ èdè Argentina àti France, àwọn ará ìpínlẹ̀ náà gbáradì láti wo ìdíje náà dáradára. Àmọ́ ohun kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ni tí àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó ní ọjọ́ àṣekágbá ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé yìí. Bí ìmọ̀ àwọn tọkọtaya náà ṣe jọ lórí gbogbo nǹkan tí wọ́n máa lò ní ọjọ́ ìgbéyàwó wọn, ó dàbí wí pé ẹnu wọn kò kò lórí orílẹ̀ èdè tí wọ́n jọ máa ṣe àtìlẹyìn fún. Sachin R tó jẹ́ ọkọ ìyàwó ló jẹ́ alátìlẹyìn Messi ti orílẹ̀ èdè Argentina nígbà tí ìyàwó rẹ̀ sì ń ṣe àtìlẹyìn fún orílẹ̀ èdè France láti gbégbá orókè níbi ìdíje náà. Èyí ló mú àwọn tọkọtaya náà wọ “jẹsí” lórí aṣọ tí wọ́n fi ṣe ìgbéyàwó wọn níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà tó wáyé ní ìlú Kochi láti fi ìfẹ́ wọn sí eré ìdárayá náà hàn. Athira tó jẹ́ ìyàwó wọ “jẹsí Mbappe láti fi ìfẹ́ rẹ̀ sí France hàn nígbà tí ọkọ rẹ̀ Sachin wọ “jẹsí” Messi láti ṣàtìlẹyìn fún Argentina. Ìwé ìròyìn Malayala Manorama jábọ̀ pé ní kíákíá ni àwọn tọkọtaya náà kúrò níbi tí wẹ̀jẹwẹ̀mu ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn ti ń wáyé láti lọ wó àṣekágbá eré bọ́ọ̀lù náà. Ìpínlẹ̀ Kerala gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ ni ayẹyẹ lọ́kan-ò-jọ̀kan ṣì ń wáyé níbẹ̀ nítorí Messi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ń ṣe àtìlẹyìn fún.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c2lqel4gnwko
yor
sports
Jurgen Klopp: Akọ́nimọ̀ọ́gbá Liverpool tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn tuntun tí yóò múu wà nípò di ọdún 2026
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, ti buwọlu adehun afikun ọlọọdun meji kun adehun rẹ to wa nilẹ tẹlẹ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu naa. Lọdun 2024 lo yẹ ki adehun rẹ to wa nilẹ tẹlẹ pari, ṣugbọn adehun tuntun to fọwọsi bayii ti sun un di ọdun 2026 bayii. Ni ọdun 2015 ni Klopp darapọ mọ Liverpool ki o to sọ ọ bi ẹna loṣu kẹta ọdun 2022 pe o ṣeeṣe ki oun gba isinmi kuro lẹnu iṣẹ akọnimọọgba lasiko ti saa adehun oun ba pari lọdun 2024. Ife ẹyẹ marun ni Klopp ti gba pẹlu Liverpool lati igba to ti dara pọ mọ wọn. Nigba to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu naa lọdun 2015, Klopp ṣeleri ati mu idunnu wa fawọn ololufẹ agbabọọlu naa lati mu wọn di ẹni to ni igbagbọ to jinlẹ ninu ilepa ikọ agbabọọlu naa lati ṣe aṣeyọri. Nigba naa, Liverpool ko tii gba ife ẹyẹ liigi ilẹ Gẹẹsi lati ọdun 1990. Klopp ko ikọ naa sodi gba ife ẹyẹ Champions League Yuroopu ni saa liigi ọdun 2018 si 2019 ki o to ko wọn sodi gba ife ẹyẹ liigi lọdun 2020. Nigba to n buwọlu adehun tuntun naa, Klopp ni "inu oun dun, ayọ oun kun, oun si rii gẹgẹ bi anfani nlanla" Klopp fi kun un pe " Nigba tawọn to ni ẹgbẹ agbabọọlu naa mu aba adehun tuntun tọ mi wa, mo bi ara mi leere ibeere ti mo maa n beere ni gbangba lọpọ igba. Ṣe mo ni agbara ati okun lati ṣiṣẹ naa lẹẹkansi lati ṣe awọn ohun ti ẹgbẹ agbabọọlu to dara yii nilo latọdọ ẹni to di ipo akọnimọọgba mu?" "Ko gba mi lọpọ akoko lati ri idahun sii..ifẹ ibi yii ti gba ọkan mi." Bakan naa lawọn amugbalẹgbẹ rẹ, Pep Lijnders ati Peter Krawietz naa ti tọwọ bọ iwe adehun tuntun pẹlu.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61265210
yor
sports
AFCON 2021: Orílẹ̀-èdè Cameroon tí yóò gbàlejò ìdíje nàá yí ọjọ́ padà
Cameroon Football Federation (Fecafoot) don announce say 2021 Africa Cup of Nations go happun for January 9. Ajọ to n mojuto bọọlu afẹsẹgba ni Cameroon (Fecafoot) ti kede pe ọjọ kẹsan, oṣu Kinni ni idije Africa Cup of Nations yoo bẹrẹ l'ọdun 2021. Oṣu Kẹfa ati Ikeje loyẹ ki idije naa waye, ṣugbọn ajọ Fecafoot sọ pe ayipada naa waye nitori bi oju ọjọ ṣe maa n ri ni orilẹ-ede naa ni akoko ti wọn n ṣe e. Awọn alaṣẹ ajọ naa ṣe ipade pẹlu awọn aṣoju ajọ Confederation of African Football (CaF), to n mojuto bọọlu gbigba ni Africa l'Ọjọru nilu Yaounde. "Ajọ Fecafoot fi si ori ayelujara pe "ọjọ kẹsan an, oṣu Kinni si ọjọ Kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2021 ni wsn yoo gba idije AFCON 2021". Ayipada yii tun tumọ si pe idije naa ko ni i waye ni asiko kan na pẹlu idije Club World Cup ti yoo waye ni China l'oṣu Kẹfa, ọdun 2021. Ajọ Caf ṣalaye pe ayipada naa waye nitori pe Cameroon beere fun un. Ṣugbọn ṣa, o ṣeeṣe ki idije AFCON 2021 ni ipa lara idije Champions League nitori awọn agbabọọlu ilẹ Africa bi i Sadio Mane, Mohammed Salah, ati awọn miran to le fẹ gba bọọlu fun orilẹ-ede wọn.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-51128360
yor
sports
Anthony Joshua kékeré: Mo fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ́ gbé mi lọ sí òkè okun - Tijani Azeez
Ọmọ ọdun mẹrinla abẹṣẹkubiojo ni Tijani Azeez to si jẹ akẹkọọ ni ile iwe ati ni ile ẹk to ti n kọ ẹṣẹ jija. "Ti mo ba lọ ileewe laarọ, ti mo de ni ago mẹrin, maa tun bẹrẹ si ni kọ ẹkọ ẹṣẹ di ago meje alẹ". Lati ọmọ ọdun meji ni ọmọ ọdun mẹrinla yii ni oun ti bẹrẹ ẹṣẹ jija toripe baba rẹ gan lo si ọna yii. Gbogbo igba ni inu Tijani maa n dun si ohun to fẹran lati maa ṣe yii to bẹẹ to jẹ wipe iye ọjọ ati wakati to fi n kọ ẹṣẹ jija laarin ọsẹ kan ko lonka rara. Olukọni to n kọ tijani bo ṣe n ja ẹṣẹ jẹ onimọ to ti n kọ ẹṣẹ lati ọdun 2003 koda o wu oun gan ki ọmọ to bi funrarẹ maa ja ẹṣẹ. Ọpọlọpọ ọrọ iwuri lo sọ nipa Tijani azeez.
https://www.bbc.com/yoruba/56369878
yor
sports
Ronaldo Brazil làgbà gbogbo agbábọ́ọ̀lù, kì í ṣẹgbẹ́ ẹ Messi àti Ronaldo- Roberto Carlos
Agbabọọlu Real Madrid tẹlẹ ri, Roberto Carlos ti sọ pe ẹlẹsẹ ayo, Ronaldo Nazario Delima pegede ju Lionel Messi ati Cristiano Ronaldo lọ nigba to si fi n gba bọọlu. Ronaldo Delima gba gbajugbaja ami ẹyẹ Ballon d'Or lẹẹmeji, o si tun gba ife ẹyẹ agbaye lọdun 1994 ati 2002. Ṣugbọn ifarapa leralera lori ookun rẹ ko jẹ ko le gba bọọlu pẹ. Amọ, o pitu meje tawọn ọdẹ n pa ninu igbo nigba to fi n ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ati Barcelona lorilẹ-ede Spain. Carlos ni lootọọ ni Messi ati Ronaldo n tii fi bọọlu dara, fun bi ọdun mẹẹdogun bayii, o ni Ronaldo Delima si ni baba wọn. Carlos to jẹ akẹgbẹ rẹ ni Real Madrid ati Brazil jẹri wi pe o nira fawọn ẹlẹsẹ ayo lati gba bọọlu sawọn nigba naa ju akoko yii lọ nitori iyatọ ti ba ofin ere bọọlu nisin yii.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-52754773
yor
sports
Suzzanne Wenger: Obìnrin òyìnbó tó mọ ojú òrìṣà Osun ju ọmọ Yorùbá lọ
Ni ilẹ kaarọ oojiire, ẹsin ibilẹ tabi iṣẹṣe rinlẹ lati atijọ, ohun si lo jẹ ẹsin abalaye tawọn baba nla wa tẹwọgba lati fi maa sin Olodumare. Amọ, nigba ti awọn oyinbo alawọ funfun de, ẹya Yoruba fi ẹsin abalaye silẹ, ti wọn si tẹwọgba ẹsin Kristiẹni ati ti Musulumi. Ẹtahoro ọmọ Yoruba lo ku to n gbe awọn orisa abalaye ga, ti wọn si n se ẹsin ibilẹ. Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: Idi si ree to se jẹ ohun iyalẹnu lati ri obinrin oyinbo to n kara mọ aasiki ẹsin ibilẹ ju awa alawọ dudu gan an lọ. Orukọ obinrin naa ni Suzzane Wenger, to wa lati ilu oyinbo, ti kii si fi ọkankan ninu awọn orisa ilẹ Yoruba sere. Gẹgẹ bi oju opo Wikipedia to wa lori itakun agbaye ti slaye, ipa kekere kọ ni Suzzane Wenger, ti ọpọ mọ si Adunni Olorisa ko, lati ri pe ẹsin abalaye wa ko parun nilẹ Yoruba. Adunni Olorisa jẹ agbẹgilere, to si maa n fi igi da ara to ba wu, eyi to mu ko rọrun fun lati gbẹ ere nipa oniruuru orisa to wa nilẹ Yoruba. Bi itan aye obinrin naa si se lọ ree ati ipa manigbagbe to ko nidi agbega asa ati orisa ilẹ Kaarọ Oojire Ọjọ Kẹrin, osu keje, ọdun 1915 ni wọn bi Suzzanne Wenger sile aye, lasiko ogun agbaye akọkọ. Ilu Graz, lorilẹ-ede Guusu Austria si ni wọn bi obinrin naa si, sinu idile ẹlẹsin Kristẹni, amọ, o nifẹ gbogbo ohun to ba jẹ ti isẹda tabi adayeba. Eyi lo mu ki Suzzanne lọ kọ nipa isẹ ọna, paapaa ba se n gbẹ igi ni ere, to si lọ yika awọn ilu nla nla lati mọ nipa isẹ naa, to si tun n ta awọn ọja to ba fi igi se. Nitori ifẹ si isẹ ọna to ni, lara awọn ilẹ to ti sisẹ ọna naa ni Vienna, Italy, Switzerland ati Paris, lorilẹ-ede Faranse. Ilu Paris si ni Suzzanne wa, to fi se alabapade ọkọ rẹ akọkọ, Ulli Beier ẹni to sẹsẹ ri isẹ olukọ lọgba fasiti Ibadan. Ulli Bier ati Suzzanne Wenger se igbeyawo nilu London lọdun 1949, eyi to mu ko rọrun fun wọn lati dijọ wa silẹ Naijiria bii tọkọ taya. Nigba to di ọdun 1950, awọn tọkọ-taya yii lọ tẹdo silu Ede nitori wọn n wa ayika to kun fun ohun isẹda lati maa gbe. Bawo ni Suzzanne Wenger se gba ẹsin iṣẹṣe? Suzzanne Wenger ko saadede tẹwọ gba orisa ibilẹ amọ aisan nla kan lo deede gbe e ṣanlẹ laarin ọdun kan ti oun ati ọkọ rẹ wọ Naijiria, ti wọn si tẹdo si ilu Ibadan. Lọ́dun 1950 yii ni arun ikọ ife da a wolẹ, bẹẹ ni ko si dokita oyinbo kankan larọwọto lati se itọju rẹ, to si n ku lọ bi ọjọ ti n gori ọjọ. Asiko yii ni awọn olorisa dide, ti wọn si n se itọju obinrin yii pẹlu agbo, egboogi, ewe ati egbo titi ti ara rẹ fi da, to si bọ lọwọ arun asekupani naa. Lati igba naa, ni Suzzanne ti fi aye rẹ fun awọn orisa, ti ko si boju wẹyin mọ, bẹẹ lo si mu ẹsin bibọ orisa ni ọkunkundun, to si gba a gbọ titi di ọjọ iku rẹ. Asiko yii si lo salabapade orisa Obatala ati Alagemo, to si nifẹ pupọ si ọna ti wọn n gba bọ awọn orisa yii ati gbogbo ohun to jẹ mọ. Bi o tilẹ jẹ pe Suzzanne ko gbọ ede Yoruba, sibẹ eyi ko se idiwọ fun un lati maa kọ nipa ilana irubọ ati etutu awọn orisa yii, to si di ọrẹ awọn olorisa naa. Suzzanne yi orukọ rẹ pada kuro ni ti oyinbo, awọn olorisa si sọ ọ ni orukọ abisọ nilana ẹsin abalaye. Orukọ rẹ tuntun ni Iwinfunmi Adunni Olorisa, Ọba Samuel Adeleye Adenle, Ataoja tilu Osogbo si lo fun un ni orukọ naa. Adunni ati ọkọ rẹ tun lọ silu Osogbo lati tẹdo si, ibẹ si ni wọn ti tuka gẹgẹ bi tọkọ-taya. Obinrin oyinbo naa n tẹsiwaju pẹlu orisa bibọ, to si n kọ ẹkọ lojoojumọ nipa ilana ẹsin abalaye. Adunni tun dan igbeyawo wo lẹẹkan si, to si tun se igbeyawo pẹlu ọkọ keji, tii se onilu ibilẹ lọdun 1959. Orukọ onilu naa ni Oloye Ayansola Oniru Alarape, toun naa ti di oloogbe bayii. Amọ igbeyawo naa ko tun tọjọ, ti wọn fi tuka, ti Adunni si da wa titi opin aye rẹ lai sopo fẹ ọkọ kankan mọ, amọ to fi awọn orisa se ọkọ. Adunni ko tẹwọ gba orisa kan soso ni pato amọ o gba ilana ẹsin ibilẹ, gbogbo ọna si lo n gba gbe awọn ẹsin abalaye yii larugẹ. Oniruuru ere ni Adunni fi igi gbẹ lati safihan awọn orisa ilẹ Yoruba, to si n fi owo, ara ati isẹ ọwọ gbe oẹsin abalaye tilẹ Yoruba larugẹ. Gbogbo awọn ẹlẹsin Kristiẹni ati ti Musulumi lo n se ariwisi si obinrin oyinbo yii pe se lo tun n se agbende ati agbega iwa ibọrisa, eyi to ti n lọ sokun igbagbe. Amọ, gbogbo ariwisi wọn ni ko tu irun kankan lara Adunni, to si n tẹsiwaju lati maa fọn rere pe ajọsepọ wa laarin awọn ẹsin mẹtẹẹta, ko si iyatọ. Awọn ohun meremere ti Adunni Olorisa se nidi agbega osiṣa nigba aye rẹ Kíni ìdí ti àwọn ọmọ ogun fi n ṣọ́ àwọn Imaam ni Mecca? Mọ̀ sií i nípa Oba Yesufu Asanike , Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo August Agboola Brownie, ọmọ Yorùbá tí wọ́n n wárí fún ní Poland Aadọta ọdun gbako ni Adunni Olorisa lo pẹlu iran Yoruba ko to filẹ bora. Ọjọ ni ọjọ Aje, ọjọ kejila, osu Kinni, ọdun 2009, ti Aduuni Olorisa dakẹ, to si ki aye pe o digbose se nile iwosan Aguda ti Fatimah to wa nilu Osogbo. Gbogbo ọmọ mẹẹdogun ti obinrin oyinbo tọ yii si gba tọ ọ lo wa ni ẹba ibusun rẹ lasiko to mi kanlẹ. Lara awọn ọmọ ti Adunni gba tọ ni Yinka Davies Okundaye ti ọpọ eeyan mọ si Nikky Afirikana, ẹni toun naa gbajumọ nidi isẹ ọna ati asọ Adire sise. Ọmọ ọdun mẹfa ni Yinka wa nigba to di ọmọ orukan, ti Adunni si gba lati ma a tọju rẹ gẹgẹ bii ọmọ bibi inu rẹ. Ko si to jade laye ni Adunni ti fi ọrọ silẹ pe wọn ko gbọdọ gbe oku oun sinu yinyin ni ibudo igbokusi tabi se inawo alarinrin lati se oku oun. Ọpọ eeyan to si gbọ nipa iku akikanju obinrin iya olorisa yii lo ni kii se pe o ku, o sun ni lati di ọkan lara orisa ti iran Yoruba ko ni le gbagbe laelae. Bakan naa ni awọn ọmọ rẹ fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn sin Adunni nilana ẹsin isẹse amọ ko si ẹni to ge ẹya ara rẹ kankan, lodi si ahesọ ọrọ tawọn kan n sọ kiri. Adunni Olorisa ti waye, o si ti lọ mọ ipa manigbagbe to ko nidi agbega asa ilẹ Yoruba ko le parẹ laelae. Lara awọn ẹkọ naa ni pe ko yẹ ka maa fi ọwọ rọ oun adayeba wa sẹyin nitori ọmọ ale nii fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ. Bakan naa ni itan igbe aye Adunni kọ wa pe ka maa se anu nipa gbigbe ori awọn ọmọde sori soke boya ọba oke fun wa ni ọmọ abi bẹẹ kọ. Itan yii tun kọ wa pe ka maa se amulo awọn ohun isẹse wa bii egboogi, agbo, ewe ati egbo nitori iwulo tiwọn naa wa, eyi to ti n lọ sokun igbagbe bayii.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56670376
yor
sports
Arsenal rántí "Invincibles," ó pé ọdún mẹ́rìndínlógún tí Arsenal gba ife Premier League
O ti pe ọdun mẹrindinlogun bayii ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gba ife ẹyẹ Premier League lai fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan ni saa bọọlu ọdun 2003/2004. Nigba naa si ni Arsenal gba ife ẹyẹ idije Premier League kẹyin. Arsene Wenger ni akọnimọọgba ikọ Arsenal nigba naa. Patrick Vieira ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu ikọ naa ninu eyi tawọn agbaọjẹ agbabọọlu bi Thierry Henry, Robert Pires, Dennis Beckamp, Sol Campbell, Arshley Cole ati Kanu Nwankwo wa. Ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọta ni Arsenal gba lai padanu ọkankan ninu wọn. Lori ifẹsẹwọnsẹ aadọta ni wọn de ki ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United to fẹyin wọn gbolẹ ti wọn si da wọn duro. O ṣeeṣe ki idije Premier League bẹrẹ pada laipẹ, lẹyin ti o ti wa ni idaduro lati inu oṣu kẹta nitori ajakalẹ aarun coronavirus. Ajọ UEFA ti fawọn alaṣẹ idije naa atawọn idije liigi bọọlu mii kaakiri ilẹ Yuropu di ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu karun un lati ṣeto igba ti wọn fẹ bẹrẹ saa bọọlu yii pada. Awọn alaṣẹ Premier League fẹ bẹrẹ liigi ọhun pada lọjọ kẹjọ oṣu kẹfa, eyi ti wọn fẹ ko pari ninu oṣu keje ọdun yii.Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Tottenham, West Ham ati Brighton ti ṣi papa iṣere wọn fawọn agbabọọlu wọ lati ma ṣe igbaradi ọlọdanni.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-52459695
yor
sports
Premier league: Ìjà orogún London, Arsenal ati Tottenham ranjú mọ ara wọn, ṣùgbọn iná ojú wọn kò ran tábà
Diẹ lo ku ki omi tẹyin wọ igbin Arsenal lẹnu loni nibi ifẹsẹwọnsẹ awọn ati orogun wọn ni ilu Londọn, iyẹn Tottenham. Tottenham ko fi ojuure wo Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu bi wọn ṣe side iya fun Arsenal ni iṣẹju kẹwa ifẹsẹwọnsẹ naa lati ẹsẹ Eriksen. Ogoji iṣẹju ni Harry Kane, balogun ikọ Tottenham ba tun gba ọkan si. Ẹgbé agbábóólù orílẹ-èdè Naìjíríà gba ẹbuǹ wúrà ilẹ Afrika Van Dijk gbadé UEFA mọ́ Messi àti Ronaldo lọ́wọ́ Liverpool kun Arsenal wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bí ẹran àsun 'lójúbọ' Anfield Ikú dóró! Agbábọ́ọ̀lù Super Falcons tẹ́lẹ̀, Chiejine jáde láyé lẹ́ni ọdún 36 Wo àwọn eléré ìdárayá mẹ́ta tí àjọ FIFA ti fòfin dè títí ayé Amọṣa, ṣe awọn agba bọ wọn ni bi ẹṣin ba da ni aa tuu gun ni. Ki ifẹsẹwọnsẹ naa to wọ isinmi fun saa akọkọ ni Lacazette, atamatase Arsenal da ọka pada ninu rẹ. Arsenal jẹwọ ọmọ ọkọ fun Tottenham ni abala ikeji ifẹsẹwọnsẹ naa ṣugbọn pẹlu gbogbo kirakita wọn, goolu kan ṣoṣo ti Aubameyang gba wọle nikan ni wọn ri dimu eyi to ko wọn yọ ninu itiju naa. Ori lo ko Tottenham pẹlu yọ lọwọ ogun atẹyinja ṣugbọn ṣa wọn sun iya ta lagba niluu London di ọjọ mii, ọjọọ re. Bi ọrọ orogun adedigba ni ifẹsẹwọnsẹ laarin Arsenal ati Tottenham maa n jẹ nitori ifigagbaga awọn mejeeji lori mimọ tani alagbara ẹkun ariwa ilu London, eyi ti a ms si North London. Ireti ọpọ lori ifẹsẹwọnsẹ naa ko kuku ja sofo nitori bi ajere lo ṣe gbona janjan ṣugbọn lẹyin o rẹyin. Ninu awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹfa to maa n du ipo mẹrin akọkọ lori atẹ igbelewọn liigi ilẹ Gẹẹsi, iyẹn Manchester city, Liverpool, Arsenal, Manchester United, Chelsea ati Tottenham, Manchester city pẹlu Liverpool nikan lo bori ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn lopin ọsẹ yii, ọmi ni Manchester United ati Chelsea ta ninu ifẹsẹwọnsẹ tiwọn to waye lọjọ satide.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49541047
yor
sports
FIFAWWC: Ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ Germany ati Naijiria ti parí pẹ̀lú àmi ayò ìbànújẹ́ mẹ́ta
Ikọ Germany ati Super Falcons Naijiria wako ni France ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti awọn obinrin to n lọ lọwọ ni ọjọ Abamẹta, ṣugbọn lẹyin ò rẹyin, Germany fi agba han Naijiria pẹlu ami ayo mẹta si odo. Lẹyin ogun iṣeju, ikọ Germany fun Naijiria ni ami ayo kan. Ṣugbọn iṣeju marun lẹyin rẹ, wọn tun fun wọn ni wo-mi-n-gba-si-ọ, to sọ ami ayo naa di meji. Pẹlú iṣẹju mẹjọ si ipari ifẹsẹwọnsẹ naa, wọn tun ti fi ikẹta lee. Bayii ipele ko mẹsẹ o yọ ni idije ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin FIFA de duro. Orilẹ-ede Germany lo ṣaaju ninu ẹgbẹ B nitori wọn bori ninu idije mẹta wọn nigba ti Naijiria bori ninu idije kan to sọ wọn di alaṣeyọri kẹta ni ẹgbẹ A. Igba akọkọ laarin ogun ọdun ni yii, ti Naijiria a de ipele ikẹrindinlogun ninu idije ife ẹyẹ agbayeSuper Falcons gòkè odò bọ́ sípele ìkẹrìndínlógún ní France. Agbabọọlu Naijiria ni ikejidinlogoji to dara julọ ni agbaye. Lara awọn to maa gba bọọlu fun Naijiria ni Osinachi Ohale, Onome Obi, Rita Chikwelu, Francisca, Desire Oparanozie atawọn mii. Asisat Oshoala ni yoo ṣaaju awọn ẹlẹsẹ ayo ninu idije naa. Ta ni Germany ti Naijiria n koju? Awọn agbabọọlu orilẹ-ede Germany ni ikeji to dara julọ ni gbogbo agbaye. Germany lo gbalejo idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 2011. Awọn ni wọn bori ninu idije wọn pẹlu orilẹ-ede USA to dara julọ ni agbaye lọdun 2011. Awọn agbabọọlu mẹfa lo ku ninu awọn mejidinlọgbọn ti wọn ṣoju orilẹ-ede wọn nigba naa. Alexandra Popp lo ku ninu awọn agbabọọlu naa to maa koju Naijiria. Alexandra yoo gba bọọlu fun igba ọgọrun un ti Germany ba koju Naijiria loni. Orilẹ-ede Germany ti gba ife ẹyẹ agbaye tawọn obinrin lọdun 2003 ati 2007. Nigba ti wọn gbe ipo keji ni ọdun 1995. Ipo kẹrin ni Germany gbe lọdun 1991 ati 2015. Ileri Super Falcons fun awọn ọmọ Naijiria: Nitootọ ni ọpọ gba pe Germany kii ṣe ẹran rirọ fun Naijiria ṣugbọn awọn agbabọọlu Naijiria ni awọn a gbiyanju lati bori. Onome Ebi, ọkan lara awọn agbabọọlu ti oju wa lara rẹ ni awọn sa ipa awọn ninu idije pẹlu France ko to di pe wọn gba ami ayo kan sile Naijiria ninu kọju si mi koo gbaa sile. O ni Naijiria ko wa ta guguru ni France, a maa bọ si ipele to kan lagbara Olorun ni.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-48729463
yor
sports
Mike Tyson Canabis ambassador: Malawi kọ lẹ́tà sí Mike Tyson pé kó di asojú wọn fún ewé ọlà, igbó
Ileese eto ọgbin lorilẹ-ede Malawi ti kọwe ẹbẹ ransẹ si Mike Tyson pe ko di asoju awọn lori ọrọ Igbo. Mike Tyson to jẹ gbajugbaja abẹsẹkubi ojo ni ti gba iwe ifẹ lati ọdọ ileesẹ ijọba apapọ orilẹ-ede Malawi to n ri sio eto ọgbin. Won ni ki Mike Tyson jọwọ ara rẹ gẹgẹ bii asoju wọn lori ọra Igbo to jẹ ewé ọlà. Minista Lobin Lowe salaye nipa bi Igbo se di eyi ti ofin Malawi faaye gba nile ati nita orilk-ede Malawi. Ileese eto ọgbin naa ni pe Egbẹ United States Cannabis Association naa lọwọ si ipe lati soju naa. Ogbẹni Lowe so pe olokowo naa ni Mike Tyson ati pe oun naa ni oko Igbo to ti na owo si to pọ. 'Malawi Gold' to jẹ wura Malawi ni orukọ ti wọn n pe Igbo ni Malawi. Ọdun 1985 ni Mike Tyson bẹrẹ abẹṣẹkubi ojo, ko to fẹyinti lọdun 2005.
https://www.bbc.com/yoruba/media-59405173
yor
sports
Ìdíje bọ̀ọ́lù àwọn obìnrin, WAFCON 2022 gbérasọ ní Morocco
Ọjọ keji, oṣu Keje, ọdun 2022, ni idije fun ife ẹyẹ bọọlu awọn obinrin ni Afrika, Women's Africa Cup of Nations, yoo bẹ̀rẹ̀ ni orile-ede Morocco. Ti ọdun yii si ni igba akọkọ ti orile-ede mejila n kopa ninu idije naa. Saaju asiko yii, orile-ede mẹ́jọ lo ma ń kopa. Bakan naa lo jẹ pe igba àkọ́kọ́ re e ti Morocco gbalejo idije naa. Papa ìṣeré mẹta ni yoo ti waye, n'ilu Rabat olu ilu Morocco, ati ilu Casablanca laarin ọjọ keji oṣu Keje, si ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keje. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ akọkọ lati ṣide yoo waye laarin Morocco ati Burkina Faso ni papa isere Prince Moulay Abdellah n'ilu Rabat. Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Falcons, lo gba ife naa ni idije mẹta to kọja, wọn si ti gba a nígbà mẹsan-an, ninu igba mọkanla ti idije naa ti waye. Ipin C ni Naijiria wa ninu idije ti ọdun yii. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ yoo waye lọjọ Aje pẹlu orile-ede South Africa. Lẹyin naa ni wọn o koju Botswana ati Burundi. Ohun kan to jẹ mímọ̀ ni pe lati ìbẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́, ni Super Falcons ti ma n gba jọba idije. Àwọn agbabọọlu Naijiria to n sisẹ nilẹ okeere, pọ laarin àwọn ọmọ ikọ Super Falcons. Lara wọn ni Asisat Oshoala, ọmọ ẹgbẹ́ agbabọọlu Spain. Oun naa ni balogun ikọ Super Falcons. Ni opin idije WAFCON 2022 yii, ẹgbẹ́ agbabọọlu orile-ede to ba bori yoo ni anfaani lati kopa ni idije ife agbaye lọdun to n bọ. Bakan naa, orile-ede mẹrin to ba de ipele to kangun si aṣekagba, semi-final, yoo ni anfaani lati lọ si Australia ati New Zealand. Ẹgbẹrun lọ́nà ẹẹdẹgbẹta Dọla ni ẹ̀bùn owo ti orile-ede to ba borí ni WAFCON 2022 yoo gba.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c88v1ndzx5ro
yor
sports
Ronaldinho: Agbábọ́ọ̀lù Brazil tẹ́lẹ̀, Ronaldinho gba ìtúsílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n, àmọ́...
Agbabọọlu Brazil tẹlẹ, Ronaldinho ti gba itusilẹ lọgba ẹwọn lorilẹede Paraguay. Amọ, ijọba ilẹ Paraguay si fi ofin de e wi pe ko gbọdọ jade nile. Lọjọ kẹfa oṣu kẹta to lọ ni wọn mu Ronaldinho ati arakunrin rẹ, Roberto Assis lori ẹsun pe wọn lo ayederu iwe irina wọn orilẹede Paraguay. Awọn mejeeji gbọdọ wa ni igbele bayii titi di igba ti igbẹjọ wọn yoo fi bẹrẹ. Ṣugbọn Ronaldinho ati arakunrin rẹ sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn. Agbẹjọro wọn tiẹ ṣapejuwe igbesẹ ijọba naa lati fi wọn si ahamọ iwa ta ni yoo mu mi eleyi to lodi si ofin. Adajọ Gustavo Amarilla ara gbedeke to wa ninu beeli awọn mejeeji ni pe wọn ko gbọdọ sa lọ. Ronaldinho rinrin ajo lọ si orilẹede Paraguay tẹlẹ lati ṣe ifilọlẹ iwe rẹ ati ipolongo fawọn ọmọ ti obi wọn ko ri ọwọ họri. Ronaldinho to gba ife ẹyẹ agbaye pẹlu Brazil lọdun 2002 gba bọọlu fun Paris St-Germain, Barcelona ati AC Milan ilẹ Yuropu ko to fẹhinti lẹyin to ṣoju Fluminense fun igba diẹ ni Brazil.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-52218356
yor